SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-Èdè Sierra Leone àti Guinea
Ilẹ̀ Orílẹ̀-èdè méjèèjì ló ní irà ní etíkun wọn, wọ́n ní ọ̀dàn, àwọn òkè tí orí rẹ̀ tẹ́jú tí wọ́n fi ń dáko àtàwọn òkè ńláńlá tó wà láàárín ìlú. Ilẹ̀ Guinea ni orísun mẹ́ta lára àwọn odò ńláńlá tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ìyẹn odò Gambia, Niger àti Senegal.
Àwọn Èèyàn Ẹ̀yà Mende àti Temne ló pọ̀ jù lára ẹ̀yà méjìdínlógún [18] tó wà ní Sierra Leone. Àgbègbè ìlú Freetown ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀yà Krio tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó dòmìnira láti ìgbèkùn ń gbé. Àwọn ẹ̀yà tó wà ní ilẹ̀ Guinea lé ní ọgbọ̀n. Àwọn Fúlàní, àwọn Mandingo àtàwọn Susu ló pọ̀ jù lára wọn.a
Ẹ̀sìn Nǹkan bí ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá àwọn ọmọ ilẹ̀ Sierra Leone jẹ́ Mùsùlùmí, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn yòókù ló máa ń sọ pé Kristẹni làwọn. Ní ilẹ̀ Guinea, àwọn tó jẹ́ Mùsùlùmí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ní orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ló tún ń ṣe àwọn ẹ̀sìn àbáláyé ilẹ̀ Áfíríkà.
Èdè Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní èdè tirẹ̀. Èdè Krio ni èdè àjùmọ̀lò wọn nílẹ̀ Sierra Leone. Èdè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn èdè ilẹ̀ Yúróòpù àti ti ilẹ̀ Áfíríkà ló wà nínú èdè Krio yìí. Èdè Faransé ni èdè àjùmọ̀lò ti ilẹ̀ Guinea. Ó lé díẹ̀ ní ìdajì àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí tí kò mọ ìwé kà.
Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́ Àgbẹ̀ alárojẹ ni èyí tó pọ̀ jù lára wọn. Orí dáyámọ́ǹdì tí wọ́n ń wà látinú iyanrìn ni orílẹ̀-èdè Sierra Leone ti ń rí nǹkan bí ìdajì nínú gbogbo owó tó ń wọlé látorí àwọn ohun tí wọ́n ń kó lọ tà lókè òkun. Orílẹ̀-èdè Guinea wà lára àwọn ibi tí ohun àmúṣọrọ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ògidì ayọ́ pọ̀ sí jù lọ ní àgbáyé.
Oúnjẹ Wọ́n sábà máa ń sọ pé “Tí mi ò bá tíì jẹ ìrẹsì, a jẹ́ pé mi ò tíì jẹun lónìí nìyẹn!” Ẹ̀gẹ́ tí wọ́n sè, tí wọ́n sì gún dáadáa ni wọ́n fi ń ṣe fùfú. Ọbẹ̀ ilá, ẹran àti ọbẹ̀ tí wọ́n fún omi ọsàn wẹ́wẹ́ sí ni wọ́n sábà máa fi ń jẹ fùfú yìí.
Ojú Ọjọ́ Ooru máa ń mú gan-an ní etíkun. Àmọ́ àwọn apá ibi tí òkè wà máa ń tutù. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ọyẹ́ tó máa ń fẹ́ wá láti aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà máa ń fa òtútù, ó sì máa ń mú kí eruku bo gbogbo àgbègbè náà
a Àwọn ẹ̀yà míì ní orúkọ tó pọ̀.
SIERRA LEONE |
GUINEA |
|
---|---|---|
ILẸ̀ (kìlómítà níbùú àti lóòró) |
71,740 |
245,857 |
IYE ÈÈYÀN |
6,092,000 |
11,745,000 |
IYE AKÉDE LỌ́DÚN 2013 |
2,039 |
748 |
IYE ÈÈYÀN TÍ AKÉDE KỌ̀Ọ̀KAN MÁA WÀÁSÙ FÚN |
2,988 |
15,702 |
IYE TÓ WÁ SÍ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI LỌ́DÚN 2013 |
8,297 |
3,609 |