OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Máa Fojú Inú Wo Ohun Tó Ò Ń Kà Nínú Bíbélì
Ọ̀pọ̀ ìtàn tó kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ló kún inú Bíbélì. Tá a bá ń fojú inú wo àwọn ìtàn yìí bá a ṣe ń kà á, á jẹ́ kó túbọ̀ yé wa, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú wọn. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká lè máa fojú inú wo ohun tá a bá ń kà nínú Bíbélì.
Máa kà á sókè. Tó o bá ń ka Bíbélì sókè, ìyẹn á jẹ́ kó o lè túbọ̀ máa fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Tẹ́ ẹ bá sì ń ka Bíbélì pa pọ̀ nínú ìdílé, ẹ lè ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan ka ọ̀rọ̀ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ìtàn náà, ìyẹn á jẹ́ kó dà bíi pé ẹ wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Máa fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Gbìyànjú láti mọ ohun táwọn tó ò ń kà nípa wọn ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, bi ara ẹ pé: ‘Kí nìdí tẹ́ni náà fi ṣe ohun tó ṣe tàbí sọ ohun tó sọ? Ká sọ pé èmi nirú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, báwo lọ̀rọ̀ yẹn ì bá ṣe rí lára mi àti pé kí ló ṣeé ṣe kí n máa rò?’
Yàwòrán ohun tó ò ń kà. Tó o bá yàwòrán ohun tó ò ń kà, á jẹ́ kó o lè fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀, kó o rántí àwọn ẹ̀kọ́ ibẹ̀ dáadáa, kódà tí àwòrán náà ò bá tiẹ̀ rẹwà.