Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 19
Orin 54 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia ojú ìwé 2 sí 3 àti ọ̀rọ̀ ìṣáájú, ìpínrọ̀ 1 sí 15 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 8-11 (8 min.)
No. 1: 1 Kíróníkà 11:15-25 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Àdúrà Tó Ṣètẹ́wọ́gbà Ṣe Dà Bíi Tùràrí Olóòórùn Dídùn sí Jèhófà?—Sm. 141:2; Ìṣí. 5:8 (5 min.)
No. 3: Kí La Gbọ́dọ̀ Ṣe Kí Ọlọ́run Tó Gbọ́ Àdúrà Wa?—wp13 8/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: ‘Ẹ ta gbòǹgbò kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.’—Kól. 2:6, 7.
20 min: “Bí A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Wa Wọ Àwọn Tí À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́kàn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣe àṣefihàn méjì tó yàtọ̀ síra. Onílé sọ pé ọmọ òun kú, ó sì ti wà lọ́run báyìí. Nínú àṣefihàn àkọ́kọ́, akéde náà ka Oníwàásù 9:5 tó sọ̀rọ̀ nípa ipò táwọn òkú wà. Obìnrin náà kò fara mọ́ ohun tí akéde sọ tórí pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kà kò tù ú nínú. Nínú àṣefihàn kejì, akéde náà ka Jòhánù 5:28, 29, ó sì fọgbọ́n ṣàlàyé ìrètí àjíǹde tó wà nínú ẹsẹ náà. Ohun tó ṣe yìí mú kí obìnrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa.
10 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́ àti Ẹ̀yin Àgbàlagbà, Ẹ Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere fún Àwọn Ẹlòmíì. (Fílí. 3:17; 1 Tím. 4:12) Ìjíròrò tó dá lórí Ìwé Ọdọọdún 2015, ojú ìwé 71, ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 72, ìpínrọ̀ 4 àti ojú ìwé 76 sí 78. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 90 àti Àdúrà