September 12 Sí 18
SÁÀMÙ 120-134
- Orin 33 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”: (10 min.) - Sm 121:1, 2—Torí pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo, èyí mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e (w04 12/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3) 
- Sm 121:3, 4—Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá (w04 12/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 4) 
- Sm 121:5-8—Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ (w04 12/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 5 sí 7) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Sm 123:2—Ẹ̀kọ́ wo ni àkàwé nípa “ojú àwọn ìránṣẹ́” kọ́ wa? (w06 9/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 4) 
- Sm 133:1-3—Kí ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ nínú sáàmù yìí? (w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3) 
- Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? 
- Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 127:1–129:8 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Àwòrán iwájú ìwé ìròyìn wp16.5 tó wà lójú ìwé 2—Wàásù fún ẹnì kan tó ń bínú. 
- Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Kókó iwájú ìwé ìròyìn wp16.5 —Pe ẹni náà wá sípàdé. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 8 ìpínrọ̀ 6—Ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kó lè rí bó ṣe lè fi ohun tó kọ́ sílò. 
- Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Jèhófà Ti Ṣe fún Mi: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò yìí. Ó wà lórí ìkànnì jw.org/yo.Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Jèhófà Ti Ṣe fún Mi. (Lọ sí NÍPA WA > OHUN TÁ À Ń ṢE.) Ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni Jèhófà ṣe ran Crystal lọ́wọ́, kí sì lèyí mú kó ṣe? Kí ló máa ń ṣe nígbà tí èrò òdì bá ń kó ìbànújẹ́ bá a? Kí ni ìrírí Crystal kọ́ ẹ? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia Ìparí, ìpínrọ̀ 1 sí 13 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 119 àti Àdúrà