Orin 149
A Dúpẹ́ fún Ìràpadà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- Jèhófà, a dúró, - níwájú rẹ lónìí, - Torí o fi ìfẹ́ tó - ga jù lọ hàn sí wa. - Ọmọ rẹ tó kú fún wa ló, - jẹ́ ká níyè. - Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye - jù lọ ni èyí jẹ́. - (ÈGBÈ) - Ó f’ẹ̀mí rẹ̀ dá wa sílẹ̀. - Ẹ̀jẹ̀ iyebíye ló lò. - Títí ayé - laó máa dúpẹ́ fún ìràpadà yìí. 
- Tinú tinú ni Jésù - f’ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. - Ìfẹ́ ló mú kó fi ẹ̀mí - rẹ̀ pípé lé lẹ̀. - Ó jẹ́ ká nírètí nígbà - tírètí pin. - Aó níyè àìnípẹ̀kun, - aó bọ́ lọ́wọ́ ikú. - (ÈGBÈ) - Ó f’ẹ̀mí rẹ̀ dá wa sílẹ̀. - Ẹ̀jẹ̀ iyebíye ló lò. - Títí ayé - laó máa dúpẹ́ fún ìràpadà yìí. 
(Tún wo Héb. 9:13, 14; 1 Pét. 1:18, 19.)