JULY 28–AUGUST 3
ÒWE 24
Orin 38 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Gbára Dì fún Àkókò Wàhálà
(10 min.)
Túbọ̀ máa gba ìmọ̀ àti ọgbọ́n Ọlọ́run (Owe 24:5; w23.07 18 ¶15)
Nígbà tó o bá rẹ̀wẹ̀sì, rí i dájú pé o ò pa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tì, irú bí àdúrà gbígbà, Bíbélì kíkà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ (Owe 24:10; w09 12/15 18 ¶12-13)
Tá a bá nígbàgbọ́ tá a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní bọ́hùn lásìkò wàhálà (Owe 24:16; w20.12 15)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 24:27—Kí ni òwe yìí kọ́ wa? (w09 10/15 12)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 24:1-20 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. O ò ráyè wàásù títí ìjíròrò náà fi parí. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fún un ní káàdì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
7. Àsọyé
(3 min.) lmd àfikún A kókó 11—Àkòrí: Ọlọ́run Máa Ń Bá Wa Sọ̀rọ̀. (th ẹ̀kọ́ 6)
Orin 99
8. Ẹ Máa Ran Ara Yín Lọ́wọ́ Lásìkò Wàhálà
(15 min.) Ìjíròrò.
Níbi tójú ọjọ́ dé yìí, àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, rògbòdìyàn, inúnibíni tàbí àjálù lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Nígbà tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àwọn Kristẹni tọ́rọ̀ kan máa ń ṣera wọn lọ́kan, wọ́n sì máa ń gbé ara wọn ró. Àmọ́, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ò bá tiẹ̀ kàn wá, a máa ń káàánú àwọn tí àjálù náà bá, a sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—1Kọ 12:25, 26.
Ka 1 Àwọn Ọba 13:6 àti Jémíìsì 5:16b. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí nìdí tí àdúrà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá gbà nítorí àwọn míì fi máa ń lágbára gan-an?
Ka Máàkù 12:42-44 àti 2 Kọ́ríńtì 8:1-4. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ tó sì jẹ́ pé ìwọ̀nba owó táṣẹ́rẹ́ la lè fi ti iṣẹ́ kárí ayé lẹ́yìn láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó níṣòro, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣì gbìyànjú láti ṣèrànwọ́?
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ A Fún Àwọn Ará Wa Lókun Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí làwọn ará wa ṣe kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó ń gbé níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù kí oúnjẹ tẹ̀mí lè dé ọ̀dọ̀ wọn?
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa, báwo làwọn ará ṣe ṣègbọràn sí àṣẹ náà pé ká máa pàdé pọ̀ láti gbé ara wa ró?—Heb 10:24, 25
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 4-5