ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 86-90
  • 1915 sí 1947 Ìgbà tí A Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ (Apá Kìíní)

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1915 sí 1947 Ìgbà tí A Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ (Apá Kìíní)
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Tàn!
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 86-90
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 86]

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

1915 sí 1947 Ìgbà tí A Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ (Apá Kìíní)

Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Tàn!

Ọdún 1915 tí àwọn tó ń gbé ní Sierra Leone tẹ́lẹ̀ pa dà dé láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n mú ìhìn rere wá sí orílẹ̀-èdè yìí, wọ́n sì mú àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì wá. Ní nǹkan bí oṣù July ọdún yẹn, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan dé sí ìlú Freetown, òun lẹni àkọ́kọ́ tó ti ṣèrìbọmi tó máa dé sí ìlú náà. Alfred Joseph lorúkọ rẹ̀. Ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] ni arákùnrin yìí, ọmọ bíbí ilẹ̀ Guyana tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù ni. Ọdún yẹn náà ló ṣèrìbọmi ní erékùṣù Barbados tó wà ní West Indies kó tó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ títún ọkọ̀ ojú irin ṣe ní ìlú Freetown. Inú ọgbà ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó ọkọ̀ ojú irin tó wà ní ìlú Cline Town ni Alfred ń gbé, ibẹ̀ sí ibi tí Igi Àràbà ìlú Freetown wà sì lé díẹ̀ ní kìlómítà mẹ́ta. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.

[Graph tó wà ní ojú ìwé 86]

Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, Leonard Blackman tí òun àti Alfred jọ ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ìlú Barbados kó wá síbi tí Alfred wà. Màmá Leonard, ìyẹn Elvira Hewitt ló kọ́ Alfred lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ilé Leonard àti Alfred wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì jọ máa ń pàdé láti jíròrò nípa Bíbélì. Wọ́n tún máa ń fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti àwọn tó bá fẹ́ mọ̀ nípa Bíbélì ní àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì.

Arákùnrin Alfred àti Leonard rí i pé ìlú Freetown dà bí pápá tó ti “funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Lọ́dún 1923, Alfred kọ̀wé sí oríléeṣẹ́ wa ní New York pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà níbí ló fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣé ẹ lè rán ẹnì kan wá kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kó sì mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbèrú ní ilẹ̀ Sierra Leone?” Èsì tí wọ́n fún un ni pé: “A máa rán ẹnì kan wá!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 88]

Arákùnrin William “Bible” Brown àti Antonia ìyàwó rẹ̀

Alfred sọ pé “Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, lálẹ́ ọjọ́ Sátidé kan báyìí, ẹnì kan tẹ̀ mí láago láìròtẹ́lẹ̀.”

“Ẹni náà sọ pé ‘Ṣé ìwọ lo kọ̀wé sí Watch Tower Society pé kí wọ́n rán àwọn tó ń wàásù wá?’

“Mo dáhùn pé ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’

“Ẹni náà wá sọ pé ‘Tóò, wọ́n ti rán mi wá o!’

“Arákùnrin William R. Brown lẹni tó sọ̀rọ̀ yẹn. Ọjọ́ yẹn ni òun, Antonia ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ wọn obìnrin dé sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Gainford Hotel ni wọ́n dé sí.

“Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, bí èmi àti Leonard ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ́wọ́, a rí ọkùnrin fìrìgbọ̀n kan lẹ́nu ọ̀nà wa. Arákùnrin William R. Brown lẹni yìí. Ìtara tó ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ pọ̀ débi pé ó fẹ́ sọ àsọyé Bíbélì fún àwọn èèyàn lọ́jọ́ kejì. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a lọ sanwó sílẹ̀ láti lo gbọ̀ngàn tó tóbi jù ní ìlú Freetown, ìyẹn Wilberforce Memorial Hall, a sì ṣètò àsọyé mẹ́rin tó dá lórí Bíbélì, ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Thursday tó tẹ̀ lé e la fi àkọ́kọ́ nínú àwọn àsọyé náà sí.

“Àwùjọ wa kéré, àmọ́ a bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé ìròyìn, ìwé ìkésíni àti ọ̀rọ̀ ẹnu láti kéde àwọn àsọyé náà ní pẹrẹu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ̀ bóyá àwọn ará ìlú náà máa wá, a ò dáwọ́ ìkésíni wa dúró. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] èèyàn títí kan ọ̀pọ̀ lára àwọn olórí ẹ̀sìn tó wà ní ìlú Freetown ló kún inú gbọ̀ngàn náà. Inú wa dùn débi pé tí wọ́n bá gẹṣin nínú wa lọ́jọ́ náà, kò lè kọsẹ̀!”

Ní odindi wákàtí kan tí Arákùnrin Brown fi sọ àsọyé yìí, ó ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́, bẹ́ẹ̀ ló sì tún lo ẹ̀rọ tó ń gbé àwòrán jáde lára ògiri láti jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó kà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sọ fún wọn pé, “Brown kọ́ ló sọ bẹ́ẹ̀, Bíbélì ni o!” Ẹnu ya àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń pàtẹ́wọ́ bó ṣe ń ṣàlàyé kókó kọ̀ọ̀kan. Kì í ṣe bí Arákùnrin Brown ṣe mọ ọ̀rọ̀ sọ tó ló wú àwùjọ náà lórí bí kò ṣe bó ṣe já fáfá nínú lílo Bíbélì láti fi ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn. Ọ̀dọ́kùnrin kan lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó wà níbẹ̀ sọ pé, “Ọ̀gbẹ́ni Brown mọ Bíbélì rẹ̀ dunjú!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 90]

1924

Àwọn àsọyé Arákùnrin Brown fa kíki gan-an, èyí sì mú káwọn ará ìlú máa rọ́ wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ní ọjọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, àwọn tó wá gbọ́ àsọyé tún kún inú gbọ̀ngàn náà fọ́fọ́. Àkòrí àsọyé ọjọ́ náà ni “Lílọ sí Hẹ́ẹ̀lì àti Pípadà, Àwọn Wo Ló Wà Níbẹ̀?” Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Arákùnrin Brown ṣàlàyé lálẹ́ ọjọ́ náà wọni lọ́kàn débi pé ó mú kí àwọn kan tí wọ́n ti di gbajúmọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì fi ẹ̀sìn wọn sílẹ̀.

Àkòrí àsọyé kẹrin tó kẹ́yìn nínú àwọn àsọyé náà ni, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.” Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ará ìlú Freetown ń sọ bí èrò tó wá gbọ́ àsọyé náà ṣe pọ̀ tó, ó ní: “Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní láti wọ́gi lé ìsìn tí wọ́n máa ń ṣe nírọ̀lẹ́ torí pé gbogbo ọmọ ìjọ wọn ló lọ gbọ́ àsọyé Arákùnrin Brown.”

Torí pé Arákùnrin Brown máa ń lo Bíbélì nígbà gbogbo, tó sì máa ń sọ pé ohun tí Bíbélì bá sọ ni abẹ gé, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní “Bible” Brown. Orúkọ yìí ni àwọn èèyàn fi mọ̀ ọ́n káàkiri Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Orúkọ yìí ni àpèlé William R. Brown títí tó fi parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, inú rẹ̀ sì máa ń dùn tí wọ́n bá pè é bẹ́ẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́