ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 45-51
Jèhófà Kò Ní Fi Ẹni Tó Ní Ìròbìnújẹ́ Ọkàn Sílẹ̀
Dáfídì ló kọ Sáàmù 51. Ó kọ ọ́ lẹ́yìn tí wòlíì Nátánì pe àfíyèsí rẹ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà. Ẹ̀rí ọkàn Dáfídì dà á láàmú, ó sì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—2Sa 12:1-14.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣì lè dáa
- Kí Dáfídì tó ronú pìwà dà tó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ti ń dà á láàmú 
- Ẹ̀dùn ọkàn Dáfídì pọ̀ torí pé ó pàdánù ojú rere Ọlọ́run, èyí mú kó ronú pé òun dà bí ẹni tí wọ́n fọ́ egungun rẹ̀ 
- Dáfídì fẹ́ kí Jèhófà dárí ji òun kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, kó sì lè máa láyọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ 
- Dáfídì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè tètè máa ṣègbọràn sí i 
- Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà máa dárí ji òun