Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 27
Orin 1 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 23 ìpínrọ̀ 19 sí 23, àti àpótí tó wà lójú ìwé 239 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 26-31 (8 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọlọgbọ́n nípa “ríra àkókò tí ó rọgbọ padà.”—Éfé. 5:15, 16.
5 min: Ìrírí. Ṣe àṣefihàn ìrírí kan tàbí méjì nípa bí akéde kan ṣe fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà ní Hébérù 6:11, 12. Sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fi taratara kéde Ìjọba Ọlọ́run.
10 min Ṣíṣàlàyé Nípa Ìjọba Ọlọ́run—Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run, Kí Ló sì Máa Ṣe fún Wa? Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. A gbé e ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 280, ìpínrọ̀ 1 sí 4.
15 min: “Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lágbára Tó Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.” Ìjíròrò. Lẹ́yìn náà, ṣe àṣefihàn alápá-méjì. Àkọ́kọ́, akéde kan fi ìwé pẹlẹbẹ Ìròyìn Ayọ̀ lọ ẹnì kan. Ó sọ apá kan lára ohun tó wà ní 2 Tímótì 3:16, 17, láìṣí Bíbélì. Lẹ́yìn náà, akéde yìí wá tún àṣefihàn náà ṣe, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ó ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà tààràtà látinú Bíbélì. Ní kí àwọn ará sọ ìdí tí àṣefihàn kejì fi gbéṣẹ ju ti àkọ́kọ́ lọ.
Orin 124 àti Àdúrà