March 16-22
JẸ́NẸ́SÍSÌ 25-26
- Orin 18 àti Àdúrà 
- Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.) 
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
- “Ísọ̀ Ta Ogún Ìbí Rẹ̀”: (10 min.) - Jẹ 25:27, 28—Ìbejì ni Ísọ̀ àti Jékọ́bù, àmọ́ ìwà wọn yàtọ̀ síra (it-1 1242) 
- Jẹ 25:29, 30—Ísọ̀ ò ronú kó tó ṣèpinnu torí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, ebi sì ń pa á 
- Jẹ 25:31-34—Aláìmoore ni Ísọ̀, ó fi ìwàǹwára ta ogún ìbí rẹ̀ fún Jékọ́bù nítorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré (w19.02 16 ¶11; it-1 835) 
 
- Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.) - Jẹ 25:31-34—Kí nìdí tí a ò fi lè lo ẹsẹ Bíbélì yìí láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn baba ńlá Mèsáyà gbọ́dọ̀ jẹ́ àkọ́bí? (Heb 12:16; w17.12 15 ¶5-7) 
- Jẹ 26:7—Kí nìdí tí Ísákì ò fi sọ òkodoro ọ̀rọ̀ nínú ipò tó bá ara rẹ̀ yìí? (it-2 245 ¶6) 
- Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì? 
 
- Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 26:1-18 (th ẹ̀kọ́ 5) 
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
- Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́—Fídíò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Kí la lè ṣe tá ò fi ní dójú ti onílé tí kò bá mọ ìdáhùn sí ìbéèrè wa? Báwo ni akéde náà ṣe ṣàlàyé Mátíù 20:28 kó lè wọ onílé lọ́kàn? 
- Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 3) 
- Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? (th ẹ̀kọ́ 15) 
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
- Máa Lo Fídíò Tó O Bá Ń Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Kọ́ni: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú? àti Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà? Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá wo fídíò kọ̀ọ̀kan tán, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo lo ṣe lè lo fídíò yìí nígbà tó o bá ń fí ìwé Ìròyìn Ayọ̀ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́? (mwb19.03 7) Kí lo kíyè sí nínú fídíò náà tó máa wúlò fún ẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Rán àwọn ara létí pé ẹ̀dà ìwé Ìròyìn Ayọ̀ tó wà lórí ẹ̀rọ̀ ní ìlujá tó máa gbé wọn lọ síbi tí fídíò kọ̀ọ̀kan wà. 
- Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 17 ¶1-8 
- Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) 
- Orin 107 àti Àdúrà