Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
JANUARY 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 17-20
“Ìpín Àwọn Tó Ń Kó Wa Lẹ́rù”
“Ìjọba Mi Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”
16 Irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Bíbélì fi aráyé wé omi òkun tó ń ru gùdù, tí kò sì ní àlàáfíà. (Aísá. 17:12; 57:20, 21; Ìṣí. 13:1) Ọ̀rọ̀ òṣèlú máa ń dá ìjà sílẹ̀, ó máa ń kọ ẹ̀yìn àwọn èèyàn sí ara wọn, wàhálà tó sì máa ń fà kì í tán bọ̀rọ̀, síbẹ̀ àwa èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn àlàáfíà, a sì wà níṣọ̀kan. Ó dájú pé inú Jèhófà á máa dùn bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn rẹ̀ wà níṣọ̀kan láìka ìyapa tó wà nínú ayé.—Ka Sefanáyà 3:17.
Má Ṣe Dá Sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Tàbí Ogun
4 Wọ́n lè má fúngun mọ́ wa pé ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú lórílẹ̀-èdè tá à ń gbé. Àmọ́ bí òpin ètò Sátánì yìí ṣe ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ láá túbọ̀ máa ṣòro fún wa láti wà láìdá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun. Lónìí, ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn ti di “aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan” àti “olùwarùnkì,” wọ́n á sì túbọ̀ máa yapa sí i. (2 Tímótì 3:3, 4) Láwọn orílẹ̀-èdè kan, nǹkan ti yí pa dà lágbo òṣèlú, torí náà wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ àwọn ará wa pé kí wọ́n lọ́wọ́ sí òṣèlú àti ogun. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká pinnu báyìí pé a ò ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun kódà tí wọ́n bá fipá mú wa láti lọ́wọ́ sí i. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin tá a lè ṣe láti múra sílẹ̀.
Ohun Tí Jèhófà Pinnu Láti Ṣe sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
20 Kí ni àbájáde rẹ̀? Aísáyà sọ pé: “Ní àkókò ìrọ̀lẹ́, họ́wù, wò ó! ìpayà òjijì ń bẹ. Kí ó tó di òwúrọ̀—kò sí mọ́. Èyí ni ìpín àwọn tí ń kó wa ní ìkógun, àti ipa tí ó jẹ́ ti àwọn tí ń piyẹ́ wa.” (Aísáyà 17:14) Ọ̀pọ̀ ló ń piyẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n ń kanra mọ́ wọn tí wọ́n sì ń kàn wọ́n lábùkù. Nítorí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe apá kan àwọn ẹ̀sìn jàǹkàn jàǹkàn ayé yìí, ńṣe làwọn ẹlẹ́tanú tí ń ṣe lámèyítọ́ àtàwọn alátakò tí ara ń ta kà wọ́n sí ẹni táwọn kàn lè nawọ́ gán nígbàkigbà. Àmọ́, ó dá àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú pé “òwúrọ̀,” nígbà tí ìpọ́njú wọn yóò dópin kù sí dẹ̀dẹ̀.—2 Tẹsalóníkà 1:6-9; 1 Pétérù 5:6-11.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
20:2-5—Ṣé òótọ́ ni pé Aísáyà rìn kiri níhòòhò fún ọdún mẹ́ta? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀wù àwọ̀lékè nìkan ni Aísáyà bọ́ sílẹ̀ tó sì ń rìn kiri pẹ̀lú aṣọ jáńpé.
JANUARY 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 21-23
Kí La Kọ́ Nínú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ṣébínà?
Báwo Ni Ìbáwí Ṣe Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa?
7 Ká lè rí àǹfààní tí ìbáwí máa ń mú wá, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ àwọn méjì tí Jèhófà bá wí yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́ ni Ṣébínà tó gbáyé nígbà ìṣàkóso Ọba Hesekáyà, ẹnì kejì sì ni Graham, arákùnrin kan lóde òní. Ṣébínà ni “ẹni tí ń ṣe àbójútó ilé” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti Ọba Hesekáyà, torí náà ipò àṣẹ ló wà. (Aísá. 22:15) Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, ó sì ń wá ògo fún ara rẹ̀. Kódà, ó gbẹ́ ibojì ńlá kan fún ara rẹ̀, ó sì ń gun “àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ògo.”—Aísá. 22:16-18.
8 Torí pé Ṣébínà ń wá ògo fún ara rẹ̀, Ọlọ́run lé e ‘kúrò ní ipò rẹ̀,’ ó sì fi Élíákímù rọ́pò rẹ̀. (Aísá. 22:19-21) Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà fẹ́ gbógun ja Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, Senakéríbù rán àwọn kan tó wà nípò gíga nínú ìjọba rẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá kí wọ́n lè ṣẹ̀rù ba àwọn Júù, kí wọ́n sì mú kí Hesekáyà túúbá fún wọn. (2 Ọba 18:17-25) Hesekáyà wá rán Élíákímù pé kó lọ rí àwọn tí Senakéríbù rán wá, Élíákímù àtàwọn méjì míì ni wọ́n sì jọ lọ. Ọ̀kan nínú wọn ni Ṣébínà tó ti wá di akọ̀wé báyìí. Ǹjẹ́ èyí kì í ṣe ẹ̀rí pé Ṣébínà gba ìbáwí tí Jèhófà fún un? Kò ráhùn, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fìrẹ̀lẹ̀ gba iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ tí wọ́n fún un. Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ mẹ́ta tá a lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.
9 Àkọ́kọ́, Ṣébínà pàdánù ipò rẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ìkìlọ̀ Bíbélì tó sọ pé, “ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” (Òwe 16:18) Tíwọ náà bá láwọn àǹfààní kan nínú ìjọ, tí àǹfààní náà sì ń mú káwọn míì máa kan sárá sí ẹ, ṣé wàá sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Ṣé wàá gbà pé Jèhófà ló mú kó o ṣe àwọn àṣeyọrí tó o ṣe àti pé òun ló fún ẹ láwọn ẹ̀bùn tó o ní? (1 Kọ́r. 4:7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.”—Róòmù 12:3.
Báwo Ni Ìbáwí Ṣe Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa?
10 Èkejì, bí Jèhófà ṣe bá Ṣébínà wí fi hàn pé Jèhófà kò wo Ṣébínà bí ẹni tí kò lè ṣàtúnṣe mọ́. (Òwe 3:11, 12) Ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn jẹ́ fáwọn tó bá pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní nínú ìjọ lónìí. Dípò kí wọ́n máa bínú tàbí kí wọ́n máa fapá jánú, ó yẹ kí wọ́n sapá láti ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n bá lè ṣe nínú ìjọ, kí wọ́n sì gbà pé torí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn ló ṣe bá wọn wí. Ká rántí pé tá a bá rẹ ara wa sílẹ̀, Jèhófà máa san wá lẹ́san. (Ka 1 Pétérù 5:6, 7.) Jèhófà máa ń fi ìbáwí onífẹ̀ẹ́ mọ wá, torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ ara wa di amọ̀ rírọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
Báwo Ni Ìbáwí Ṣe Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa?
11 Ẹ̀kẹta, táwọn òbí tàbí àwọn alàgbà bá fẹ́ báni wí, wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá Ṣébínà wí. Lọ́nà wo? Bí Jèhófà ṣe bá Ṣébínà wí fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan dá ló kórìíra, kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ náà. Tíwọ náà bá fẹ́ báni wí, á dáa kó o fara wé Jèhófà. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá sapá láti wá ibi tẹ́ni náà dáa sí, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó dá lo kórìíra, kì í ṣe òun fúnra rẹ̀.—Júúdà 22, 23.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
21:1—Àgbègbè wo ni Bíbélì pè ní “aginjù òkun”? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Bábílónì kò sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun rárá, Bíbélì pè é ní “aginjù òkun.” Ìdí ni pé ọdọọdún ni omi odò Yúfírétì àti Tígírísì máa ń kún bo àgbègbè náà, èyí sì máa ń fa àbàtà tó lọ salalu bí òkun.
JANUARY 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 24-27
“Ọlọ́run Wa Nìyí!”
“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí!”
21 Ṣé o ti ríbi tí ọmọ kékeré kan ti ń fi bàbá rẹ̀ han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tínú ẹ̀ sì ń dùn bó ṣe ń sọ fún wọn pé, “Bàbá mi nìyẹn”? Ó dájú pé wàá gbà pé ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ bàbá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ṣe yẹ kí Jèhófà rí sáwọn tó ń sìn ín. Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn olóòótọ́ èèyàn máa kéde pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí!” (Àìsáyà 25:8, 9) Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, bẹ́ẹ̀ láá túbọ̀ máa dá ẹ lójú pé Baba tó ju baba lọ ni.
Ohun Tá A Kọ́ Nígbà Tí Jésù Pèsè Búrẹ́dì Lọ́nà Ìyanu
14 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí,” ìgbà tí ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣẹ “ní ayé, bíi ti ọ̀run” ló ń sọ. (Mát. 6:9-11) Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí nígbà yẹn? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ara ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe ni pé kó pèsè oúnjẹ tó dáa fún gbogbo èèyàn. Àìsáyà 25:6-8 sọ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tó dáa máa wà nínú Ìjọba Ọlọ́run. Sáàmù 72:16 náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ máa wà lórí ilẹ̀;ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.” Ṣé ìwọ náà ń fojú sọ́nà láti se oúnjẹ tó o fẹ́ràn jù tàbí kó o tiẹ̀ se àwọn oúnjẹ tó ò sè rí? Yàtọ̀ síyẹn, wàá gbin ọgbà àjàrà, wàá sì gbádùn èso àti wáìnì tó o bá kórè níbẹ̀. (Àìsá. 65:21, 22) Gbogbo èèyàn tó bá wà láyé nígbà yẹn ló máa gbádùn àwọn nǹkan yìí, kì í ṣe ìwọ nìkan.
Bá A Ṣe Ń Jàǹfààní Ìfẹ́ Tí Jèhófà Fi Hàn sí Wa
11 Fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí fún ẹ nínú Párádísè. O ò ní ronú mọ́ pé lọ́jọ́ kan wàá ṣàìsàn tàbí pé wàá kú. (Àìsá. 25:8; 33:24) Gbogbo nǹkan tó o fẹ́ ni Jèhófà máa ṣe fún ẹ. Kí ló máa wù ẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀? Ṣé ìmọ̀ ẹ̀rọ ni àbí ó wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà nínú ewéko, ẹranko àtèèyàn? Ṣé orin ni àbí bí wọ́n ṣe ń yàwòrán? Ó dájú pé àwọn ayàwòrán ilé, àwọn kọ́lékọ́lé àtàwọn àgbẹ̀ máa wà. Ó sì tún dájú pé àwọn tó ń tún nǹkan ṣe àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìrànwọ́ máa wà, irú bí àwọn tó ń se oúnjẹ, àwọn tó ń ṣe irinṣẹ́ àtàwọn tó ń tún àyíká ṣe kó lè rẹwà. (Àìsá. 35:1; 65:21) Torí pé a máa wà láàyè títí láé, àkókò máa wà fún ẹ láti ṣe àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì tó o fẹ́.
12 Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá ń kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀! (Ìṣe 24:15) Tún ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó o máa kọ́ nípa Jèhófà lára àwọn nǹkan tó dá. (Sm. 104:24; Àìsá. 11:9) Èyí tó dáa jù ni pé àá máa fayọ̀ sin Jèhófà torí pé kò ní sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́! Ṣé ó yẹ ká wá torí “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í tọ́jọ́” pàdánù àwọn ohun rere tí Jèhófà máa fún wa lọ́jọ́ iwájú? (Héb. 11:25) Kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀! Tá a bá fi àwọn nǹkan táyé ń gbé lárugẹ sílẹ̀ nítorí àwọn ohun rere tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń dúró kí Párádísè dé, àmọ́ máa rántí pé á dé lọ́jọ́ kan. Àwọn nǹkan tá a sọ yìí ò ní ṣeé ṣe ká ní Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, kó sì fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà!
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Lọ́dún 2013
Kí nìdí táwọn ẹsẹ tá a tò bí ẹní kọ ewì fi wá pọ̀ sí i nínú Bíbélì tá a tún ṣe náà? Nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹsẹ tó wà níbẹ̀ ni wọ́n tò bí ẹní kọ ewì. Lóde òní, ohun táwọn èèyàn fi ń dá ewì mọ̀ ni pé ó máa ń dún lọ́nà tó bára jọ. Àmọ́ nínú èdè Hébérù, ńṣe ni ewì máa ń jẹ́ ká rí bí ọ̀rọ̀ kan ṣe jọ èkejì tàbí bí ọ̀rọ̀ ṣe yàtọ̀ síra. Nínú èdè Hébérù, ewì kì í dá lórí bí ọ̀rọ̀ ṣe dún lọ́nà tó bára jọ bí kò ṣe bí èrò tó wà nínú ọ̀rọ̀ ṣe tẹ̀ léra lọ́nà tó gún régé.
Nínú àwọn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a ti tẹ̀ jáde tẹ́lẹ̀, a kọ ìwé Jóòbù àti Sáàmù bí ẹní kọ ewì láti fi hàn pé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ńṣe ni wọ́n kọ wọ́n káwọn èèyàn lè máa kọ wọ́n lórin tàbí kí wọ́n máa há wọn sórí. Èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n tètè lóye àwọn kókó tó wà níbẹ̀, kí wọ́n sì máa rántí ẹ̀. Nínú Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tá a tún ṣe lọ́dún 2013, a ti tún àwọn ẹsẹ tó wà nínú ìwé Òwe, Orin Sólómọ́nì àtàwọn ìwé míì táwọn wòlíì kọ tò bí ẹni kọ ewì káwọn èèyàn lè mọ̀ pé ṣe ni wọ́n kọ wọn bí ewì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì lè tètè rí àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra níbẹ̀ àtàwọn tó yàtọ̀ síra. Àpẹẹrẹ irú ohun tá à ń sọ yìí wà nínú Aísáyà 24:2, níbi tá a ti lè rí ohun tó yàtọ̀ síra nínú gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀ àti bí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan ṣe ṣàlàyé síwájú sí i nípa ẹsẹ tó ṣáájú ẹ̀ láti mú kó ṣe kedere pé kò sẹ́ni tó máa bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. Bá a ṣe kọ àwọn ẹsẹ yìí bí ẹní kọ ewì máa jẹ́ kí òǹkàwé mọ̀ pé kì í ṣe àsọtúnsọ lásán ni òǹkọ̀wé Bíbélì náà ń sọ; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kọ ọ́ bí ẹní kọ ewì kó lè fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ń sọ níbẹ̀.
Ó lè má rọrùn láti tètè rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀rọ̀ Hébérù tó jẹ́ ewì àti èyí tí kì í ṣe ewì, torí náà ohùn àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ò ṣọ̀kan lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ewì. Torí náà, ọwọ́ ẹni tó ń ṣètumọ̀ ló kù sí láti pinnu àwọn ẹsẹ tó jẹ́ ewì. Àwọn ẹsẹ kan wà tí wọn ò kọ bí ẹní kọ ewì, àmọ́ tí wọ́n ní ọ̀rọ̀ tó jọ ewì nínú. Nínú irú àwọn ẹsẹ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe, wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ dárà tàbí kí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra láti ṣàlàyé kókó pàtàkì kan.
JANUARY 26–FEBRUARY 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 28-29
Máa Fi Ẹnu àti Ọkàn Rẹ Bọlá fún Jèhófà
Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe
23 Àwọn aṣáájú ìsìn Júdà sọ pe àwọ́n lóye nípa tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ Jèhófà sílẹ̀. Ìkọ́kúkọ̀ọ́ tiwọn fúnra wọn ni wọ́n fi ń kọ́ni, wọ́n wá ń tipa bẹ́ẹ̀ dá ìwàkiwà wọn láre àti àìnígbàgbọ́ wọn àti mímú tí wọ́n mú kí àwọn èèyàn pàdánù ojú rere Ọlọ́run. “Ohun àgbàyanu,” ìyẹn ‘ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì,’ ni Jèhófà yóò lò láti fi pè wọ́n wá jẹ́jọ́ fún ìwà àgàbàgebè wọn. Ó ní: “Nítorí ìdí náà pé àwọn ènìyàn yìí ti fi ẹnu wọn sún mọ́ mi, tí wọ́n sì ti fi kìkì ètè wọn yìn mí lógo, tí wọ́n sì ti mú ọkàn-àyà wọn pàápàá lọ jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ìbẹ̀rù tí wọ́n ní fún mi sì ti di àṣẹ ènìyàn tí wọ́n fi ń kọ́ni, nítorí náà, èmi rèé, Ẹni tí yóò tún gbé ìgbésẹ̀ lọ́nà àgbàyanu pẹ̀lú àwọn ènìyàn yìí, lọ́nà àgbàyanu àti pẹ̀lú ohun àgbàyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n wọn yóò sì ṣègbé, àní òye àwọn olóye wọn yóò sì fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Aísáyà 29:13, 14) Ńṣe ni Jèhófà yóò mú kí ohun tí Júdà ń pè ní ọgbọ́n àti òye yìí pa run nígbà tó bá mú kí Agbára Ayé Bábílónì wá pa gbogbo ètò ẹ̀sìn apẹ̀yìndà rẹ̀ run pátá. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, lẹ́yìn tí àwọn tó pe ara wọn ní aṣáájú olóye fún orílẹ̀-èdè Júù kó orílẹ̀-èdè yẹn ṣìnà. Irú ohun kan náà ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Kirisẹ́ńdọ̀mù lọ́jọ́ tiwa yìí.—Mátíù 15:8, 9; Róòmù 11:8.
Kò Sí Ohun Tó Lè Mú Kí Olódodo Kọsẹ̀
7 Jésù dẹ́bi fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn torí pé wọ́n ń fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé alágàbàgebè làwọn Farisí torí pé bí wọ́n ṣe máa wẹ ọwọ́ wọn látòkèdélẹ̀ jẹ wọ́n lógún ju kí wọ́n tọ́jú àwọn òbí wọn lọ. (Mát. 15:1-11) Ohun tí Jésù sọ yẹn ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́nu. Kódà, wọ́n bi í pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn Farisí kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí o sọ?” Jésù wá fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Baba mi ọ̀run kò gbìn la máa fà tu. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.” (Mát. 15:12-14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, Jésù ò dẹ́kun àtimáa sọ òtítọ́.
Má Kúrò Nínú Ilé Jèhófà Láé!
8 Àwọn tó ń “sọ òtítọ́ nínú ọkàn” wọn kì í díbọ́n pé àwọn ń ṣe ohun tó tọ́ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, àmọ́ kí wọ́n máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́ tí wọ́n bá dá wà. (Àìsá. 29:13) Wọn kì í ṣe oníbékebèke. Oníbékebèke lè máa rò pé kì í ṣe ìgbà gbogbo lòfin Jèhófà ń ṣe wá láǹfààní. (Jém. 1:5-8) Ó lè máa ṣe àwọn nǹkan tínú Jèhófà ò dùn sí, kó sì máa rò pé wọn ò tó nǹkan. Àmọ́ tó bá rí i pé òun ò jìyà ohun tóun ṣe, ó lè mú kó máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. Ó lè rò pé òun ń sin Ọlọ́run, àmọ́ Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn ẹ̀. (Oníw. 8:11) Torí náà, kò yẹ kọ́rọ̀ tiwa rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Aísáyà Sàsọtẹ́lẹ̀ ‘Ìṣe Tó Ṣàjèjì’ Tí Jèhófà Yóò Ṣe
19 Ọ̀rọ̀ kí ni Jèhófà wá sọ wàyí o? Ó ní: “Ègbé ni fún Áríélì, fún Áríélì, ìlú tí Dáfídì dó sí! Ẹ fi ọdún kún ọdún; ẹ jẹ́ kí àwọn àjọyọ̀ lọ yí ká. Ṣe ni èmi yóò sì mú kí nǹkan le dan-in dan-in fún Áríélì, ìṣọ̀fọ̀ àti ìdárò yóò sì wà, yóò sì dà bí ibi ìdáná pẹpẹ Ọlọ́run fún mi.” (Aísáyà 29:1, 2) Ó jọ pé “Ibi Ìdáná Pẹpẹ Ọlọ́run” ni “Áríélì” túmọ̀ sí, ó sì dájú pé Jerúsálẹ́mù ló tọ́ka sí níhìn-ín. Ibẹ̀ ni tẹ́ńpìlì àti pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ wà. Àwọn Júù a máa lọ ṣe àjọyọ̀, wọn a sì máa lọ rúbọ déédéé níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà, ṣùgbọ́n inú Jèhófà kò dùn sí ìjọsìn wọn. (Hóséà 6:6) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà pàṣẹ pé “ibi ìdáná pẹpẹ” irú mìíràn ni ìlú yẹn fúnra rẹ̀ máa dà. Ńṣe lẹ̀jẹ̀ àti iná á bo ibẹ̀ bó ṣe máa ń rí níbi pẹpẹ. Jèhófà tiẹ̀ kúkú ṣàpèjúwe bó ṣe máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Èmi yóò sì dó tì ọ́ ní ìhà gbogbo, èmi yóò sì fi igi ọgbà sàga tì ọ́, èmi yóò sì gbé àwọn agbàrà dìde tì ọ́. Ìwọ yóò sì di rírẹ̀sílẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ni ìwọ yóò ti máa sọ̀rọ̀, bí ẹni pé láti inú ekuru sì ni àsọjáde rẹ yóò ti máa dún lọ́nà rírẹlẹ̀.” (Aísáyà 29:3, 4) Ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa nìyẹn ṣẹ sórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì sàga ti ìlú yẹn tí wọ́n sì pa á run, tí wọ́n sì jó tẹ́ńpìlì rẹ̀. Ṣe ni wọ́n wó Jerúsálẹ́mù palẹ̀ bẹẹrẹ bí ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ ọ lé.
FEBRUARY 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 30-32
Gbà Pé Jèhófà Máa Dáàbò Bò Ẹ́
Jèhófà Ni Ibi Ìsádi Wa
7 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ ibi ìsádi wa, a ń rí ìtùnú nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Òun yóò fi àwọn ìyẹ́ rẹ̀ àfifò dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ rẹ, ìwọ yóò sì sá di abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀. Òótọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ apata ńlá àti odi ààbò.” (Sáàmù 91:4) Ọlọ́run máa ń dáàbò bò wá, àní gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ń ràdọ̀ bo ọmọ rẹ̀. (Aísáyà 31:5) ‘Ó ń fi ìyẹ́ rẹ̀ dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ wa.’ Ẹyẹ máa ń na ìyẹ́ bo àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè fi dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa wọ́n jẹ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹyẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gúnyẹ̀ẹ́, kò séwu fún wa lábẹ́ ìyẹ́ ìṣàpẹẹrẹ Jèhófà, nítorí pé a ti fara pa mọ́ sábẹ́ ètò àjọ rẹ̀ tó jẹ́ ti àwọn Kristẹni tòótọ́.—Rúùtù 2:12; Sáàmù 5:1, 11.
Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nígbà Ìṣòro
13 Ohun tó yẹ ká ṣe. Rí i dájú pé o ò yẹra fáwọn èèyàn. Tá a bá yẹra fáwọn èèyàn, ó lè jẹ́ ká máa ronú nípa ara wa nìkan àti ìṣòro tá a ní. Ìyẹn sì lè jẹ́ kó nira fún wa láti ṣe ìpinnu tó tọ́. (Òwe 18:1) Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì lè wà tó máa gba pé ká dá wà, pàápàá tó bá jẹ́ pé àjálù ńlá ló ṣẹlẹ̀ sí wa. Àmọ́ tó bá ti ń pẹ́ jù, a lè má rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí Jèhófà fẹ́ lò láti ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, bó ti wù kí ìṣòro wa le tó, ẹ jẹ́ káwọn ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́. Gbà pé àwọn ni Jèhófà ń lò láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Òwe 17:17; Àìsá. 32:1, 2.
‘Jèhófà Máa Sọ Ẹ́ Di Alágbára’
19 Báwo lo ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára? Bí àpẹẹrẹ, tó o bá nírètí láti gbé ayé títí láé, ka ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Párádísè ṣe máa rí, kó o sì ronú lé e lórí. (Àìsá. 25:8; 32:16-18) Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nínú ayé tuntun. Máa fojú inú wo ara ẹ níbẹ̀. Ta lo rí níbẹ̀? Ohùn wo lò ń gbọ́? Báwo ló ṣe rí lára ẹ? Kó lè rọrùn fún ẹ láti fojú inú rí ohun tá à ń sọ yìí, wo àwòrán Párádísè tó wà nínú àwọn ìwé wa tàbí kó o wo fídíò orin Ayé Tuntun, Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán tàbí Fojú Inú Wò Ó. Tá a bá ń fojú inú wo àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nínú ayé tuntun, àá rí i pé “ìgbà díẹ̀” ló kù káwọn ìṣòro wa dópin, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n bò wá mọ́lẹ̀. (2 Kọ́r. 4:17) Àwọn ohun tí Jèhófà ṣèlérí yìí máa fún ẹ lókun.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ẹ Máa Bá A Lọ Láti Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
17 Bí Aísáyà ṣe ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ, ó rán àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ létí pé wàhálà ń bọ̀ o. Àwọn èèyàn yẹn yóò gba “oúnjẹ tí í ṣe wàhálà àti omi tí í ṣe ìnilára.” (Aísáyà 30:20a) Bí oúnjẹ àti omi kò ṣe ṣàjèjì síni ni wàhálà àti ìnira yóò ṣe wọ́pọ̀ nígbà tí wọ́n bá sàga tì wọ́n. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ṣe tán láti kó àwọn ọlọ́kàn títọ́ yọ. Ó ní: “Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá kì yóò tún fi ara rẹ̀ pa mọ́, ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá. Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.”—Aísáyà 30:20b, 21.
FEBRUARY 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 33-35
“Òun Ló Ń Mú Kí Nǹkan Lọ Bó Ṣe Yẹ Láwọn Àkókò Rẹ”
Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nígbà Ìṣòro
7 Ohun tó jẹ́ ìṣòro. Tá a bá níṣòro tó le gan-an, bí nǹkan ṣe rí lára wa àti bá a ṣe ń ronú lè yàtọ̀ sí bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Bí atẹ́gùn ṣe máa ń bi ọkọ̀ ojú omi síbí sọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣòro ṣe lè jẹ́ ká ṣinú rò. Ana tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé lẹ́yìn tí ọkọ òun kú, ìrònú òun kì í pa pọ̀. Ó sọ pé: “Tó bá ti ń ṣe mí bíi pé ayé mi ti dojú rú, mo máa ń káàánú ara mi. Kódà inú máa ń bí mi pé ọkọ mi kú.” Yàtọ̀ síyẹn, Ana máa ń dá wà, nǹkan sì máa ń tojú sú u tó bá fẹ́ ṣèpinnu lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ pé Luis ọkọ ẹ̀ ló máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Nígbà míì, ó máa ń ṣe é bíi pé ó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí ìjì ń bì síbí bì sọ́hùn-ún. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tí ìṣòro wa bá ti ń kọjá ohun tá a lè fara dà?
8 Ohun tí Jèhófà máa ń ṣe. Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Ka Àìsáyà 33:6.) Tí ìjì bá ń bì lu ọkọ̀ òkun kan, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í fì síbí fì sọ́hùn-ún, ìyẹn sì léwu gan-an. Kí ọkọ̀ náà má bàa fì síbí fì sọ́hùn-ún mọ́, wọ́n ṣe àwọn nǹkan sábẹ́ ọkọ̀ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ méjèèjì. Àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe náà kì í jẹ́ kí ọkọ̀ náà fì ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn tó wà nínú ẹ̀ balẹ̀. Àmọ́ ìgbà tí àwọn nǹkan yẹn máa ń ṣiṣẹ́ jù ni ìgbà tí ọkọ̀ náà bá ń lọ síwájú. Lọ́nà kan náà, Jèhófà máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá ń tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí.
Bá A Ṣe Lè Máa Láyọ̀ Tá A Bá Ń Fara Da Ìṣòro
10 Ohun tá a lè ṣe sí ìṣòro náà: Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n. Tá a bá fẹ́ máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da ìṣòro, ó yẹ ká kọ́kọ́ bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ọgbọ́n ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. (Ka Jémíìsì 1:5.) Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà wa? Jémíìsì sọ pé ká máa bẹ Ọlọ́run, ká má sì jẹ́ kó sú wa. Jèhófà ò ní bínú tá a bá ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé kó fún wa ní ọgbọ́n, kò sì ní pẹ̀gàn wa. Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run, ó sì máa fún wa ní ọgbọ́n táá jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa. (Sm. 25:12, 13) Ó mọ ohun tá à ń kojú, ó máa ń dùn ún pé à ń jìyà, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa lọ́gbọ́n?
11 Jèhófà ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fún wa ní ọgbọ́n. (Òwe 2:6) Ká tó lè ní ọgbọ́n yìí, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run déédéé. Àmọ́, kì í ṣe pé ká kàn rọ́ ìmọ̀ sórí o. Kí ọgbọ́n Ọlọ́run tó lè ṣe wá láǹfààní, a gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nígbèésí ayé wa. Jémíìsì sọ pé: “Ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ, ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán.” (Jém. 1:22) Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò, àá lẹ́mìí àlàáfíà, àá máa fòye báni lò, àá sì máa ṣàánú. (Jém. 3:17) Èyí á jẹ́ ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí, a ò sì ní pàdánù ayọ̀ wa.
‘Kò Sí Olùgbé Kankan Tí Yóò Sọ Pé: “Àìsàn Ń Ṣe Mí” ’
21 Àmọ́ ṣá o, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ìmúṣẹ tòde òní. Àwọn èèyàn Jèhófà lónìí pẹ̀lú rí ìwòsàn tẹ̀mí gbà bákan náà. Wọ́n ti rí ìdáǹdè gbà kúrò lábẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké bí àìleèkú ọkàn, Mẹ́talọ́kan, àti iná ọ̀run apáàdì. Wọ́n ń gba ìtọ́sọ́nà nípa ìwà ọmọlúwàbí, èyí tó ń mú kí wọ́n jìnnà sí ìwà ìṣekúṣe gbogbo, tó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dára. Ẹ̀wẹ̀, ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ló mú kí wọ́n lè wà ní ipò tó mọ́ lójú Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Kólósè 1:13, 14; 1 Pétérù 2:24; 1 Jòhánù 4:10) Ìwòsàn tẹ̀mí yìí ṣàǹfààní nípa ti ara. Bí àpẹẹrẹ, yíyàgò fún ìṣekúṣe àti yíyàgò fún àwọn ohun tí wọ́n bá fi tábà ṣe, kì í jẹ́ kí àwọn Kristẹni kó àwọn àrùn tó ń bá ìṣekúṣe rìn àti irú àwọn àrùn jẹjẹrẹ kan.—1 Kọ́ríńtì 6:18; 2 Kọ́ríńtì 7:1.
22 Ní àfikún sí i, àwọn ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 33:24 yóò ṣẹ lọ́nà tó pẹtẹrí nínú ayé tuntun Ọlọ́run, lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì. Nígbà tí Ìjọba Mèsáyà bá ń ṣàkóso, aráyé yóò gba ìwòsàn ńláǹlà nípa ti ara pa pọ̀ mọ́ ìwòsàn tẹ̀mí tí wọ́n ń gbà. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ó dájú pé, kété tí ètò àwọn nǹkan Sátánì bá ti pa run, irú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Afọ́jú yóò ríran, adití yóò gbọ́ràn, arọ yóò rìn! (Aísáyà 35:5, 6) Èyí ni yóò jẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá la ìpọ́njú ńlá já lè kópa nínú iṣẹ́ alárinrin ti sísọ ilẹ̀ ayé di Párádísè.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Máa Rìn Ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́”
8 Àwọn kan lè sọ pé ‘ìtàn yìí dùn gan-an, àmọ́ ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù nígbà yẹn kan àwa náà lónìí?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ náà kàn wá torí àwa náà ń rìn lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn. Bóyá ẹni àmì òróró ni wá tàbí “àgùntàn mìíràn,” kò yẹ ká kúrò lójú “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” yẹn torí ó ń jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà nìṣó báyìí, ó sì máa jẹ́ ká gbádùn àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú nínú Ìjọba ẹ̀. (Jòh. 10:16) Láti ọdún 1919 S.K., àìmọye àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé ló ti kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn lójú ọ̀nà ìjẹ́mímọ́ yẹn. A lè sọ pé ìwọ náà wà lára wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti ń rìn lójú ọ̀nà yẹn láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, tipẹ́tipẹ́ làwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í tún ọ̀nà yẹn ṣe ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ín.
FEBRUARY 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 36-37
“Má Bẹ̀rù Nítorí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí O Gbọ́”
it “Hẹsikáyà” No. 1 ¶14
Hẹsikáyà
Senakérúbù Ò Ṣàṣeyọrí Nígbà Tó Fẹ́ Gba Ìlú Jerúsálẹ́mù. Bí Hẹsikáyà ṣe rò ó gẹ́lẹ́ ló rí, ṣe ni Senakérúbù pinnu láti gbógun ja ìlú Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Senakérúbù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ gbógun ja Lákíṣì tó jẹ́ ìlú olódi, ó rán díẹ̀ lára àwọn ọmọ ogun àtàwọn ọ̀gágun ẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ó ní kí wọ́n sọ fún wọn pé òun ń bọ̀ láti wá gba ìlú wọn, kí wọ́n sì túúbá fún òun. Ẹni tó gbẹnu sọ fáwọn ará Ásíríà yìí ni Rábúṣákè torí ó gbọ́ èdè Hébérù dáadáa (Rábúṣákè kì í ṣe orúkọ ẹ̀, orúkọ oyè ni). Ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í fi Hẹsikáyà ṣe yẹ̀yẹ́, ó pẹ̀gàn Jèhófà, ó sì ń fọ́nnu pé tí ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ò bá lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ọba Ásíríà, ṣé Jèhófà ló máa wá gba ìlú Jerúsálẹ́mù sílẹ̀?—2Ọb 18:13-35; 2Kr 32:9-15; Ais 36:2-20.
Ọba Kan Jẹ Èrè Ìgbàgbọ́ Rẹ̀
10 Lẹ́yìn náà, Rábúṣákè rán àwọn Júù létí pé, bó bá wá di ti ogun jíjà, ọ̀ràn wọn yóò dà bí ìgbà tí ọlọ́mọlanke bá dúró de rélùwéè ni. Ló bá pè wọ́n níjà lọ́nà ìfẹgẹ̀, ó ní: “Kí n . . . fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin láti rí i bóyá ìwọ, níhà ọ̀dọ̀ rẹ, lè fi olùgun ẹṣin sórí wọn.” (Aísáyà 36:8) Àmọ́, ká sòótọ́, yálà àwọn ògbówọ́ agẹṣinjagun tí Júdà ní pọ̀ o tàbí wọ́n kéré o, ǹjẹ́ ìyẹn ní ohunkóhun í ṣe nínú ọ̀ràn yìí? Rárá o, nítorí ìgbàlà Júdà kò sinmi lórí bó ṣe lágbára ìjà tó. Òwe 21:31 ṣàlàyé ọ̀ràn yẹn báyìí pé: “Ẹṣin ni ohun tí a pèsè sílẹ̀ fún ọjọ́ ìjà ogun, ṣùgbọ́n ti Jèhófà ni ìgbàlà.” Rábúṣákè wá sọ pé àwọn ará Ásíríà ni Jèhófà ń tì lẹ́yìn, kì í ṣe àwọn Júù. Ó ní láìṣe bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Ásíríà kì bá tí lè wọnú ìpínlẹ̀ Júdà jìnnà dé ibi tí wọ́n dé.—Aísáyà 36:9, 10.
Ọba Kan Jẹ Èrè Ìgbàgbọ́ Rẹ̀
13 Ni Rábúṣákè bá tún yọ ọfà ọ̀rọ̀ mìíràn látinú apó ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó kìlọ̀ fáwọn Júù pé kí wọ́n má ṣe gba Hesekáyà gbọ́ o tó bá sọ fún wọn pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò dá wa nídè.” Rábúṣákè wá rán àwọn Júù létí pé ṣebí àwọn òrìṣà Samáríà kò lè gba àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá sílẹ̀ kí àwọn ará Ásíríà má lè borí wọn. Ti àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Ásíríà ti ṣẹ́gun tún ńkọ́? Ó béèrè pé: “Àwọn ọlọ́run Hámátì àti Áápádì dà? Àwọn ọlọ́run Séfáfáímù dà? Wọ́n ha sì ti dá Samáríà nídè kúrò lọ́wọ́ mi?”—Aísáyà 36:18-20.
14 Ó dájú pé Rábúṣákè tó jẹ́ abọ̀rìṣà, kò mọ̀ pé ìyàtọ̀ ńlá ń bẹ láàárín Samáríà apẹ̀yìndà àti Jerúsálẹ́mù ti ìgbà ìṣàkóso Hesekáyà. Lóòótọ́, àwọn òrìṣà Samáríà kò lágbára láti gba ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá sílẹ̀. (2 Àwọn Ọba 17:7, 17, 18) Ṣùgbọ́n Jerúsálẹ́mù ti ìgbà Hesekáyà ti kẹ̀yìn sí àwọn òrìṣà, wọ́n sì ti padà sẹ́nu sísin Jèhófà. Àmọ́ ṣá, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó jẹ́ aṣojú Jùdíà kò gbìyànjú láti ṣàlàyé ìyẹn fún Rábúṣákè. “Wọ́n sì ń bá a lọ ní dídákẹ́, wọn kò sì dá a lóhùn ọ̀rọ̀ kan, nítorí àṣẹ ọba ni pé: ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.’ ” (Aísáyà 36:21) Ni Élíákímù, Ṣébínà àti Jóà bá padà lọ bá Hesekáyà, wọ́n sì jíṣẹ́ Rábúṣákè fún ọba.—Aísáyà 36:22.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it “Ìjánu” ¶4
Ìjánu
Jèhófà sọ fún Senakérúbù ọba Ásíríà pé: “Màá fi ìwọ̀ mi kọ́ imú rẹ, màá fi ìjánu mi sáàárín ètè rẹ, ọ̀nà tí o gbà wá ni màá sì mú ọ gbà pa dà.” (2Ọb 19:28; Ais 37:29) Pẹ̀lú bí Senakérúbù ṣe ń halẹ̀ mọ́ àwọn ará Jerúsálẹ́mù, ṣe ni Jèhófà fàgbà hàn án, tó sì mú kó pa dà sílùú Nínéfè lọ́wọ́ òfo. Nígbà tó pa dà síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀ pa á. (2Ọb 19:32-37; Ais 37:33-38) Tí Jèhófà bá fi ìjánu sí páárì àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó túmọ̀ sí pé Jèhófà kápá wọn bí ìgbà tẹ́nì kan fi ìjánu kápá ẹranko kan.—Ais 30:28.
FEBRUARY 23–MARCH 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÀÌSÁYÀ 38-40
“Ó Máa Bójú Tó Agbo Ẹran Rẹ̀ Bíi Ti Olùṣọ́ Àgùntàn”
Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹni Tó Ni Bíbélì
3 Ka Àìsáyà 40:8. Ọjọ́ pẹ́ tí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń tọ́ àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin sọ́nà. Kí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe? Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì torí pé ó ti pẹ́ gan-an tí wọ́n ti kọ Ìwé Mímọ́, àwọn àkájọ ìwé àtàwọn ìwé awọ tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́ sí sì ti bà jẹ́. Àmọ́ Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn èèyàn yẹn, wọ́n fara balẹ̀ dà á kọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sọ pé: “A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé kò sí ìwé àtijọ́ kankan tí wọ́n da ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ kọ lọ́nà tó péye bíi Bíbélì.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì àti pé àwọn ohun tó lè tètè bà jẹ́ ni wọ́n kọ ọ́ sí, tó sì jẹ́ pé àwọn aláìpé ló dà á kọ, ó dá wa lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là ń kà nínú Bíbélì lónìí torí pé Jèhófà ló ni ín.
4 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ti wá. (Jém. 1:17) Ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó dáa jù lọ tí Jèhófà fún wa ni Bíbélì. Tẹ́nì kan bá fún wa lẹ́bùn, ẹ̀bùn náà fi hàn pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì tún mọ ohun tá a fẹ́. Bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó fún wa ní Bíbélì ṣe rí náà nìyẹn. Tá a bá ń ka Bíbélì déédéé, àá túbọ̀ mọ̀ ọ́n. Á jẹ́ ká rí i pé Jèhófà mọ̀ wá dáadáa, ó sì mọ ohun tá a fẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ mẹ́ta lára àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. Àwọn ni: Ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run.
Agbára Ààbò—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”
7 Nígbà tí Jèhófà fi ara ẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn, ńṣe ló fẹ́ ká mọ̀ dájú pé ó wu òun pé kóun dáàbò wá. (Ìsíkíẹ́lì 34:11-16) Ṣé o rántí ohun tí Àìsáyà 40:11 sọ nípa Jèhófà bá a ṣe jíròrò ẹ̀ ní Orí 2 ìwé yìí? Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Ó máa bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ, ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.” Báwo ni ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn ṣe dé “àyà” olùṣọ́ àgùntàn náà, tó sì fi aṣọ ẹ̀ wé e? Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni àgùntàn yẹn lọ sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn náà, bóyá kó tiẹ̀ máa forí nù ún lẹ́sẹ̀. Àmọ́, ó dájú pé olùṣọ́ àgùntàn yẹn fúnra ẹ̀ ló máa bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, táá sì gbé ọ̀dọ́ àgùntàn náà sí àyà rẹ̀ kó lè dáàbò bò ó. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí i pé ó wu Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn wa láti bójú tó wa, kó sì dáàbò bò wá. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o!
“Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”
4 Ka Aísáyà 40:26. Kò sẹ́ni tó tíì lè ka gbogbo ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé iye ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tí ayé yìí wà tó irínwó [400] bílíọ̀nù. Síbẹ̀, Jèhófà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀ yẹn lórúkọ. Kí lèyí kọ́ wa nípa Jèhófà? Tí Jèhófà bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí, mélòómélòó wá ni ìwọ tó ò ń fi tọkàntọkàn sìn ín torí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Sm. 19:1, 3, 14) Baba wa ọ̀run mọ̀ ẹ́ dáadáa. Kódà, ‘gbogbo irun orí rẹ ni Jèhófà ti kà.’ (Mát. 10:30) Onísáàmù náà tún jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ohun táwọn aláìní-àléébù ń kojú. (Sm. 37:18) Ó mọ gbogbo ìṣòro tó ò ń dojú kọ, ó sì máa fún ẹ lókun láti fara dà á.
5 Ka Aísáyà 40:28. Jèhófà ni Orísun gbogbo agbára. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí agbára oòrùn ti pọ̀ tó. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ́ David Bodanis sọ pé: ‘Iye agbára tó ń jáde lára Oòrùn ní ìṣẹ́jú àáyá kan péré pọ̀ débi pé ó tó iye agbára tí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù bọ́ǹbù átọ́míìkì máa ń mú jáde.’ Olùṣèwádìí míì tún ṣírò iye agbára tó ń jáde lára oòrùn. Ó ní: “Iye agbára tó ń jáde lára oòrùn ní ìṣẹ́jú àáyá kan ṣoṣo tó aráyé lò fún odindi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì [200,000] ọdún”! Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wá lè sọ pé ẹni tó ń fún oòrùn lágbára tó tó báyìí kò lè fún òun lókun láti kojú ìṣòro èyíkéyìí?
6 Ka Aísáyà 40:29. Ayọ̀ tá a máa rí nínú sísin Jèhófà ò kéré. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín.” Ó tún fi kún un pé: “Ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí! Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ lọ sípàdé tàbí òde ẹ̀rí nígbà míì, ó lè rẹ̀ wá ká tó kúrò nílé. Àmọ́ nígbà tá a bá pa dà dé, báwo lara wa ṣe máa ń rí? Ṣe lara máa ń tù wá pẹ̀sẹ̀, á sì rọrùn fún wa láti kojú àwọn ìṣòro tá a ní. Ẹ ò rí i pé àjàgà Jésù rọrùn lóòótọ́!
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”
7 Ìmúbọ̀sípò ti ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa nìkan kọ́ ni ìmúṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní. Ó tún ṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa pẹ̀lú. Jòhánù Oníbatisí ni ohùn ẹnì kan tí “ń ké jáde ní aginjù,” ní ìmúṣẹ Aísáyà 40:3. (Lúùkù 3:1-6) Jòhánù sì lo ọ̀rọ̀ Aísáyà fún ara rẹ̀ nípa ìmísí. (Jòhánù 1:19-23) Ọdún 29 Sànmánì Tiwa ni Jòhánù ti bẹ̀rẹ̀ sí palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jésù Kristi. Ṣe ni kíkéde tí Jòhánù ti kéde ṣáájú mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí wá Mèsáyà táa ti ṣèlérí náà, kí àwọn náà lè gbọ́rọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì tẹ̀ lé e. (Lúùkù 1:13-17, 76) Jèhófà yóò wá lo Jésù láti ṣamọ̀nà àwọn tó ronú pìwà dà lọ sínú òmìnira tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè fúnni, ìyẹn ìdáǹdè kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 1:29; 8:32) Ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò sí i nígbà tí àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí rí ìdáǹdè gbà kúrò nínú Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919, àti nígbà ìmúbọ̀sípò wọn sínú ìjọsìn tòótọ́.