ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr25 November ojú ìwé 1-13
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú “Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú “Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni”
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé—2025
  • Ìsọ̀rí
  • NOVEMBER 3-9
  • NOVEMBER 10-16
  • NOVEMBER 17-23
  • NOVEMBER 24-30
  • DECEMBER 1-7
  • DECEMBER 8-14
  • DECEMBER 15-21
  • DECEMBER 22-28
  • DECEMBER 29–JANUARY 4
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé—2025
mwbr25 November ojú ìwé 1-13

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

© 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

NOVEMBER 3-9

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 1-2

Ìtàn Nípa Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀

w15 1/15 30 ¶9-10

Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?

9 Àdéhùn ìgbéyàwó kì í ṣe àdéhùn orí ìwé lásán tí kò ní sí ìfẹ́ láàárín tọkọtaya, tí wọn ò sì ní fi ìfẹ́ hàn síra wọn. Kódà, ìfẹ́ la fi ń dá ìgbéyàwó Kristẹni mọ̀ yàtọ̀. Àmọ́ irú ìfẹ́ wo ni ìfẹ́ yìí? Ṣé ìlànà Bíbélì ló ń darí ìfẹ́ yìí? (1 Jòh. 4:8) Ṣé ìfẹ́ yìí dà bí ìfẹ́ tí ìdílé máa ń ní síra wọn? Ǹjẹ́ ìfẹ́ yìí dà bí ìfẹ́ táwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn máa ń ní síra wọn? (Jòh. 11:3) Ṣé ìfẹ́ àárín ọkùnrin àti obìnrin ni? (Òwe 5:​15-20) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìfẹ́ tòótọ́ tó so tọkọtaya pọ̀ gbọ́dọ̀ kó gbogbo ìfẹ́ yìí mọ́ra. Ìgbà tẹ́nì kan bá fìfẹ́ hàn sí wa la tó máa ń mọ agbára tí ìfẹ́ ní. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn tọkọtaya má ṣe jẹ́ kí kòókòó jàn-ánjàn-án ojoojúmọ́ mú kí wọ́n má ṣe máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́! Tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́, ọkàn wọn á balẹ̀, wọ́n á sì láyọ̀. Ní àwọn ilẹ̀ kan, ọkùnrin àti obìnrin tó fẹ́ di tọkọtaya lè má mọ ara wọn títí di ọjọ́ ìgbéyàwó, tírú àwọn bẹ́ẹ̀ bá fi kọ́ra láti máa sọ̀rọ̀ ìfẹ́ fún ara wọn, ó máa jẹ́ kí ìfẹ́ wọn jinlẹ̀, kí wọ́n sì túbọ̀ mọ ara wọn dáadáa.

10 Àwọn tọkọtaya tún máa jàǹfààní lọ́nà míì tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́. Sólómọ́nì Ọba ṣèlérí fún Ṣúlámáítì pé òun máa fún un ní “àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rìbìtì-rìbìtì ti wúrà . . . pẹ̀lú àwọn òníní tí a fi fàdákà ṣe.” Ó kó ọ̀rọ̀ dídùn sí i lórí, ó ní ó ‘lẹ́wà bí òṣùpá àrànmọ́jú, ó sì mọ́ gaara bí oòrùn tí ń ràn yòò.” (Orin Sól. 1:​9-11; 6:10) Àmọ́ Ṣúlámáítì jẹ́ olóòótọ́ sí olólùfẹ́ rẹ̀. Kí ló fún un lókun tó sì tù ú nínú láwọn àkókò tí òun àti olólùfẹ́ rẹ̀ ò fi sí pa pọ̀? Ó sọ fún wa. (Ka Orin Sólómọ́nì 1:​2, 3.) Ọ̀dọ́bìnrin náà ò gbàgbé “àwọn [ọ̀rọ̀] ìfìfẹ́hàn” tí olùṣọ́ àgùntàn náà máa ń sọ. Lójú ọ̀dọ́bìnrin náà, àwọn ọ̀rọ̀ yẹn “dára ju wáìnì” tó ń mú ọkàn yọ̀, orúkọ rẹ̀ sì tuni lára bí “òróró tí a dà jáde” sí orí. (Sm. 23:5; 104:15) Àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọ́n ti jọ sọ fún ara wọn máa jẹ́ kí ìfẹ́ wọn wà pẹ́ títí. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn tọkọtaya máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́ torí ó máa jẹ́ kí ìfẹ́ àárín wọn jinlẹ̀ sí i!

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w15 1/15 31 ¶11

Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?

11 Orin Sólómọ́nì tún kọ́ àwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lẹ́kọ̀ọ́, pàápàá jù lọ àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin náà kò nífẹ̀ẹ́ Sólómọ́nì. Ṣúlámáítì fi àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù sábẹ́ ìbúra, ó sọ pé: “Ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.” (Orin Sól. 2:7; 3:5) Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé kò dáa ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wà láàárín àwa àti ẹnì kan ṣá. Torí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí Kristẹni tó fẹ́ lọ́kọ tàbí láya ní sùúrù táá fi rí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ gan-an.

NOVEMBER 10-16

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 3-5

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Níwà Tó Dáa

w15 1/15 30 ¶8

Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?

8 Kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọ́n sọ nínu orin ewì náà ló ń tọ́ka sí ẹwà ara. Wo ohun tí olùṣọ́ àgùntàn náà sọ nípa ọ̀rọ̀ ẹnu obìnrin náà. (Ka Orin Sólómọ́nì 4:​7, 11.) Ó ní “afárá oyin ń kán tótó” ní ètè rẹ̀. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Oyin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ rẹ́ nílé oyin ni wọ́n ń pè ní afárá oyin, ó sì dùn ju oyin tí atẹ́gùn ti fẹ́ sí lọ. Ó tún sọ pé, “Oyin àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n [rẹ̀],” ó túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ún gbọ́ sétí, ó sì lárinrin. Torí náà, nígbà tí olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún ọ̀dọ́bìnrin náà pé, “ìwọ lẹ́wà látòkè délẹ̀, . . . kò sì sí àbùkù kankan lára rẹ,” kì í wulẹ̀ ṣe ẹwà rẹ̀ nìkan ló ní lọ́kàn.

w00 11/1 11 ¶17

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Mímọ́

17 Omidan Ṣúlámáítì ni ẹnì kẹta tóun náà pa ìwà títọ́ mọ́. Ọ̀dọ́ ni ó sì lẹ́wà, tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan báyìí nìkan ló nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó tún wu Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ pẹ̀lú. Jálẹ̀ inú ìtàn àtàtà tó wà nínú Orin Sólómọ́nì, Ṣúlámáítì pa ara rẹ̀ mọ́, nípa bẹ́ẹ̀ gbogbo àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un. Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti kọ ìtàn rẹ̀ sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin náà kò gbà láti fẹ́ ẹ. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ yẹn náà tún bọ̀wọ̀ fún ìwà mímọ́ rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó fi ìrònújinlẹ̀ sọ pé Ṣúlámáítì yìí dà bí “ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀.” (Orin Sólómọ́nì 4:12) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn ọgbà ẹlẹ́wà máa ń ní oríṣiríṣi ewébẹ̀ tó dùn ún wò, àwọn ìtànná olóòórùn dídùn, àti àwọn igi tí ìdúró wọ́n wuni gan-an. Wọ́n sábà máa ń sọgbà tàbí ògiri yí irú àwọn ọgbà bẹ́ẹ̀ ká, kò sì sẹ́ni tó lè wọnú ẹ̀ láìgba ẹnu ọ̀nà rẹ̀ tó wà ní títì wọlé. (Aísáyà 5:5) Gẹ́gẹ́ bí ọgbà tó ní ẹwà àrà ọ̀tọ̀ yẹn, ni ìwà mímọ́ àti fífà tí Ṣúlámáítì fani mọ́ra ṣe rí sí olùṣọ́ àgùntàn náà. Òun jẹ́ ẹni tó pa ara rẹ̀ mọ́ délẹ̀délẹ̀. Kò jẹ́ gbà kí ìfẹ́ òun fà sí ẹlòmíràn àyàfi ọkọ rẹ̀ tó bá fẹ́ lọ́jọ́ iwájú.

g05 1/8 21 ¶1-4

Irú Ẹwà Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Ṣé ẹwà inú lè fa àwọn ẹlòmíràn mọ́ra? Georgina, tó ti fẹ́ẹ̀ tó ọdún mẹ́wàá báyìí tó ti ṣègbéyàwó sọ pé: “Láti ọdún yìí wá, ohun tó ń mú kí ọkọ mi máa dá mi lọ́rùn ni bó ṣe ń fòótọ́ àti inú kan bá mi lò. Ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé ẹ̀ ni bó ṣe máa ṣe ohun tó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Èyí wà lára ohun tó máa ń jẹ́ kó gba tèmi rò kó sì máa fìfẹ́ bá mi lò. Ó máa ń ro tèmi mọ́ tiẹ̀ kó tó pinnu ohunkóhun ó sì máa ń fi hàn mí pé òun ò lè fi mí ṣeré. Mo mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ mi gan-an ni.”

Daniel tó gbéyàwó sílé lọ́dún 1987 sọ pé: “Lójú mi, arẹwà ni ìyàwó mi. Kì í ṣe ẹwà ẹ̀ nìkan ni mo rí ṣùgbọ́n bó ṣe máa ń hùwà gan-an ló jẹ́ kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó máa ń ro ti àwọn ẹlòmíràn mọ́ tiẹ̀ ó sì máa ń ṣe nǹkan tó máa ń mú kí inú wọn dùn. Ó láwọn ànímọ́ Kristẹni tó ṣeyebíye. Èyí ló máa ń jẹ́ kó wù mí láti wà pẹ̀lú ẹ̀ ṣáá.”

Láyé tó jẹ́ pé ojú làwọn èèyàn ń wò yìí, ó yẹ ká máa wo nǹkan ní àwòfín. Ó yẹ ká mọ̀ pé kò ṣeé ṣe féèyàn láti ní ìrísí “tí ò lábùkù,” tó bá sì ṣeé ṣe, á ṣòro fún èèyàn láti ní in, kò sì sí àǹfààní gidi kan nídìí ẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó ṣeé ṣe fún èèyàn láti ní àwọn ànímọ́ inú tó ń fani mọ́ra tó sì ń fún èèyàn láyọ̀. Bíbélì sọ pé: “Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ.” Dípò ká máa ṣe kìràkìtà torí pé a fẹ́ lẹ́wà, Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa pé: “Gẹ́gẹ́ bí òrùka imú oníwúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin tí ó jẹ́ arẹwà, ṣùgbọ́n tí ó yí padà kúrò nínú ìlóyenínú.”​—Òwe 11:22; 31:30.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé jíjẹ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run” ló ṣe pàtàkì jù. (1 Pétérù 3:4) Dájúdájú, irú ẹwà inú bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ju ẹwà ti ara lọ. Gbogbo èèyàn pátá ló sì lè ní irú ẹwà yẹn.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w06 11/15 18 ¶4

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Orin Sólómọ́nì

2:7; 3:5​—Kí nìdí tó fi fi àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin sábẹ́ ìbúra “nípasẹ̀ àwọn abo àgbàlàǹgbó tàbí nípasẹ̀ àwọn egbin inú pápá”? Àwọn àgbàlàǹgbó àti egbin máa ń wuni wò nítorí ìrìn ẹ̀yẹ àti ẹwà wọn. Nítorí náà, ńṣe ni omidan Ṣúlámáítì ń lo gbogbo ohun yòówù tó bá rẹwà tó sì dára láti fi àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin sábẹ́ ìbúra pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ wá sóun lọ́kàn.

NOVEMBER 17-23

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 6-8

Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Ìṣekúṣe

w15 1/15 32 ¶15-16

Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?

15 Ka Orin Sólómọ́nì 4:12. Kí nìdí tí olùṣọ́ àgùntàn náà fi sọ pé olólùfẹ́ òun dà bí “ọgbà tí a gbégi dínà rẹ̀”? Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè wọnú ọgbà tí wọ́n mọ odi yí ká. Ẹni bá fẹ́ wọlé gbọ́dọ̀ gba ẹnu ọ̀nà tí wọ́n fi àgádágodo tì. Ṣúlámáítì dà bí irú ọgbà yìí torí pé olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ nìkan ni ìfẹ́ rẹ̀ wà fún. Bí Ṣúlámáítì kò ṣe gbà láti fẹ́ ọba láìka gbogbo ìlérí tó ṣe sí, ńṣe ló fi hàn pé òun jẹ́ “ògiri” àti pé òun kì í ṣe “ilẹ̀kùn” tó ṣí sílẹ̀ gbayawu. (Orin Sól. 8:​8-10) Lọ́nà kan náà, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń pa ara wọn mọ́ títí wọ́n á fi ni ọkọ tàbí aya.

16 Lọ́jọ́ kan, lákòókò tí ojú ọjọ́ dára nígbà ìrúwé, olùṣọ́ àgùntàn náà sọ pé kí Ṣúlámáítì jẹ́ káwọn jọ nasẹ̀ jáde, àmọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ò jẹ́ kó lọ. Kó má bàa lọ, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní kó lọ máa ṣọ́ àwọn ọgbà àjàrà. Kí nìdí tí wọn ò fi jẹ́ kó lọ? Ṣé torí pé wọn ò fọkàn tán an ni? Àbí wọ́n rò pé ó fẹ́ lọ ṣèṣekúṣe ni? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, wọ́n fẹ́ dáàbò bo àbúrò wọn ni, kó máa bàa fira rẹ̀ sípò tó lè mú kó ṣèṣekúṣe. (Orin Sól. 1:6; 2:​10-15) Ẹ̀kọ́ pàtàkì ni èyí jẹ́ fáwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó. Tó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe fi ara yín sípò tó léwu, kí ìfẹ́sọ́nà yín lè jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà. Ẹ má ṣe máa dá wà lẹ́yin nìkan. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú tẹ́ ẹ bá ń fìfẹ́ hàn síra yín, bí kò bá ṣáà ti ní ìwàkiwà nínú, àmọ́ ẹ máa yẹra fún àwọn ipò tó lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe.

yp 188 ¶2

Ki Ni Nipa Ti Ibalopọ Takọtabo Ṣaaju Igbeyawo?

Bi o ti wu ki o ri, wíwà ni oníwà-mímọ́ ṣe ju ríran èwe kan lọwọ lati yẹra fún awọn àbájáde amúnirẹ̀wẹ̀sì. Bibeli sọ nipa ọ̀dọ́ omidan kan tí ó duro ní oníwà-mímọ́ láìka ifẹ gbígbónájanjan tí ó ní fun ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ si. Gẹgẹ bi ìyọrísí rẹ̀, oun lè sọ pẹlu ìyagàn pe: “Ògiri ni mi, ọmú mi sì dabi ilé-ìṣọ́.” Oun kii ṣe ‘ẹnu ọ̀nà tí ń fì dirodiro’ tí ó ń fi pẹlu ìdẹ̀rùn ‘ṣísílẹ̀ gbayawu’ lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ oníwà pálapàla. Niti ìwàrere, oun dúró gẹgẹ bi ògiri odi aláìṣeéfòdá pẹlu awọn ilé-ìṣọ́ ti kò ṣeé wọ̀! Oun lẹ́tọ̀ọ́ lati di ẹni tí a pè ní “alailabawọn” tí oun sì lè sọ nipa ẹni ti yoo wa jẹ ọkọ rẹ̀ pe, “Lójú rẹ̀ mo dabi ẹni tí ó rí alaafia.” Alaafia inu oun tìkáraarẹ̀ ṣàfikún sí itẹlọrun tí ń bẹ laaarin awọn mejeeji.​—Orin Solomoni 6:​9, 10; 8:​9, 10.

yp2 33

Àwòkọ́ṣe​—Omidan Ará Ṣúnémù

Ọmọbìnrin ará Ṣúnémù, ìyẹn Ṣúlámáítì, mọ̀ pó yẹ kóun lo orí pípé bó bá dọ̀ràn ẹni tí ọkàn òun fẹ́. Ó sọ fáwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù pé: “Mo ti mú kí ẹ wá sábẹ́ ìbúra, . . . pé kí ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.” Omidan ará Ṣúnémù yìí mọ̀ pé kì í pẹ́ tí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni fi ń nípa lórí béèyàn ṣe ń ronú. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ̀ pé àwọn míì lè rọ òun láti gbà fẹ́ni tí kò yẹ kóun fẹ́. Àní bọ́rọ̀ ṣe rí lára òun fúnra ẹ̀ gan-an lè mú kó ṣe yíyàn tí kò tọ́. Nítorí náà, ọmọbìnrin ará Ṣúnémù náà dúró bí “ògiri.”​—Orin Sólómọ́nì 8:​4, 10.

Ṣéwọ náà máa ń ronú jinlẹ̀ bíi ti ọmọbìnrin ará Ṣúnémù, bó o bá ń ronú nípa ìfẹ́? Ṣóhun tó o bá mọ̀ pó tọ́ lo máa ń ṣe ni àbí bí nǹkan bá ṣe rí lára ẹ ló máa ń darí ẹ? (Òwe 2:​10, 11) Nígbà míì, àwọn èèyàn lè tì ẹ́ pé kó o máa fẹ́ ẹnì kan, nígbà tó ò tíì ṣe tán láti ṣègbéyàwó. Ó sì lè jẹ́ ìwọ fúnra ẹ lo máa ki ọrùn ara ẹ bọ irú àjọṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá rí ọkùnrin àti obìnrin kan tí wọ́n jọ ń fara wọn lọ́wọ́ lọ, ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kíwọ náà rẹ́ni máa fà ẹ́ lọ́wọ́ kiri? Ṣé ẹni tí ẹ̀sìn ẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ lo fẹ́ fẹ́? Ọmọbìnrin ará Ṣúnémù yẹn mọ ohun tó tọ́ bó bá dọ̀rọ̀ níní ìfẹ́ tòótọ́. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀!

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w15 1/15 29 ¶3

Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Àárín Tọkọtaya Lè Wà Pẹ́ Títí?

3 Ka Orin Sólómọ́nì 8:6. Sólómọ́nì fi gbólóhùn náà, “ọwọ́ iná Jáà” ṣàlàyé ìfẹ́, gbólóhùn náà sì kẹnú gan-an. Ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́ “ọwọ́ iná Jáà” torí pé Jèhófà ló dá ìfẹ́ yìí sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Jẹ́n. 1:​26, 27) Nígbà tí Ọlọ́run dá Éfà obìnrin àkọ́kọ́ tí ó sì fà á lé Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ ewì lo kọ́kọ́ jáde lẹ́nu Ádámù láti fi ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀. Ó sì dájú pé ọkàn Éfà náà fà mọ́ Ádámù, torí pé ara rẹ̀ ni Ọlọ́run ‘ti mú un wá.’ (Jẹ́n. 2:​21-23) Níwọ̀n bí Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti fi ìfẹ́ hàn síra wọn, a jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin àti obìnrin ní ìfẹ́ alọ́májàá tí kì í kùnà sí ara wọn.

NOVEMBER 24-30

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 1-2

Ọkàn Àwọn Tí “Ẹ̀ṣẹ̀ Wọ̀ Lọ́rùn” Lè Balẹ̀

ip-1 14 ¶8

Bàbá Kan Àtàwọn Ọlọ̀tẹ̀ Ọmọ Rẹ̀

8 Aísáyà ń bá iṣẹ́ tó ń jẹ́ lọ, ó sọ ọ̀rọ̀ líle sí orílẹ̀-èdè Júdà, pé: “Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ìṣìnà ti wọ̀ lọ́rùn, irú-ọmọ tí ń ṣebi, àwọn apanirun ọmọ! Wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n ti hùwà àìlọ́wọ̀ sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, wọ́n ti yí padà sẹ́yìn.” (Aísáyà 1:4) Ìwà burúkú lè ṣẹ́jọ dépò pé yóò dà bí ẹrù tó lè kánni lọ́rùn. Láyé Ábúráhámù, Jèhófà sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ Sódómù àti Gòmórà “rinlẹ̀ gidigidi.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20) Ohun tó jọ ìyẹn náà ló wá hàn kedere nínú ọ̀ràn àwọn ènìyàn Júdà báyìí, nítorí Aísáyà sọ pé “ìṣìnà ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn.” Síwájú sí i, ó tún pè wọ́n ní “irú-ọmọ tí ń ṣebi, àwọn apanirun ọmọ.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ará Júdà dà bí ọmọ tó ti ya pòkíì. Wọ́n ti “yí padà sẹ́yìn,” tàbí bí Bíbélì New Revised Standard Version ṣe sọ ọ́, wọ́n ti “dàjèjì pátápátá” sí Baba wọn.

ip-1 28-29 ¶15-17

“Ẹ Jẹ́ Kí A Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́”

15 Jèhófà wá túbọ̀ lo ohùn pẹ̀lẹ́tù tòun tìyọ́nú sí i. Ó sọ pé: “ ‘Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa,’ ni Jèhófà wí. ‘Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì; bí wọ́n tilẹ̀ pupa bí aṣọ pípọ́ndòdò, wọn yóò dà bí irun àgùntàn gẹ́lẹ́.’ ” (Aísáyà 1:18) Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣi ìkésíni tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹsẹ tó gbámúṣé yìí lóye. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì The New English Bible sọ pé, “Jẹ́ kí a jọ la ọ̀ràn yé ara wa”​—bíi pé ìhà méjèèjì ló ní láti jùmọ̀ gbà fúnra wọn kí wọ́n lè fìmọ̀ ṣọ̀kan. Kò rí bẹ́ẹ̀ o! Jèhófà kò lè jẹ̀bi rárá, áńbọ̀sìbọ́sí nínú bó ṣe bá àwọn ọlọ̀tẹ̀ alágàbàgebè wọ̀nyí lò. (Diutarónómì 32:​4, 5) Ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ kì í ṣe ti àpérò àjọgbà láàárín ojúgbà ẹni bí kò ṣe àpéjọ láti fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀. Bíi pé Jèhófà pe Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ ni.

16 Ìyẹn lè ṣe bí ẹní kani láyà, àmọ́ o, Jèhófà ni Onídàájọ́ tó láàánú tó sì níyọ̀ọ́nú jù lọ. Bó ṣe máa ń dárí jini tó kò láfiwé rárá ni. (Sáàmù 86:5) Òun nìkan ló lè kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì tó “rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò” kó sì fọ̀ wọ́n dànù, kó sì “sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.” Kò sí ìsapá ènìyàn, kò sọ́gbọ́n iṣẹ́ ìsìn téèyàn lè ta, kò sẹ́bọ, tàbí àdúrà tó lè mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Ìdáríjì Jèhófà nìkan ló lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù. Ọlọ́run a máa darí irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ jini níbàámu pẹ̀lú ìlànà tó gbé kalẹ̀, lára rẹ̀ sì ni ìrònúpìwàdà tòótọ́ látọkànwá.

17 Òdodo ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an tó bẹ́ẹ̀ tí Jèhófà fi fi ọ̀rọ̀ tó jọ ọ́ tún un sọ lọ́nà ewì pé, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó pupa bí “aṣọ pípọ́ndòdò,” yóò funfun bí irun àgùntàn tuntun, tí wọn kò tí ì pa láró. Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí a mọ̀ ni pé òun ni Olùdárí-ẹ̀ṣẹ̀-jini lóòótọ́, títí kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá, bó bá sáà ti rí i pé a ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Bí èyí bá ṣòro fún àwọn kan láti gbà gbọ́, tí wọ́n rò pé ọ̀ràn tiwọn ti tayọ ìyẹn, kí wọ́n wo àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mánásè. Ó ń dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì​—fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Síbẹ̀, ó ronú pìwà dà, ó sì rí ìdáríjì gbà. (2 Kíróníkà 33:​9-16) Jèhófà ń fẹ́ kí gbogbo wa mọ̀, títí kan àwọn tó ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, pé kò tíì pẹ́ jù fún wa láti “mú àwọn ọ̀ràn tọ́” láàárín àwa àti òun.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

ip-1 39 ¶9

A Gbé Ilé Jèhófà Lékè

9 Àmọ́ ṣá o, lónìí, àwọn ènìyàn Ọlọ́run kì í kóra jọ pọ̀ sórí òkè ńlá kankan tí a lè fojú rí, tó ní tẹ́ńpìlì olókùúta. Àwọn ọmọ ogun Róòmù ti pa tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Àti pé, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó yéni kedere pé àwòkọ́ṣe ni tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù àti àgọ́ ìjọsìn tó wà ṣáájú rẹ̀ jẹ́. Wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi kan tó jẹ́ tẹ̀mí, tó tóbi ju ìwọ̀nyẹn lọ, ìyẹn, “àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn.” (Hébérù 8:2) Àgọ́ tẹ̀mí yẹn jẹ́ ìṣètò fún títọ Jèhófà lọ fún ìjọsìn, nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (Hébérù 9:​2-10, 23) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, “òkè ńlá ilé Jèhófà” tí Aísáyà 2:2 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dúró fún ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà, tí a gbé lékè ní àkókò tiwa yìí. Àwọn tí ń kópa nínú ìjọsìn mímọ́ gaara kì í lọ péjọ pọ̀ sójú ibi kan ní pàtó; ṣe ni wọ́n ń péjọ pọ̀ fún ìjọsìn oníṣọ̀kan.

DECEMBER 1-7

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 3-5

Jèhófà Retí Pé Káwọn Èèyàn Òun Máa Ṣègbọràn sí Òun

ip-1 73-74 ¶3-5

Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!

3 Bóyá ńṣe ni Aísáyà kọ àkàwé yìí lórin sétígbọ̀ọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ni o tàbí kò kọ ọ́ lórin, ó dájú pé ó gbàfiyèsí wọn. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló mọ̀ nípa àjàrà gbígbìn, àpèjúwe Aísáyà sì ṣe kedere, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an ló sọ. Gẹ́lẹ́ bí ìṣe àwọn tí ń gbin àjàrà lóde òní, ọlọ́gbà àjàrà yìí kò gbin kóró èso àjàrà, ńṣe lo lọ́ ègé igi tàbí èèhù láti ara àjàrà mìíràn, “ààyò” tàbí ojúlówó “àjàrà pupa.” Ibi tó yẹ wẹ́kú ló ṣe ọgbà àjàrà rẹ̀ sí, “ẹ̀gbẹ́ òkè kékeré eléso,” níbi tí ọgbà àjàrà yóò ti ṣe dáadáa.

4 Iṣẹ́ àṣekára ló máa ń gbà kí ọgbà àjàrà tó lè méso jáde. Aísáyà sọ nípa bí ọlọ́gbà náà ṣe “walẹ̀ rẹ̀, tó sì kó àwọn òkúta rẹ̀ kúrò”​—iṣẹ́ líle, tó gbomi mu! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn tó tóbi lára òkúta yẹn ló fi “kọ́ ilé gogoro.” Láyé àtijọ́, irú ilé gogoro bẹ́ẹ̀ làwọn olùṣọ́ máa ń jókòó sí láti ṣọ́ ọ̀gbìn ibẹ̀ nítorí àwọn olè tàbí àwọn ẹranko. Bákan náà, ó fi òkúta mọ ọgbà ààbò sí ẹsẹ̀ àwọn ipele títẹ́jú tí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà ní. (Aísáyà 5:5) Wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ kí àgbàrá má bàa gbá ọ̀rá ilẹ̀ náà lọ.

5 Pẹ̀lú gbogbo bí ọlọ́gbà náà ṣe ṣiṣẹ́ kárakára láti dáàbò bo ọgbà àjàrà rẹ̀ yìí, ó tọ́ pé kó máa retí pé kó so èso. Ìyẹn ló fi gbẹ́ ibi ìfúntí sílẹ̀ dè é. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó rí irè oko tó ń retí? Rárá o, àjàrà ìgbẹ́ ni ọgbà àjàrà rẹ̀ so.

ip-1 76 ¶8-9

Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!

8 Aísáyà pe Jèhófà tó ni ọgbà àjàrà náà ní “ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́.” (Aísáyà 5:1) Àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Aísáyà àti Ọlọ́run ló fi lè lo ọ̀rọ̀ tó ṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ fún Un. (Fi wé Jóòbù 29:4; Sáàmù 25:14.) Àmọ́, ìfẹ́ tí wòlíì yìí fẹ́ Ọlọ́run kò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìfẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ “ọgbà àjàrà” rẹ̀​—orílẹ̀-èdè tó “gbìn.”​—Fi wé Ẹ́kísódù 15:17; Sáàmù 80:​8, 9.

9 Jèhófà ‘gbin’ orílẹ̀-èdè rẹ̀ sí ilẹ̀ Kénáánì, ó sì fún wọn ní àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀, tó jẹ́ bí ògiri tó dáàbò bò wọ́n, kí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù má bàa kó ìwà ìbàjẹ́ ràn wọ́n. (Ẹ́kísódù 19:​5, 6; Sáàmù 147:​19, 20; Éfésù 2:14) Síwájú sí i, Jèhófà fún wọn ní àwọn onídàájọ́, àlùfáà, àti wòlíì tí yóò máa kọ́ wọn. (2 Àwọn Ọba 17:13; Málákì 2:7; Ìṣe 13:20) Nígbà tí ogun ń bá Ísírẹ́lì fínra, Jèhófà gbé àwọn olùdáǹdè dìde fún wọn. (Hébérù 11:​32, 33) Ìyẹn ni Jèhófà fi béèrè pé: “Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀?”

w06 6/15 18 ¶1

“Bójú Tó Àjàrà Yìí”!

Aísáyà fi “ilé Ísírẹ́lì” wé ọgbà àjàrà tó di èyí tó ń so “èso àjàrà ìgbẹ́” tàbí èso kíkẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. (Aísáyà 5:​2, 7) Èso àjàrà ìgbẹ́ máa ń kéré gan-an sí èso àjàrà táwọn àgbẹ̀ máa ń gbìn, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ níṣu lára torí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kóró ló ń gba gbogbo inú rẹ̀. Àjàrà ìgbẹ́ kò dára fún wáìnì ṣíṣe, bẹ́ẹ̀ ni kò dára fún jíjẹ. Irú àjàrà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tó dára gan-an láti fi ṣàpèjúwe orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà náà, èyí tó kún fún ìwà ìrúfin dípò kó máa so èso òdodo. Síso tí wọ́n ń so èso tí kò wúlò kì í ṣe ẹ̀bi Jèhófà tó jẹ́ olóko. Gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe ni Jèhófà ti ṣe kí orílẹ̀-èdè náà lè méso jáde. Ìyẹn ló fi béèrè pé: “Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀?”​—Aísáyà 5:4.

w06 6/15 18 ¶2

“Bójú Tó Àjàrà Yìí”!

Níwọ̀n bí àjàrà Ísírẹ́lì, ìyẹn àwọn èèyàn Jèhófà, kò ti so èso, Jèhófà sọ fún wọn pé òun máa wó ògiri tóun mọ láti fi dáàbò bò wọ́n. Ó lóun ò ní rẹ́wọ́ àjàrà ìṣàpẹẹrẹ náà mọ́, òun ò sì ní roko rẹ̀ mọ́. Òjò tí àjàrà náà nílò kò ní rọ̀, ẹ̀gún àti epò yóò sì kún bo ọgbà àjàrà náà.​—Aísáyà 5:​5, 6.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

ip-1 80 ¶18-19

Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!

18 Ti Jèhófà ni gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ jẹ́ látilẹ̀wá. Gbogbo ìdílé ni Ọlọ́run fún lógún tirẹ̀, wọ́n sì lè fi háyà tàbí kí wọ́n yá tẹlòmíràn lò, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ tà á “fún àkókò títí lọ fáàbàdà.” (Léfítíkù 25:23) Òfin yìí ṣèdíwọ́ fún fífọwọ́ ọlá gbáni lójú, bíi pé kẹ́nì kan ràgà bo gbogbo ilẹ̀. Ó tún gba àwọn ìdílé lọ́wọ́ dídi òtòṣì paraku. Àmọ́, ńṣe làwọn kan ní Júdà ń fi ìwọra rú òfin tí Ọlọ́run ṣe lórí ọ̀ràn dúkìá. Míkà kọ̀wé pé: “Ojú wọn sì ti wọ pápá, wọ́n sì ti já wọn gbà; àti àwọn ilé pẹ̀lú, wọ́n sì ti gbà wọ́n; wọ́n sì ti lu abarapá ọkùnrin àti agbo ilé rẹ̀ ní jìbìtì, ènìyàn àti ohun ìní àjogúnbá rẹ̀.” (Míkà 2:2) Ṣùgbọ́n Òwe 20:21 kìlọ̀ pé: “Ogún ni a ń fi ìwọra kó jọ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún.”

19 Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò gba gbogbo ohun tí oníwọra wọ̀nyẹn ti fi bìrìbìrì kó jọ. Ilé tí wọ́n já gbà yóò wà “láìsí olùgbé.” Èso táṣẹ́rẹ́ ni ilẹ̀ tójú wọn wọ̀ yóò so. Kò sọ bí ègún yìí ṣe máa ṣẹ àti ìgbà tí yóò ṣẹ. Bóyá apákan rẹ̀, ó kéré tán, tọ́ka sí ohun tó máa bá wọn lọ́jọ́ iwájú, nígbà ìgbèkùn ní Bábílónì.​—Aísáyà 27:10.

DECEMBER 8-14

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 6-8

“Èmi Nìyí! Rán Mi!”

ip-1 93-94 ¶13-14

Jèhófà Ọlọ́run Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Mímọ́ Rẹ̀

13 Ẹ jẹ́ ká jọ fetí sílẹ̀ pẹ̀lú Aísáyà. “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn Jèhófà tí ó wí pé: ‘Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?’ Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: ‘Èmi nìyí! Rán mi.’ ” (Aísáyà 6:8) Ó dájú pé ńṣe ni Jèhófà béèrè ìbéèrè rẹ̀ kí Aísáyà lè dáhùn, torí yàtọ̀ sí i kò tún sí ènìyàn mìíràn tó jẹ́ wòlíì nínú ìran yẹn. Dájúdájú, ńṣe ni Jèhófà ń ké sí Aísáyà láti di ońṣẹ́ òun. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Jèhófà fi béèrè pé, “Ta . . . ni yóò lọ fún wa?” Bí Jèhófà ṣe yí kúrò lórí lílo “èmi,” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ atọ́ka ẹnì kan ṣoṣo, tó sì lo “wa,” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ atọ́ka ẹlẹ́ni púpọ̀, fi hàn pé ó kéré tán, ó ti mú ẹnì kan mọ́ra. Ta ni? Òun ha kọ́ ni Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, tó di ẹni tí ń jẹ́ Jésù Kristi? Bẹ́ẹ̀ ni, Ọmọ yìí kan náà ni Ọlọ́run sọ fún pé, “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Òwe 8:​30, 31) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí Jèhófà ní wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nínú ààfin ọ̀run náà.​—Jòhánù 1:14.

14 Ojú ẹsẹ̀ mà ni Aísáyà fèsì o! Ohun yòówù kí iṣẹ́ náà jẹ́, ó fèsì kíákíá pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” Kò sì béèrè ohun tó máa jẹ́ ère tòun bóun bá tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yẹn. Àpẹẹrẹ àtàtà ni ẹ̀mí ìmúratán tó ní jẹ́ fún gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí, tí iṣẹ́ wọn jẹ́ láti wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Bíi Aísáyà, wọn kò jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọn, wọ́n sì ṣàṣeparí iṣẹ́ jíjẹ́ “ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọ etí dídi sí wọn. Tìgboyàtìgboyà ni wọ́n sì fi ń bá iṣẹ́ wọn lọ gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti ṣe, nítorí wọ́n mọ̀ pé, ẹni gíga jù lọ ló gbéṣẹ́ lé àwọn lọ́wọ́.

ip-1 95 ¶15-16

Jèhófà Ọlọ́run Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Mímọ́ Rẹ̀

15 Jèhófà wá ṣàlàyé ohun tí Aísáyà yóò sọ àti èsì tó máa rí gbà, pé: “Lọ, kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ní àgbọ́túngbọ́, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe lóye; kí ẹ sì rí ní àrítúnrí, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ní ìmọ̀ kankan.’ Mú kí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́, sì mú kí etí wọn gan-an gíràn-án, sì lẹ ojú wọn gan-an pọ̀, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kí ọkàn-àyà wọn má sì lóye, kí wọ́n má sì yí padà ní tòótọ́, kí wọ́n má sì rí ìmúláradá gbà fún ara wọn.” (Aísáyà 6:​9, 10) Ṣé pé kí Aísáyà kàn máa sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu àwọn Júù, kó sọ̀rọ̀ sí wọn ṣàkàṣàkà kí wọ́n sì yarí, kí wọ́n dọ̀tá Jèhófà? Rárá o! Ìbátan Aísáyà ni wọ́n, ojú mọ̀lẹ́bí ló fi ń wò wọ́n. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ń sọ ohun tí yóò jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn wọ̀nyẹn sí ọ̀rọ̀ òun, bó ti wù kí Aísáyà sapá tó lẹ́nu iṣẹ́ yẹn.

16 Àwọn èèyàn yẹn ló lẹ̀bi. “Àgbọ́túngbọ́” ni Aísáyà yóò mú kí wọ́n gbọ́, ṣùgbọ́n wọn kò ní gba iṣẹ́ rẹ̀, kò sì ní yé wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn yóò ya olóríkunkun àti elétí dídi àfi bí ẹni pé afọ́jú àti odi ni wọ́n. Lílọ tí Aísáyà ń lọ sọ́dọ̀ “àwọn ènìyàn yìí” lemọ́lemọ́ ni yóò fi jẹ́ kí wọ́n fi hàn pé ńṣe làwọn ò fẹ́ kí òye ohun tó ń sọ yé àwọn. Wọn yóò fúnra wọn fi hàn pé ńṣe làwọn kọ etí dídi sí iṣẹ́ tí Aísáyà ń jẹ́ fáwọn​—iṣẹ́ Ọlọ́run. Báwọn èèyàn mà ṣe ń ṣe gẹ́lẹ́ lónìí nìyẹn o! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló ń kọ̀ láti gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀.

ip-1 99 ¶23

Jèhófà Ọlọ́run Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Mímọ́ Rẹ̀

23 Fífà tí Jésù fa ọ̀rọ̀ Aísáyà yọ, ńṣe ló ń fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ lọ́jọ́ tòun. Irú ìṣarasíhùwà tí àwọn Júù ayé Aísáyà ní làwọn èèyàn yìí ní gbogbo gbòò ní. Wọ́n di ojú, wọ́n tún di etí wọn sí iṣẹ́ tó ń jẹ́, àwọn náà sì pa run pẹ̀lú. (Mátíù 23:​35-38; 24:​1, 2) Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọ̀gágun Títù kó agbo ọmọ ogun Róòmù wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. Àmọ́ ṣá, àwọn kan gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù, wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Jésù sọ pé “aláyọ̀” ni àwọn yẹn. (Mátíù 13:​16-23, 51) Ó ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé nígbà tí wọ́n bá rí i tí “àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká” kí wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Lúùkù 21:​20-22) Bí ìgbàlà ṣe dé fún “irúgbìn mímọ́” tó lo ìgbàgbọ́, táa sì sọ di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” nìyẹn.​—Gálátíà 6:16.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w06 12/1 9 ¶4

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà​—Apá Kìíní

7:​3, 4​—Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo Áhásì Ọba tó jẹ́ ẹni burúkú? Àwọn Ọba ilẹ̀ Síríà àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti gbìmọ̀ pọ̀ láti mú Áhásì Ọba kúrò lórí oyè kí wọ́n sì fi ẹni tí wọ́n á lè máa darí bó ṣe wù wọ́n rọ́pò rẹ̀, ìyẹn ọmọkùnrin Tábéélì, tí kì í ṣe àtọmọdọ́mọ Dáfídì. Ètekéte Èṣù yìí yóò ṣèdíwọ́ fún májẹ̀mú Ìjọba tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá. Kí ohunkóhun má bàa ṣẹlẹ̀ sí ìran tí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” yóò ti wá ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Áhásì.​—Aísáyà 9:6.

DECEMBER 15-21

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 9-10

Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa “Ìmọ́lẹ̀ Tó Mọ́lẹ̀ Yòò”

ip-1 125-126 ¶16-17

A Ṣèlérí Ọmọ Aládé Àlàáfíà

16 Bẹ́ẹ̀ ni, àkókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristi lórí ilẹ̀ ayé ni “ẹ̀yìn ìgbà náà” tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Gálílì ni Jésù ti lo èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ẹkùn Gálílì ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí polongo pé: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mátíù 4:17) Gálílì ló ti ṣe Ìwàásù olókìkí tó ṣe lórí Òkè, ibẹ̀ ló ti yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ibẹ̀ ló ti ṣe àkọ́ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, ibẹ̀ ló sì ti fara han nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọmọlẹ́yìn lẹ́yìn tó jíǹde. (Mátíù 5:1–7:27; 28:​16-20; Máàkù 3:​13, 14; Jòhánù 2:​8-11; 1 Kọ́ríńtì 15:6) Lọ́nà yìí, Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ nípa bíbọlá fún “ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì.” Àmọ́ ṣá o, Jésù kò fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ mọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn Gálílì. Bí Jésù ṣe wàásù káàkiri gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó “mú kí a bọlá fún” gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, títí kan Júdà.

17 “Ìmọ́lẹ̀ ńlá kan” tí Mátíù sọ pé ó wà ní Gálílì ńkọ́? Inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà náà ló ti fa ìyẹn yọ. Aísáyà kọ̀wé pé: “Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ní ti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ibú òjìji, àní ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.” (Aísáyà 9:2) Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, èké àwọn abọ̀rìṣà ti bo ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tún wá dá kún un nípa wíwonkoko mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ inú ẹ̀sìn tiwọn, èyí tí wọ́n fi “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀.” (Mátíù 15:6) Àwọn “afọ́jú afinimọ̀nà” táwọn onírẹ̀lẹ̀ ń tọ̀ lẹ́yìn ń kó ìnira àti ṣìbáṣìbo bá wọn. (Mátíù 23:​2-4, 16) Nígbà tí Jésù, Mèsáyà, fara hàn, ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírẹ̀lẹ̀ là lọ́nà ìyanu. (Jòhánù 1:​9, 12) Ńṣe ló ṣe wẹ́kú bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe iṣẹ́ tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn ìbùkún ìràpadà rẹ̀, pé wọ́n jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ńlá” náà.​—Jòhánù 8:12.

ip-1 126-128 ¶18-19

A Ṣèlérí Ọmọ Aládé Àlàáfíà

18 Ìdí ayọ̀ àwọn tó kọbi ara sí ìmọ́lẹ̀ náà pọ̀ gan-an ni. Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè náà di púpọ̀ sí i; o ti sọ ayọ̀ yíyọ̀ di púpọ̀ fún un. Wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí a ti ń yọ̀ ní àkókò ìkórè, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó kún fún ìdùnnú nígbà tí wọ́n ń pín ohun ìfiṣèjẹ.” (Aísáyà 9:3) Ìwàásù Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú kí àwọn olùfẹ́ òdodo jáde wá, wọ́n ń fẹ́ láti sin Jèhófà ní ẹ̀mí àti òtítọ́. (Jòhánù 4:24) Kò pọ́dún mẹ́rin rárá tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn fi di ẹlẹ́sìn Kristẹni. Ẹgbẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n batisí lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, “iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún.” (Ìṣe 2:41; 4:4) Bí àwọn àpọ́sítélì ṣe ń fi ìtara tànmọ́lẹ̀ náà kiri, “iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn . . . ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù; ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà.”​—Ìṣe 6:7.

19 Ìbísí yìí mú inú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dùn gan-an ni, àfi bí ìdùnnú ẹni tó rí ìkórè wọ̀ǹtì-wọnti tàbí tẹni tí wọ́n pín ohun ìfiṣèjẹ oníyebíye fún lẹ́yìn ogun àjàṣẹ́gun kan. (Ìṣe 2:​46, 47) Láìpẹ́, Jèhófà mú kí ìmọ́lẹ̀ náà tàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 14:27) Èyí sì mú káwọn ènìyàn inú ẹ̀yà gbogbo máa yọ̀ pé ọ̀nà láti tọ Jèhófà lọ tí ṣí sílẹ̀ fáwọn náà.​—Ìṣe 13:48.

ip-1 128-129 ¶20-21

A Ṣèlérí Ọmọ Aládé Àlàáfíà

20 Títí gbére ni àbájáde ìgbòkègbodò Mèsáyà yóò máa báṣẹ́ lọ, gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn látinú ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tẹ̀ lé e pé: “Àjàgà ẹrù wọn àti ọ̀pá tí ó wà ní èjìká wọn, ọ̀gọ ẹni tí ń kó wọn ṣiṣẹ́, ni ìwọ ti ṣẹ́ sí wẹ́wẹ́ bí ti ọjọ́ Mídíánì.” (Aísáyà 9:4) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà ayé Aísáyà, ṣe ni àwọn ará Mídíánì lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Móábù láti tan Ísírẹ́lì sọ́fìn ẹ̀ṣẹ̀. (Númérì 25:​1-9, 14-18; 31:​15, 16) Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ará Mídíánì han àwọn ọmọ Ísírẹ́lì léèmọ̀ fọ́dún méje, wọ́n ń ya lu àwọn abúlé àti oko wọn, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rù. (Àwọn Onídàájọ́ 6:​1-6) Àmọ́ ṣá o, Jèhófà tipasẹ̀ Gídéónì ìránṣẹ́ rẹ̀ rẹ́yìn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíánì. Lẹ́yìn “ọjọ́ Mídíánì” yẹn, kò tún sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn ará Mídíánì tún fìyà jẹ àwọn ènìyàn Jèhófà mọ́. (Àwọn Onídàájọ́ 6:​7-16; 8:28) Láìpẹ́, Gídéónì ńlá náà, Jésù Kristi, yóò ṣá àwọn ọ̀tá ènìyàn Jèhófà tòde òní balẹ̀. (Ìṣípayá 17:14; 19:​11-21) Lẹ́yìn náà, òun yóò wá fi agbára Jèhófà, láìṣe nípa mímọ̀-ọ́n ṣe tènìyàn, ṣẹ́gun wọn porogodo, tí wọn ò fi ní gbérí mọ́ láé, “bí ti ọjọ́ Mídíánì.” (Àwọn Onídàájọ́ 7:​2-22) Láéláé, àjàgà àwọn aninilára ò tún ní wá sí ọrùn àwọn ènìyàn Ọlọ́run mọ́!

21 Iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ń ṣe yìí kò fi hàn pé ó ń gbárùkù ti ogun. Ọmọ Aládé Àlàáfíà ni Jésù tó jíǹde jẹ́, pípa tí yóò sì pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run ni yóò fi mú kí àlàáfíà jọba títí ayé. Aísáyà wá sọ nípa bí ìhámọ́ra ogun ṣe di sísun ráúráú, ó ní: “Gbogbo bàtà abokókósẹ̀ ti ẹni tí ń fi ìmìjìgìjìgì fẹsẹ̀ kilẹ̀ àti aṣọ àlàbora tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀ ti wá wà fún sísun gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún iná.” (Aísáyà 9:5) Jìgìjìgì tí ilẹ̀ ń mì bí àwọn sójà ṣe ń fi bàtà abokókósẹ̀ kilẹ̀ wì-wì-wì kò ní wáyé mọ́ láé. Láéláé, a kò ní rí ẹ̀wù ẹ̀jẹ̀ táwọn ògbójú jagunjagun máa ń wọ̀ mọ́. Kò ní sógun mọ́!​—Sáàmù 46:9.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

ip-1 130 ¶23-24

A Ṣèlérí Ọmọ Aládé Àlàáfíà

23 Ẹní bá ń fúnni nímọ̀ràn tàbí tó ń báni dámọ̀ràn ni agbani-nímọ̀ràn. Jésù Kristi fúnni ní ìmọ̀ràn àgbàyanu nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. A kà á nínú Bíbélì pé, “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) Ọlọ́gbọ́n Agbani-nímọ̀ràn àti agbatẹnirò ló jẹ́, ẹni tó lóye ẹ̀dá ènìyàn lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀. Ìmọ̀ràn rẹ̀ kò mọ sí ti bíbániwí tàbí kó nani lẹ́gba ọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìtọ́ni àti àmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ ló máa ń jẹ́. Ìmọ̀ràn Jésù jẹ́ àgbàyanu nítorí pé gbogbo ìgbà ló máa ń jẹ́ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n, pípé, tí kò lè kùnà. Bí èèyàn bá fi í sílò, ìyè ayérayé ló ń sinni lọ.​—Jòhánù 6:68.

24 Ìmọ̀ràn Jésù kì í ṣe èyí tó kàn tinú làákàyè rẹ̀ wá. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n Sólómọ́nì náà ni Orísun ti Jésù. (1 Àwọn Ọba 3:​7-14; Mátíù 12:42) Ó yẹ kí àpẹẹrẹ ti Jésù sún àwọn olùkọ́ni àti agbani-nímọ̀ràn nínú ìjọ Kristẹni láti máa gbé ìtọ́ni wọn karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.​—Òwe 21:30.

DECEMBER 22-28

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 11-13

Kí Ni Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa Ẹni Tó Máa Jẹ́ Mèsáyà Náà?

ip-1 159 ¶4-5

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

4 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà ayé Aísáyà, àwọn Hébérù mìíràn tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì ti sọ ọ́ pé Mèsáyà, Aṣáájú tòótọ́ tí Jèhófà yóò rán sí Ísírẹ́lì, ń bọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 49:10; Diutarónómì 18:18; Sáàmù 118:​22, 26) Wàyí o, Jèhófà lo Aísáyà láti ṣe àlàyé síwájú sí i. Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ̀ka igi kan yóò sì yọ láti ara kùkùté Jésè; àti láti ara gbòǹgbò rẹ̀, èéhù kan yóò máa so èso.” (Aísáyà 11:1; fi wé Sáàmù 132:11.) “Ẹ̀ka igi” àti “èéhù” pa pọ̀ fi hàn pé Mèsáyà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jésè nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ Dáfídì, ẹni tí wọ́n fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 16:13; Jeremáyà 23:5; Ìṣípayá 22:16) Nígbà tí Mèsáyà tòótọ́ bá dé, ìyẹn “èéhù” láti ilé Dáfídì yìí, èso rere ni yóò so.

5 Jésù ni Mèsáyà táa ṣèlérí yẹn. Ọ̀rọ̀ Aísáyà 11:1 ni Mátíù òǹkọ̀wé ìhìn rere ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé pípè tí wọ́n ń pe Jésù ní “ará Násárétì” mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì ṣẹ. Ìlú Násárétì ni wọ́n ti tọ́ Jésù dàgbà, ìyẹn ni wọ́n fi ń pè é ní ará Násárétì, ó sì jọ pé orúkọ yìí tan mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “èéhù” nínú Aísáyà 11:1.​—Mátíù 2:​23, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Lúùkù 2:​39, 40.

ip-1 159 ¶6

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

6 Irú alákòóso wo ni Mèsáyà yóò jẹ́? Ṣé yóò ya òṣìkà, aṣetinú-ẹni bíi ará Ásíríà tó pa ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá níhà àríwá run ni? Rárá o. Aísáyà sọ nípa Mèsáyà pé: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà; ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísáyà 11:​2, 3a) Òróró kọ́ ni wọ́n fi yan Mèsáyà, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni. Èyí wáyé nígbà tí Jésù ṣe batisí, tí Jòhánù Olùbatisí rí i tí ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà sórí Jésù. (Lúùkù 3:22) Ẹ̀mí Jèhófà “bà lé” Jésù, ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn nínú bó ṣe ń fi ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ràn, agbára ńlá, àti ìmọ̀ ṣe àwọn nǹkan. Àwọn àgbàyanu ànímọ́ tó yẹ alákòóso gan-an nìwọ̀nyí!

ip-1 160 ¶8

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

8 Kí ni ìbẹ̀rù Jèhófà tí Mèsáyà ní? Ó dájú pé Ọlọ́run kò da jìnnìjìnnì bo Jésù, kó wá di pé ẹ̀rù ìbáwí rẹ̀ ló ń bà á. Kàkà bẹ́ẹ̀, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni Mèsáyà fi bẹ̀rù Ọlọ́run, ó fi ìfẹ́ bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un. Olùbẹ̀rù Ọlọ́run a máa fẹ́ láti “ṣe ohun tí ó wù ú” ní gbogbo ìgbà, bí Jésù ti ṣe. (Jòhánù 8:29) Nínú ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe, Jésù kọ́ni pé kò sóhun tó ń múni láyọ̀ bíi pé kéèyàn máa fi ojúlówó ìbẹ̀rù Jèhófà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ojoojúmọ́.

ip-1 160 ¶9

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

9 Aísáyà túbọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ànímọ́ Mèsáyà pé: “Kì yóò . . . ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́.” (Aísáyà 11:3b) Ká ní o fẹ́ rojọ́ ní kóòtù, inú rẹ kò ha ní dùn tóo bá rí irú adájọ́ yìí? Bí Mèsáyà ṣe jẹ́ Onídàájọ́ gbogbo aráyé, rírojọ́ èké, lílo ọgbọ́n àyínìke ní kóòtù, àgbọ́sọ, tàbí àwọn ohun mìíràn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, bíi jíjẹ́ ọlọ́rọ̀, kò lè nípa lórí rẹ̀. Ó rí àṣírí gbogbo ẹ̀tàn, ó ń wò ré kọjá ìrí ojú lásán, ó sì ń fòye mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” “ọkùnrin tó fara sin.” (1 Pétérù 3:​4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àpẹẹrẹ títayọ tí Jésù fi lélẹ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe fún gbogbo àwọn táa bá ní kí wọ́n bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́ nínú ìjọ Kristẹni.​—1 Kọ́ríńtì 6:​1-4.

ip-1 161 ¶11

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

11 Nígbà tí ìbáwí tọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ó bá wọn wí lọ́nà tó gbà ṣàǹfààní fún wọn jù lọ, èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ dáradára fáwọn alàgbà Kristẹni. Àmọ́, ìdájọ́ mímúná ní ń bẹ fáwọn aṣebi ní tiwọn. Nígbà tí Ọlọ́run yóò bá pe ètò àwọn nǹkan yìí wá jíhìn, ńṣe ni Mèsáyà máa fi ohùn ọlá àṣẹ rẹ̀ “lu ilẹ̀ ayé,” nípa pípàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ẹni burúkú run. (Sáàmù 2:9; fi wé Ìṣípayá 19:15.) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, kò ní ṣẹ́ ku ẹni burúkú kankan tí yóò tún máa dí àlàáfíà ayé lọ́wọ́ mọ́. (Sáàmù 37:​10, 11) Jésù lágbára láti ṣe é láṣeyọrí nítorí pé òdodo àti ìṣòtítọ́ ló sán mọ́ ìgbáròkó àti abẹ́nú rẹ̀ bí ìgbànú.​—Sáàmù 45:​3-7.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

ip-1 165-166 ¶16-18

Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso Mèsáyà

16 Ìgbà tí Sátánì ṣàṣeyọrí láti sún Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà ní Édẹ́nì ni àtakò kọ́kọ́ dìde sí ìjọsìn tòótọ́. Títí dòní, Sátánì kò tíì jáwọ́ nínú ète rẹ̀ láti yí iye èèyàn tó bá lè ṣeé ṣe fún un padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Jèhófà kò ní gbà kí ìjọsìn tòótọ́ pa rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Orúkọ rẹ̀ rọ̀ mọ́ ọn, ọ̀ràn àwọn olùjọsìn rẹ̀ sì jẹ ẹ́ lógún pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lo Aísáyà láti ṣe ìlérí pàtàkì yìí pé: “Yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé gbòǹgbò Jésè yóò wà tí yóò dìde dúró gẹ́gẹ́ bí àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá yóò yíjú sí láti ṣe ìwádìí, ibi ìsinmi rẹ̀ yóò sì di ológo.” (Aísáyà 11:10) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Dáfídì fi ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè yẹn, jẹ́ àmì tí ń pe àfiyèsí àwọn olóòótọ́ àṣẹ́kù lára àwọn Júù tó fọ́n ká pé kí wọ́n padà sílé láti tún tẹ́ńpìlì kọ́.

17 Ṣùgbọ́n, ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà tọ́ka sí ju ìyẹn lọ o. Bí a ṣe rí i tẹ́lẹ̀, ó tọ́ka sí ìṣàkóso Mèsáyà, Aṣáájú tòótọ́ kan ṣoṣo táwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ Aísáyà 11:10 yọ láti fi hàn pé, láyé ìgbà tirẹ̀ lọ́hùn-ún, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yóò láyè tiwọn nínú ìjọ Kristẹni. Nínú ìwé tó kọ, ó fa ọ̀rọ̀ ẹsẹ yìí yọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì Septuagint, pé: “Aísáyà . . . wí pé: ‘Gbòǹgbò Jésè yóò wà, ẹnì kan tí ń dìde láti ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì wà; òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbé ìrètí wọn kà.’ ” (Róòmù 15:12) Ẹ̀wẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yìí tilẹ̀ tún rìn jìnnà jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó dé ọjọ́ tiwa yìí, nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń fi ìfẹ́ wọn sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn àṣẹ́kù tó jẹ́ arákùnrin Mèsáyà.​—Aísáyà 61:​5-9; Mátíù 25:​31-40.

18 Nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà lóde òní, “ọjọ́ yẹn” tí Aísáyà ń tọ́ka sí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Mèsáyà gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run lọ́dún 1914. (Lúùkù 21:10; 2 Tímótì 3:​1-5; Ìṣípayá 12:10) Láti ìgbà yẹn wá ni Jésù Kristi ti di àmì àfiyèsí tó hàn kedere, ibi ìkójọpọ̀, fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí àti àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbogbo tó ń yán hànhàn fún ìjọba òdodo. Lábẹ́ ìdarí Mèsáyà yìí, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:14; Máàkù 13:10) Agbára ìhìn rere yìí sì kọ yọyọ. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” ló ń jọ̀wọ́ ara wọn fún Mèsáyà nípa dídarapọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. (Ìṣípayá 7:9) Bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ṣe túbọ̀ ń dara pọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ́kù nínú “ilé àdúrà” Jèhófà nípa tẹ̀mí, ṣe ni wọ́n ń fi kún ògo “ibi ìsinmi” Mèsáyà náà, tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Ọlọ́run.​—Aísáyà 56:7; Hágáì 2:7.

DECEMBER 29–JANUARY 4

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 14-16

Ọ̀tá Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ò Ní Lọ Láìjìyà

ip-1 180 ¶16

Jèhófà Tẹ́ Ìlú Agbéraga

16 Èyí kò ṣẹlẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa. Síbẹ̀, ó ṣe kedere lóde òní pé gbogbo ohun tí Aísáyà sọ nípa Bábílónì ló ti ṣẹ. Ẹnì kan tó jẹ́ alálàyé lórí Bíbélì sọ nípa Bábílónì pé, “ní báyìí, ahoro àti òkìtì àlàpà tó lọ súà ni, ó sì ti wà bẹ́ẹ̀ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá.” Ó tún wá fi kún un pé: “Èèyàn ò lè máa wo gbogbo èyí kó máà rántí bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà àti ti Jeremáyà ṣe ní ìmúṣẹ tó ṣe rẹ́gí gan-an.” Ó dájú pé, nígbà ayé Aísáyà, kò sẹ́ni tó jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Bábílónì yóò ṣubú, pé yóò sì wá dahoro níkẹyìn. Àní sẹ́, igba ọdún lẹ́yìn tí Aísáyà kọ̀wé rẹ̀ ni Bábílónì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn Mídíà àti Páṣíà! Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà ló sì tó dahoro. Ǹjẹ́ èyí kò fún ìgbàgbọ́ wa lókun ní ti pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí? (2 Tímótì 3:16) Ẹ̀wẹ̀, níwọ̀n bí Jèhófà ti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti sọ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn ṣẹ, ó dá wa lójú hán-únhán-ún pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí kò tíì ṣẹ ṣì ń bọ̀ wá ṣẹ bó bá tákòókò lójú Ọlọ́run.

ip-1 184 ¶24

Jèhófà Tẹ́ Ìlú Agbéraga

24 Nínú Bíbélì, wọ́n fi àwọn tó jọba láti ìlà ìdílé Dáfídì wé ìràwọ̀. (Númérì 24:17) Orí Òkè Síónì làwọn “ìràwọ̀” wọ̀nyẹn máa ń jókòó sí ṣàkóso, bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Dáfídì. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì ti kọ́ tẹ́ńpìlì sí Jerúsálẹ́mù, Síónì wá dorúkọ tó wà fún gbogbo ìlú yẹn. Lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, gbogbo ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló gbọ́dọ̀ lọ sí Síónì lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún. Bí ibẹ̀ ṣe di “òkè ńlá ìpàdé” nìyẹn. Bí Nebukadinésárì sì ṣe pinnu láti tẹ àwọn ọba Jùdíà lórí ba, kó sì wá kó wọn kúrò lórí òkè yẹn, ńṣe ló ń gbé ara rẹ̀ lékè “àwọn ìràwọ̀” wọ̀nyẹn. Kò gbé ògo ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí wọn fún Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká kúkú sọ pé ó fi ìgbéraga gbé ara rẹ̀ sí ipò Jèhófà ni.

ip-1 189 ¶1

Ohun Tí Jèhófà Pinnu Láti Ṣe sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè

JÈHÓFÀ lè lo àwọn orílẹ̀-èdè láti fi jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ níyà nítorí ìwà burúkú wọn. Síbẹ̀ náà, kò ní gbójú fo ìwà ìkà láìnídìí, ìgbéraga, àti ìwà kèéta táwọn orílẹ̀-èdè yẹn bá hù sí ìjọsìn tòótọ́. Ìyẹn ló fi mí sí Aísáyà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú pé kó kọ “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Bábílónì.” (Aísáyà 13:1) Àmọ́ o, ewu ọjọ́ iwájú ṣì ni Bábílónì jẹ́. Nígbà ayé Aísáyà, Ásíríà ló ń ni àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú lára. Ásíríà pa ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá run, ó sì sọ èyí tó pọ̀ jù nínú Júdà dahoro. Ṣùgbọ́n ayọ̀ ìṣẹ́gun Ásíríà kò tọ́jọ́ rárá. Aísáyà kọ̀wé pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti búra, pé: ‘Dájúdájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbèrò, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣẹlẹ̀ . . . kí n lè fọ́ ará Ásíríà náà ní ilẹ̀ mi àti pé kí n lè tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá mi; àti pé kí àjàgà rẹ̀ lè kúrò lọ́rùn wọn ní ti gidi àti pé kí ẹrù rẹ̀ gan-an lè kúrò ní èjìká wọn.’ ” (Aísáyà 14:​24, 25) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ yìí ni Ásíríà kò jẹ́ ewu fún Júdà mọ́.

ip-1 194 ¶12

Ohun Tí Jèhófà Pinnu Láti Ṣe sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè

12 Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ṣẹ? Kò ní pẹ́. “Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Móábù tẹ́lẹ̀ rí. Wàyí o, Jèhófà ti sọ̀rọ̀, pé: ‘Láàárín ọdún mẹ́ta, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọdún lébìrà tí a háyà, ògo Móábù ni a ó fi gbogbo onírúurú arukutu púpọ̀ dójú tì pẹ̀lú, àwọn tí yóò ṣẹ́ kù yóò sì jẹ́ díẹ̀ tí kò tó nǹkan, kì í ṣe alágbára ńlá.’ ” (Aísáyà 16:​13, 14) Lóòótọ́, àwọn awalẹ̀pìtàn rí ẹ̀rí pé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, Móábù jìyà tó le koko, púpọ̀ nínú àwọn ìlú rẹ̀ sì tú. Tigilati-pílésà Kẹta sọ pé Salamánù ará Móábù wà lára àwọn alákòóso tó san owó òde fóun. Senakéríbù gba owó òde lọ́wọ́ Kamusunábì, ọba Móábù. Ọba Esari-hádónì àti Aṣọbánípà ti Ásíríà sọ pé Músúrì àti Kamaṣátù ọba Móábù jẹ́ ọmọ abẹ́ ìjọba àwọn. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni àwọn ọmọ Móábù pa rẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ènìyàn kan. Wọ́n ti rí àlàpà àwọn ìlú ńlá kan tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ti Móábù, àmọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ ni ẹ̀rí gidi tí wọ́n tíì rí wà jáde nípa ọ̀tá alágbára yìí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nígbà kan rí.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w06 12/1 11 ¶1

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà​—Apá Kìíní

14:​1, 2​—Ọ̀nà wo làwọn èèyàn Jèhófà gbà di “amúnilóǹdè àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè” tí wọ́n sì “jọba lórí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí”? Èyí ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn bíi Dáníẹ́lì tó di ipò ńlá mú nílẹ̀ Bábílónì nígbà ìṣàkóso àwọn Mídíà àti Páṣíà. Bákan náà ni Ẹ́sítérì tó di ayaba nílẹ̀ Páṣíà; àti Módékáì, tí wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí igbá kejì Ọba gbogbo àgbègbè tí Ilẹ̀ Páṣíà ń ṣàkóso lé lórí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́