Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 8
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 8
Orin 6 àti Àdúrà
kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 25 ìpínrọ̀ 17 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 259 (30 min.)
lé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 19-21 (8 min.)
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 19:24-37 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ayọ̀?—igw ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
No. 3: Ẹ̀kọ́ Wo Ni Lúùkù 12:13-15, 21 Kọ́ Wa? (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé.”—Diu. 32:7.
10 min: Rántí Àwọn Ọjọ́ Láéláé. Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. Ka Diutarónómì 4:9; 32:7 àti Sáàmù 71:15-18, kó o sì jíròrò rẹ̀. Ṣàlàyé bí àwọn ajíhìnrere òde òní ṣe lè jàǹfààní tí wọ́n bá ń rántí àwọn èèyàn àtàwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn nínú ètò Ọlọ́run. Sọ fún àwọn ará pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n lè máa jíròrò ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Látinú Àpamọ́ Wa” nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn. Sọ díẹ̀ lára àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn oṣù yìí, kó o sì sọ bó ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí.
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I —Bó O Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ẹnu Ọ̀nà.” Ìjíròrò tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa bójú tó. Mẹ́nu ba kókó tó tan mọ́ ìjíròrò yìí nínú àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá ìjọ yín tó jẹ́ ká rí i pé a ṣì lè ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i. Ní kí akéde kan tó nírìírí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnu ọ̀nà nípa lílo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé yìí. Gba àwọn ará níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnu ọ̀nà.
Orin 29 àti Àdúrà