ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 25-26
Ísọ̀ Ta Ogún Ìbí Rẹ̀
Ísọ̀ “kò mọyì àwọn ohun mímọ́.” (Heb 12:16) Ìdí nìyẹn tó fi ta ogún ìbí rẹ̀, tó sì tún fẹ́ àwọn obìnrin tí kò sin Jèhófà.—Jẹ 26:34, 35.
BI ARA RẸ PÉ: ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo mọyì àwọn ohun mímọ́ yìí?’
- Àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà 
- Ẹ̀mí mímọ́ 
- Bá a ṣe ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà 
- Iṣẹ́ ìwàásù 
- Àwọn ìpàdé wa 
- Ìgbéyàwó