SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
1945 sí 1990 ‘Mímú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wá sí Òdodo’—Dán. 12:3. (Apá Kìíní)
Àwọn Míṣọ́nnárì Dé Láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
Ní oṣù June ọdún 1947, àwọn mẹ́ta kan tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì dé sí ìlú Freetown. Orúkọ wọn ni Charles Fitzpatrick, George Richardson àti Hubert Gresham. Àwọn míì sì tún dé lẹ́yìn wọn.
Àwọn míṣọ́nnárì náà rí ìtara tí àwọn akéde tó wà nílẹ̀ Sierra Leone ní fún iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ àwọn akéde náà ṣì nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa kọ́ni lọ́nà tó já fáfá. (Mát. 28:20) Torí náà, àwọn míṣọ́nnárì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn akéde bí wọ́n á ṣe máa pa dà lọ bá àwọn tí wọ́n wàásù fún àti bí wọ́n á ṣe máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n tún jẹ́ kí wọ́n mọ ìtọ́ni tó dé kẹ́yìn nípa àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn ìlànà ètò Ọlọ́run. Wọ́n ṣe ìpàdé fún gbogbo ènìyàn ní gbọ̀ngàn Wilberforce Memorial Hall. Àádọ́ta lé nírínwó [450] èèyàn ló pésẹ̀ síbẹ̀, èyí sì múnú àwọn míṣọ́nnárì náà dùn gan-an. Nígbà tó yá, wọ́n ṣètò ọjọ́ kan lọ́sẹ̀ tí wọ́n á máa fi ìwé ìròyìn lọni. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí koná mọ́ ìtara àwọn ará, ó sì mú kí wọ́n pọ̀ sí i lẹ́yìn náà.
Àmọ́, ojú ọjọ́ ilẹ̀ Sierra Leone kò bá àwọn míṣọ́nnárì yìí lára mu. Nínú ìròyìn ẹ̀ka ọ́fíìsì kan lọ́dún 1948, wọ́n ní: “Ojú ọjọ́ lórílẹ̀-èdè Sierra Leone kò rọgbọ rárá. Oṣù mẹ́fà gbáko ni òjò fi máa ń rọ̀ lọ́dọọdún, ó máa ń pọ̀ gan-an, kì í sì í dá bọ̀rọ̀. Nígbà míì, ó máa ń fi odindi ọ̀sẹ̀ méjì rọ̀ láì dáwọ́ dúró. Nígbà ẹ̀rùn, ooru máa ń mú gan-an ojú ọjọ́ sì máa ń gbóná gan-an.” Àwọn tó kọ́kọ́ wá ṣèbẹ̀wò sí Sierra Leone láti ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé ojú ọjọ́ ibẹ̀ lè pa aláwọ̀ funfun. Àìsàn ibà, ibà pọ́njú àtàwọn àìsàn tó máa ń ṣeni nílẹ̀ olóoru wọ́pọ̀ gan-an níbẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan làwọn míṣọ́nnárì náà ń ṣàìsàn tí wọ́n sì ń fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn akéde tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sierra Leone. Àmọ́ wọn ò torí ìyẹn dá iṣẹ́ ìwàásù dúró. Ní ọdún 1947 sí 1952, iye àwọn akéde pọ̀ sí i látorí méjìdínlógójì [38] tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ sí mẹ́tàléláàádọ́rin [73]. Ní ìlú Waterloo tó wà nítòsí ìlú Freetown, àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣiṣẹ́ kára gan-an, wọ́n sì dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ níbẹ̀. Wọ́n tún dá àwọn àwùjọ tuntun sílẹ̀ ní ìlú Kissy àti ìlú Wellington nítòsí ìlú Freetown. Ó ti wá jọ pé iṣẹ́ náà máa gbilẹ̀ gan-an nílẹ̀ Sierra Leone. Kí ló máa jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe?
Ìbẹ̀wò Kan Tó Fúnni Lókun
Lóṣù November, ọdún 1952, ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó ga, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ lára sọ̀ kalẹ̀ látinú ọkọ̀ ní etíkun ìlú Freetown, ó sì wọnú ìgboro ìlú náà. Milton G. Henschel lorúkọ rẹ̀, ó lé díẹ̀ ní ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún, oríléeṣẹ́ wa ló sì ti wá. Ó ní: “Ó yà mí lẹ́nu pé ìlú náà ní àwọn nǹkan ìgbàlódé, ó sì mọ́ tónítóní ju àwọn ìlú míì lọ lágbàáyé. . . . Wọ́n ní àwọn ọ̀nà tó dára, àwọn ṣọ́ọ̀bù oníṣòwò tó kún fọ́fọ́, àwọn ọkọ̀ tuntun àti èrò tó ń lọ tó ń bọ̀.”
Arákùnrin Henschel lọ sí ilé àwọn míṣọ́nnárì ní ìlú Freetown, ilé náà kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí tòsí Igi Àràbà táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó. Ó sọ fún àwọn ará tó pé jọ síbẹ̀ pé ètò Ọlọ́run máa túbọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ nílẹ̀ Sierra Leone. Lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, èèyàn mẹ́tàléláàádọ́ta-lé-rúgba [253] ló pé jọ sínú gbọ̀ngàn Wilberforce Memorial Hall láti wá gbọ́ àwọn ìfilọ̀ tó ń mórí ẹni yá gágá tí Arákùnrin Henschel ṣe. Ó ní: Wọ́n máa kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì kan sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone, wọ́n máa ní alábòójútó àyíká; wọ́n á máa ṣe àpéjọ àyíká; wọ́n máa dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ ní ìlú Kissy; wọ́n sì máa mú kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ gbilẹ̀ láwọn abúlé àtàwọn ìgbèríko. Inú àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ dùn gan-an!
Arákùnrin Henschel ní: “Wọn ò yéé sọ pé kusheh. Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ‘o káre láé!’ Ìdùnnú wọn ṣubú layọ̀. Kódà, ilẹ̀ ti ṣú kí àwọn ará tó kúrò nínú gbọ̀ngàn náà . . . wọ́n jáde lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́, àwọn kan lára wọn sì ń kọrin.”
Arákùnrin William Nushy, míṣọ́nnárì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ni ètò Ọlọ́run yàn láti bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun tí wọ́n fẹ́ kọ́ náà. Káàdì àti ọmọ ayò casino ni William ń tà tẹ́lẹ̀ káàkiri ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ṣùgbọ́n nígbà tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó fi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà òdodo ṣèwà hù, èyí mú kí àwọn akéde nílẹ̀ Sierra Leone fẹ́ràn rẹ̀, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un.