NOVEMBER 3-9
ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 1-2
Orin 132 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ìtàn Nípa Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀
(10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tó Wà Nínú Orin Sólómọ́nì.]
Sólómọ́nì sọ ọ̀rọ̀ tó dùn fún ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì, ó sì ṣèlérí pé òun máa fún un ní ọ̀pọ̀ nǹkan (Sol 1:9-11)
Ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí olólùfẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, ìyẹn ló mú kó jẹ́ olóòótọ́ sí i (Sol 2:16, 17; w15 1/15 30 ¶9-10)
ÀBÁ: Nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, apá tá a pè ní “Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí” máa ń wà níbẹ̀rẹ̀ ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan. Lo apá yìí tó o bá ń ka ìwé Orin Sólómọ́nì kó o lè mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ gan-an.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sol 2:7—Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lè kọ́ lára ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì? (w15 1/15 31 ¶11)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sol 2:1-17 (th ẹ̀kọ́ 12)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Orin 46
7. ‘Ẹni Tó Lawọ́ Máa Gba Ìbùkún’
(15 min.) Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí.
Tá a bá ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn nǹkan tá a ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, Jèhófà máa bù kún wa. Ohun kan ni pé, inú ẹni tá a ràn lọ́wọ́ máa dùn gan-an, àwa náà sì máa láyọ̀. (Owe 22:9) Tá a bá ń fúnni, a máa láyọ̀ kì í ṣe torí pé à ń fara wé Jèhófà nìkan, àmọ́ torí pé a tún máa rí ojú rere ẹ̀.—Owe 19:17; Jem 1:17.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ A Máa Láyọ̀ Tá A Bá Ń Fúnni. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni ìtìlẹyìn tí àwọn ará wa kárí ayé ṣe ṣe jẹ́ káwọn ará tá a rí nínú fídíò yẹn láyọ̀?
Báwo ni àwọn ará tá a ràn lọ́wọ́ ṣe rí ayọ̀ nígbà táwọn náà ran àwọn míì lọ́wọ́?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 32-33