March 21 Sí 27
JÓÒBÙ 6-10
- Orin 68 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Jóòbù Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀”: (10 min.) - Job 6:1-3, 9, 10, 26; 7:11, 16—Tí ìdààmú bá bá àwọn èèyàn, kì í ṣe ohun tí wọ́n ní lọ́kàn gan-an ni wọ́n sábà máa ń sọ (w13 8/15 19 ¶7; w13 5/15 22 ¶13) 
- Job 9:20-22—Àwọn ìṣòro tí Jóòbù ní mú kó ní èrò tí kò tọ́, ó rò pé ojú kan náà ni Ọlọ́run fi ń wo ẹni burúkú àti ẹni rere (w15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2) 
- Job 10:12—Kódà nígbà tí Jóòbù kojú àdánwò tó lè koko, ó sọ àwọn ohun tó dára nípa Jèhófà (w09 4/15 7 ¶18; w09 4/15 10 ¶13) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Job 6:14—Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ṣe pàtàkì? (w10 11/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 20) 
- Job 7:9, 10; 10:21—Tí Jóòbù bá gbà pé àjíǹde wà, kí nìdí tó fi sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ yìí? (w06 3/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 11) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: Job 9:1-21 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: wp16.2 ojú ìwé 16—Sọ bí a ṣe ń fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa. (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Ìpadàbẹ̀wò: wp16.2 ojú ìwé 16—Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá. (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: fg ẹ̀kọ́ 2 ìpínrọ̀ 6 sí 8 (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Máa Lo Ìjìnlẹ̀ Òye Tó O Bá Ń Tu Àwọn Èèyàn Nínú: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tí àwọn alàgbà wò láìpẹ́ yìí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Lẹ́yìn náà, ní kí àwọn ará sọ bí àwọn arákùnrin méjì tá a rí nínú fídíò náà ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nípa bí a ṣe lè tu ẹni tó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún wa nínú lẹ́yìn tí èèyàn rẹ̀ kan kú. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 11 ìpínrọ̀ 12 sí 20, àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 98 (30 min.) 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 27 àti Àdúrà