May 27–June 2
GÁLÁTÍÀ 1-3
- Orin 106 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Mo Ta Kò Ó Lójúkojú”: (10 min.) - [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Gálátíà.] 
- Ga 2:11-13—Nígbà tí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù dé ọ̀dọ̀ Pétérù, ìbẹ̀rù èèyàn mú kí Pétérù máa yẹra fún àwọn ará tó jẹ́ Kèfèrí (w17.04 27 ¶16) 
- Ga 2:14—Pọ́ọ̀lù bá Pétérù wí (w13 3/15 5 ¶12) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.) - Ga 2:20—Irú ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo ìràpadà, kí sì nìdí? (w14 9/15 16 ¶20-21) 
- Ga 3:1—Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi pe àwọn ará Gálátíà ní “aláìnírònú”? (it-1 880) 
- Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ga 2:11-21 (th ẹ̀kọ́ 10) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. 
- Ìpadàbẹ̀wò Kejì: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 2) 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bh 191-192 ¶18-19 (th ẹ̀kọ́ 6) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- “Bí Gbogbo Wa Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa”: (15 min.) Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Lẹ́yìn táwọn ará bá ti wo fídíò Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa, tẹ́ ẹ sì ti dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀, ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń ṣojú ìjọ yín nínú ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Tí ìjọ yín ò bá ní ẹni tó ń ṣojú fún yín, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Tó bá jẹ́ pé ìjọ yín nìkan ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹni tó ń bójú tó àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba.) Ṣé à ń ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa nígbà tó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé à ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tí kò fi ní sí ìpalára èyíkéyìí? Àwọn àtúnṣe wo lẹ ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba láìpẹ́ yìí, kí lẹ sì tún ń gbèrò láti ṣe? Tí ẹnì kan bá mọ iṣẹ́ kan tàbí tó bá fẹ́ máa ran àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń tún nǹkan ṣe, kí ni ẹni náà máa ṣe? Báwo ni tọmọdé tàgbà wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba, láìka ipò yòówù ká wà sí? 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 6 ¶7-13 
- Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.) 
- Orin 72 àti Àdúrà