ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 January ojú ìwé 26-31
  • Máa Sọ Òtítọ́ Lọ́nà Tó Ń Tuni Lára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Sọ Òtítọ́ Lọ́nà Tó Ń Tuni Lára
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • IBO LA TI LÈ RÍ ÒTÍTỌ́?
  • ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA SỌ ÒTÍTỌ́
  • BÓ ṢE YẸ KÁ MÁA SỌ̀RỌ̀ TÁ A BÁ Ń SỌ ÒTÍTỌ́
  • ÌGBÀ TÓ YẸ KÁ SỌ ÒTÍTỌ́
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìyàtọ̀ Láàárín Òtítọ́ àti Irọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Wá Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Yìí
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká 2025-2026—Tí Alábòójútó Àyíká Máa Bá Wa Ṣe
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 January ojú ìwé 26-31

MARCH 30–APRIL 5, 2026

ORIN 76 Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?

Máa Sọ Òtítọ́ Lọ́nà Tó Ń Tuni Lára

“ Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́.”—SM. 31:5.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe lè sọ òótọ́ fáwọn èèyàn, tó sì máa ṣe wọ́n láǹfààní.

1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ di ara ìdílé Jèhófà?

TÁ A bá kọ́kọ́ pàdé ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà, ọ̀kan lára ìbéèrè tá a sábà máa ń bi ẹni náà ni pé, “Báwo lẹ ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?” Àwọn kan máa ń sọ pé, “Àwọn òbí mi ló kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.” Àwọn míì sì máa ń sọ pé ṣe làwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ “kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.” Ohun tó ń jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀ ni pé a ti jẹ́ kí òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí ìgbésí ayé wa pa dà pátápátá. Kí nìdí? Ìdí ni pé ká tó lè di ara ìdílé Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ká sì máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́. Lára àwọn àṣẹ náà ni pé ká máa sòótọ́, ká sì máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé olóòótọ́ ni wá.—Sm. 15:1-3.

2. (a) Kí làwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù máa ń ṣe? (b) Báwo ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn ṣe rí lára wọn?

2 Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń sọ òtítọ́. Àwọn ọ̀tá Jésù pàápàá mọ̀ pé ó máa ń sọ òtítọ́, kódà tí wọn ò bá fara mọ́ ohun tó sọ. (Mát. 22:16) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn, ó sọ bó ṣe máa rí lára wọn. Ó ní: “Mo wá láti fa ìpínyà, ọkùnrin sí bàbá rẹ̀, ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.” (Mát. 10:35) Jésù mọ̀ pé òótọ́ ọ̀rọ̀ tóun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn òun sọ fáwọn èèyàn náà máa rí bákan lára wọn, síbẹ̀ kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. (Mát. 23:37) Ó mọ̀ pé àwọn èèyàn kan máa gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà gbọ́, àwọn míì ò sì ní gbà á gbọ́.—2 Tẹs. 2:9-11.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Bíi ti Jésù, gbogbo ìgbà ló yẹ káwa náà jẹ́ olóòótọ́, kódà táwọn èèyàn ò bá fẹ́ràn wa torí pé à ń sọ òótọ́. Bákan náà, ó yẹ ká máa wàásù, ká sì máa kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ inú Bíbélì, kódà táwọn kan ò bá gba ohun tá à ń kọ́ wọn gbọ́. Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé kò yẹ ká ronú nípa ìgbà tó yẹ ká sọ òótọ́ fáwọn èèyàn àti bó ṣe yẹ ká sọ ọ́? Rárá o! Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ dáhùn ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì. Ìbéèrè náà ni pé: Ibo la ti lè rí òtítọ́? Yàtọ̀ síyẹn, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sọ òtítọ́? Báwo ló ṣe yẹ ká sọ ọ́? Ìgbà wo ló sì yẹ ká sọ ọ́? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fọgbọ́n sọ òtítọ́ fáwọn èèyàn àti ìgbà tó yẹ ká sọ ọ́ kára lè tù wọ́n.

IBO LA TI LÈ RÍ ÒTÍTỌ́?

4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ò láfiwé tó bá di pé ká sọ òtítọ́?

4 Jèhófà ò láfiwé tó bá di pé ká sọ òtítọ́. Ìdí ni pé gbogbo ohun tó bá sọ máa ń jẹ́ òótọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tó sọ nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ ṣeé gbára lé. (Sm. 19:9; 119:142, 151) Gbogbo ohun tó bá sọ pé òun máa ṣe ló máa ń ṣẹ. (Àìsá. 55:10, 11) Àwọn ìlérí tó bá ṣe kì í yẹ̀. (Nọ́ń. 23:19) Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ò lè parọ́ láé! (Héb. 6:18) Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé “Ọlọ́run òtítọ́” ni Jèhófà.—Sm. 31:5.

5. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé a lè di ọ̀rẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́”? Ṣàlàyé. (Ìṣe 17:27)

5 Àwọn kan máa ń sọ pé a ò lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà “Ọlọ́run òtítọ́,” àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ìdí sì ni pé àwọn nǹkan tó dá tó wà láyìíká wa jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run wà lóòótọ́. (Róòmù 1:20) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn Gíríìkì kan tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nílùú Áténì sọ̀rọ̀, ó sọ pé Ọlọ́run fẹ́ ká ‘rí òun’ àti pé “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ka Ìṣe 17:27.) Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń fa àwọn tó nírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fẹ́ mọ òtítọ́ sọ́dọ̀ ara rẹ̀.—Jòh. 6:44.

6. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, kí sì nìdí tó o fi mọyì àwọn ẹ̀kọ́ náà?

6 Ọ̀nà kan tá a lè gbà mọ Jèhófà ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí àwọn tó kọ Bíbélì. (2 Pét. 1:20, 21) Torí náà, òótọ́ ni gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì, ó sì ṣeé gbára lé. Bí àpẹẹrẹ, a gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àgbáyé wa yìí àtàwọn nǹkan ẹlẹ́mìí tó wà láyé. (Jẹ́n. 1:1, 26) A tún gba nǹkan tó sọ gbọ́ nípa ohun tó fà á tí gbogbo wa fi di ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ìdí tá a fi ń jìyà, tá a sì ń kú. (Róòmù 5:12; 6:23) Bákan náà, a gbà pé òótọ́ ni Bíbélì sọ pé Jèhófà máa lo Jésù Ọmọ rẹ̀ láti tún gbogbo ohun tí Sátánì “baba irọ́” ti bà jẹ́ ṣe. (Jòh. 8:44; Róòmù 16:20) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa ọjọ́ iwájú ṣeé gbára lé, pé Jésù máa pa àwọn èèyàn burúkú run, ó máa jí àwọn òkú dìde, ó máa sọ ayé di Párádísè, á sì sọ àwa èèyàn di pípé. (Jòh. 11:25, 26; 1 Jòh. 3:8) Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa ni Jèhófà ṣe bó ṣe jẹ́ ká mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí! A sì mọyì bó ṣe sọ pé ká máa fi òtítọ́ náà kọ́ àwọn èèyàn.—Mát. 28:19, 20.

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA SỌ ÒTÍTỌ́

7-8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sọ òótọ́? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Máàkù 3:11, 12) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Bá a ṣe sọ níṣàájú, tá a bá fẹ́ wà lára ìdílé Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa sọ òótọ́. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ tá a bá fẹ́ kínú ẹ̀ dùn sí wa. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà ni ìdí tá a fi ń sọ òtítọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wà láyé. (Ka Máàkù 3:11, 12.) Ìgbà kan wà tó ń wàásù nítòsí Òkun Gálílì, èrò rẹpẹtẹ sì wá sọ́dọ̀ ẹ̀. Lára àwọn èèyàn náà ni àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, wọ́n wólẹ̀ níwájú Jésù, wọ́n sọ fún un pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.” Kí nìdí táwọn ẹ̀mí èṣù yìí fi sọ òtítọ́ nípa Jésù? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán àwọn, káwọn èèyàn náà má bàa sin Jèhófà mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù yẹn sọ òótọ́, àǹfààní tara wọn ni wọ́n ń wá. Jésù mọ̀ pé irọ́ ni wọ́n ń pa. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi pàṣẹ fáwọn ẹ̀mí èṣù náà pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù nípa òun mọ́.

8 Kí la kọ́ nínú ìtàn Bíbélì yìí? Ohun tá a kọ́ ni pé ìdí tá a fi ń sọ òtítọ́ ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ìdí tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ náà ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Táwọn èèyàn bá sì yìn wá nítorí ohun tá a kọ́ wọn, Jèhófà ló yẹ ká fògo fún!—Mát. 5:16; fi wé Ìṣe 14:12-15.

Àwòrán méjì tó jẹ́ ká rí ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí arábìnrin kan ń gbà kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. 1. Arábìnrin náà ń sọ̀rọ̀ nípa ara ẹ̀, ó sì dojú Bíbélì ẹ̀ bolẹ̀. 2. Arábìnrin náà ṣí Bíbélì ẹ̀, ó sì ń fi ibi tó ń kà han ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.

Tó o bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ṣé ìwọ lo fẹ́ kí wọ́n máa kan sárá sí àbí Jèhófà lo fẹ́ kí wọ́n máa yìn lógo? (Wo ìpínrọ̀ 7-8)


9. Kí ni kò yẹ ká ṣe, kí sì nìdí?

9 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan míì tí kò yẹ ká ṣe ká má bàa gbé ògo fún ara wa. Ká sọ pé arákùnrin kan tó ń ṣàbójútó nínú ètò Ọlọ́run fọkàn tán wa ó sì sọ̀rọ̀ àṣírí fún wa, a wá lọ sọ̀rọ̀ náà fáwọn ẹlòmíì. Táwọn tá a sọ̀rọ̀ náà fún bá rí i pé òótọ́ lohun tá a sọ, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n wa lé, kí wọ́n sì máa sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó jẹ́ àṣírí la mọ̀. Ìyẹn lè mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé wa gẹ̀gẹ̀, àmọ́ inú Jèhófà ò ní dùn sí wa. (Òwe 11:13) Kí nìdí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ lohun tá a sọ, ọ̀rọ̀ àṣírí ni, ẹni náà ò sì fi rán wa, torí náà ohun tá a ṣe yẹn ò dáa.

BÓ ṢE YẸ KÁ MÁA SỌ̀RỌ̀ TÁ A BÁ Ń SỌ ÒTÍTỌ́

10. Kí ni “ọ̀rọ̀ onínúure”? (Kólósè 4:6)

10 Ka Kólósè 4:6. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará tó wà nílùú Kólósè pé kí wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn “máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure.” Kí ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n mọ̀? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ onínúure ni ọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn èèyàn ró, tó sì ń mára tù wọ́n.

11-12. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ṣàlàyé. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, á dáa ká fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa mára tu àwọn èèyàn. Òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì dà bí idà tó mú, tó lè pín ọkàn àti ẹ̀mí níyà. Ìyẹn ni pé ó lè fi irú ẹni tá a jẹ́ àtohun tó wà lọ́kàn wa hàn. (Héb. 4:12) Àmọ́ tá ò bá fọgbọ́n lo Bíbélì, a lè ṣẹ àwọn èèyàn ká sì dá wàhálà sílẹ̀. Kí ló lè fa irú nǹkan bẹ́ẹ̀?

12 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Ká sọ pé a pàdé ẹnì kan bá a ṣe ń wàásù, ẹni náà sì nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ ó máa ń lo ère tó bá ń gbàdúrà, inú òun àti ìdílé ẹ̀ sì máa ń dùn tí wọ́n bá ń ṣọdún Kérésì àti ọdún Àjíǹde. A lè fi Bíbélì ṣàlàyé fún un pé kò bọ́gbọ́n mu láti máa gbàdúrà sí ère lásánlàsàn, ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé ọdún àwọn abọ̀rìṣà ni ayẹyẹ Kérésì àti ọdún Àjíǹde. (Àìsá. 44:14-20; 2 Kọ́r. 6:14-17) Òótọ́ pọ́ńbélé lohun tá a sọ yìí, àmọ́ tó bá jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tá a pàdé ẹ̀ ni a la gbogbo ọ̀rọ̀ yìí mọ́lẹ̀ fún un, á jẹ́ pé a ò lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Àwòrán méjì tó jẹ́ ká rí ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà wàásù fún ọkùnrin kan tóun àti ìdílé ẹ̀ ń múra ọdún Kérésì. 1. Tọkọtaya náà fi àpilẹ̀kọ “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọdún Kérésìmesì?” tó wà lórí jw.org han ọkùnrin yẹn. Ojú ọkùnrin náà le bó ṣe ń gbọ́rọ̀ wọn. 2. Tọkọtaya náà fi àpilẹ̀kọ “Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Jẹ́ Bàbá Rere” tó wà lórí jw.org han ọkùnrin yẹn. Ọkùnrin náà ń rẹ́rìn-ín bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀.

Báwo la ṣe lè fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (Wo ìpínrọ̀ 11-12)a


13. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí iyọ̀ dun ọ̀rọ̀ wa?

13 Pọ́ọ̀lù tún gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ kí iyọ̀ dun ọ̀rọ̀ wa. Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń sọ pé ká máa fi ọ̀rọ̀ tó dùn bo òótọ́ ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ kí ‘iyọ̀ dun’ ọ̀rọ̀ wa, ìyẹn ni pé ká sọ òtítọ́ fáwọn èèyàn lọ́nà tí wọ́n á nífẹ̀ẹ́ sí, táá sì tù wọ́n lára. (Jóòbù 12:11) Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn. Tá a bá ń se oúnjẹ, a lè rò pé àwọn èròjà tá a máa ń lò tó ń mú ká gbádùn oúnjẹ wa làwọn ẹlòmíì máa nífẹ̀ẹ́ sí, kọ́rọ̀ má sì rí bẹ́ẹ̀. Lọ́nà kan náà, a lè rò pé bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ máa ń tu gbogbo èèyàn lára, ọ̀rọ̀ sì lè má rí bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, bóyá ọmọdé ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ o tàbí àgbàlagbà, torí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn nìyẹn. Àmọ́, nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ míì, wọ́n lè máa wo ẹni náà bíi pé kò mọ̀rọ̀ sọ. Pọ́ọ̀lù sọ pé ó yẹ ká mọ “bó ṣe yẹ [ká] dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.” Torí náà, ó yẹ ká máa kíyè sí ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀, kó má kàn jẹ́ ohun tó ti mọ́ wa lára torí àṣà ìbílẹ̀ wa, àmọ́ ká sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa tu àwọn èèyàn lára.

ÌGBÀ TÓ YẸ KÁ SỌ ÒTÍTỌ́

14. Ṣé Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ní gbogbo ohun tó mọ̀ nígbà tó wà láyé? Ṣàlàyé.

14 Jésù máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa ń tu àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ lára, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì kọ́ wọn. (Máàkù 6:34) Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tó yẹ kí wọ́n kọ́. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ohun tí Jésù mọ̀ ló kọ́ wọn. Ìdí ni pé ó mọ ohun tágbára wọn gbé. Ó mọ̀ pé lákòókò yẹn, àwọn nǹkan kan wà tí ò tíì lè yé wọn. Kódà, ó tiẹ̀ sọ fún wọn pé tóun bá ṣàlàyé ẹ̀ fún wọn, kò ní yé wọn. (Jòh. 16:12) Kí nìyẹn kọ́ wa?

15. Ṣé ẹ̀ẹ̀kan náà ló yẹ ká kọ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní gbogbo ohun tá a mọ̀? Ṣàlàyé. (Òwe 25:11) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan náà ló yẹ ká kọ́ àwọn èèyàn ní gbogbo ohun tá a mọ̀ nínú Bíbélì. Báwo la ṣe lè ṣe bíi ti Jésù? Ó yẹ káwa náà mọ ohun tágbára àwọn èèyàn gbé. Ẹ jẹ́ ká pa dà sórí ẹni tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tóun àti ìdílé ẹ̀ máa ń gbádùn ọdún Kérésì àti ọdún Àjíǹde. A mọ̀ pé inú ẹ̀sìn èké làwọn ayẹyẹ yìí ti wá, inú Ọlọ́run ò sì dùn sí i. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká sọ pé ọdún Kérésì ku ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣé o rò pé ọ̀rọ̀ ẹ máa tu ẹni náà lára tó o bá fi ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ayẹyẹ ẹ̀sìn èké hàn án, tó o sì sọ fún un lójú ẹsẹ̀ pé kó má ṣe àwọn ayẹyẹ náà mọ́? Òótọ́ ni pé àwọn kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń tètè fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fáwọn míì, ó máa ń pẹ́ kí wọ́n tó ṣe àyípadà tó yẹ. A máa ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú tó bá jẹ́ pé àkókò tó tọ́ la sọ ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ fún wọn, ìyẹn ni pé kó jẹ́ àkókò tó máa rọrùn fún wọn láti fi ohun tá a kọ́ wọn sílò.—Ka Òwe 25:11.

Tọkọtaya tó wà nínú àwòrán tó ṣáájú ń fi ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!” kọ́ ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ nínú ilé ẹ̀. Igi Kérésì wà nítòsí.

Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó o bá fẹ́ pinnu ìgbà tó yẹ kó o sọ̀rọ̀ àti bó ṣe yẹ kọ́rọ̀ ẹ pọ̀ tó (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Báwo la ṣe lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè máa “rìn nínú òtítọ́”?

16 Lára ohun tó máa ń múnú wa dùn jù ni pé ká ran ẹnì kan lọ́wọ́ kó lè wá sin Jèhófà. A lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti máa “rìn nínú òtítọ́” tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí: Máa hùwà tó dáa tẹ́ni náà lè fara wé. (3 Jòh. 3, 4) Máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o gbà pé àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì máa ṣẹ. Máa sọ òtítọ́ fáwọn èèyàn, àmọ́ kó má jẹ́ torí àǹfààní tó o máa rí. Máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa tu àwọn èèyàn lára tó o bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Táwọn èèyàn bá sì yìn ẹ́ torí ohun tó o kọ́ wọn, Jèhófà ni kó o fògo fún. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́ lò ń sìn.

KÍ LA KỌ́ NÍNÚ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ YÌÍ?

  • Ìṣe 17:27

  • Kólósè 4:6

  • Òwe 25:11

ORIN 160 “Ìhìn Rere”!

a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Nínú àwòrán àkọ́kọ́, arákùnrin kan rí ọkùnrin kan tó ń múra ọdún Kérésì sílẹ̀, ó wá fi àpilẹ̀kọ tó ṣàlàyé pé ọdún abọ̀rìṣà lọdún Kérésì hàn án. Nínú àwòrán kejì, arákùnrin náà fi àpilẹ̀kọ tó ṣàlàyé béèyàn ṣe lè jẹ́ bàbá rere han ọkùnrin náà. Èwo nínú méjèèjì lo rò pé ó máa wọ ẹni náà lọ́kàn?

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́