MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
O Lè Ṣàṣeyọrí Láìka Ti “Ẹ̀gún” Tó Wà Nínú Ara Rẹ Sí!
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan le gan-an yìí, àwọn ìṣòro tó dà bí ẹ̀gún ń bá gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run fínra. (2Ti 3:1) Báwo la ṣe lè gbára lé Jèhófà, kí la sì lè ṣe láti fara dà àwọn ìṣòro yìí? Wo fídíò náà “Ojú Àwọn Afọ́jú Yóò Là” kó o lè rí ohun tí Talita Alnashi àti àwọn òbí rẹ̀ ṣe, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
- Kí ni “ẹ̀gún” tó wà nínú ara Talita? 
- Àwọn ìlérí inú Bíbélì wo ló ti ran Talita àtàwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́ láti má sọ̀rètí nù? 
- Báwo ni àwọn òbí Talita ṣe fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún Talita? 
- Báwo ni àwọn òbí Talita ṣe lo àwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run pèsè láti ran Talita lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? 
- Báwo ni Talita ṣe fi hàn pé òun ń dàgbà nípa tẹ̀mí láìka “ẹ̀gún” tó wà nínú ara rẹ̀ sí? 
- Ìṣírí wo lo ti rí látinú ìrírí Talita?