Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 7
Orin 86 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
ia orí 4 ìpínrọ̀ 1 sí 15, àti àpótí tó wà lójú ìwé 39 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 10-14 (8 min.)
No. 1: 2 Kíróníkà 13:13-22 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú (5 min.)
No. 3: Ìṣàkóso Ta Ló Máa Mú Ká Láyọ̀ Ká sì Máa Gbé ní Àlàáfíà Bó Ṣe Rí Láti Ìbẹ̀rẹ̀—wp14 5/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Oṣù Yìí: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.”—Ìṣe 14:22.
10 min: “A Gbọ́dọ̀ Ti Inú Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú Wọ Ìjọba Ọlọ́run.” Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. Ka Ìṣe 14:21, 22 àti 1 Pétérù 4:12-14, kó o sì jíròrò rẹ̀. (Wo Ilé Ìṣọ́ September 15, 2014, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 3 sí 6.) Ní ṣókí, sọ díẹ̀ lára àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ ìsìn oṣù yìí, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. Gba àwọn ará níyànjú láti wo fídíò ‘Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa’ láti múra sílẹ̀ de Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.
10 min: Báwo Ló Ṣe Yẹ Kó O Dáhùn? (Kól. 4:6) Àsọyé tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 69, ìpínrọ̀ 1 sí 3. Ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn méjì tó yàtọ̀ síra. Nínú àṣefihàn àkọ́kọ́, akéde náà yára fèsì ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí onílé sọ sí i, ohun tó ṣe yìí kò jẹ́ kí onílé gbọ́rọ̀ rẹ̀. Nínú àṣefihàn kejì, akéde náà kọ́kọ́ sinmẹ̀dọ̀ lẹ́yìn tí onílé sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i, ó wá sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, ohun tó ṣe yìí jẹ́ kí onílé gbọ́rọ̀ rẹ̀.
10 min: “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Hábákúkù.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 74 àti Àdúrà