February 29 Sí March 6
Ẹ́SÍTÉRÌ 1-5
- Orin 86 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ẹ́sítérì Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run”: (10 min.) - [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sítérì.] 
- Es 3:5-9—Hámánì fẹ́ pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run (ia ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 18 àti 19) 
- Es 4:11–5:2—Ìgbàgbọ́ tí Ẹ́sítérì ní borí ìbẹ̀rù ikú (ia ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 2; ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 24 sí 26) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Es 2:15—Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn? (w06 3/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 7) 
- Es 3:2-4—Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? (ia ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 18) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: Ẹst 1:1-15 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run lọ ẹnì kan. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá. 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó gba ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Ẹ jọ jíròrò ojú ìwé 2 àti 3. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi ojú ìwé 4 àti 5 nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹni tó gba ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run nígbà àkọ́kọ́. (km 7/12 ojú ìwé 2 sí 3 ìpínrọ̀ 4) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ: (10 min.) 
- Báwo Lo Ṣe Ń Jàǹfààní Nínú Ọ̀nà Tuntun Tá A Gbà Ń Ṣèpàdé àti Ìwé Ìpàdé?: (5 min.) Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nínú ìpàdé tuntun yìí. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n lè máa jàǹfààní gan-an nínú rẹ̀. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 10 ìpínrọ̀ 1 sí 11 àti àpótí tó wà lójú ìwé 86 (30 min.) 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 149 àti Àdúrà