October 2-8
DÁNÍẸ́LÌ 7-9
- Orin 116 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì Sọ Ìgbà Tí Mèsáyà Máa Dé”: (10 min.) - Da 9:24—Ikú ìrúbọ tí Mèsáyà kú ló mú kí Ọlọ́run lè máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá (it-2 902 ¶2) 
- Da 9:25—Mèsáyà náà dé ní òpin ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69] ti ọdún (it-2 900 ¶7) 
- Da 9:26, 27a—Wọ́n pa Mèsáyà náà ní àárín àádọ́rin ọ̀sẹ̀ [70] ti ọdún (it-2 901 ¶2, 5) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Da 9:24—Ìgbà wo ni a fòróró yan “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́”? (w01 5/15 27) 
- Da 9:27—Májẹ̀mú wo ló ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ títí di òpin àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ti ọdún, tàbí ọdún 36 Sànmánì Kristẹni? (w07 9/1 20 ¶4) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Da 7:1-10 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò tó dá lórí “Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò.” Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú kí wọ́n tètè pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn. 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀ Nínú Ìwé Mímọ́”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí Tá A Fi Ń Wá Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) kr orí 19 ¶1-7, àwọn àpótí “Ṣọ́ọ̀ṣì “New Light”” àti “Iṣẹ́ Kíkọ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì —Àtúntò Látàrí Ìyípadà Tó Ń Wáyé” 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 53 àti Àdúrà