ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 94-98
  • 1915 sí 1947 Ìgbà tí A Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ (Apá Kẹta)

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1915 sí 1947 Ìgbà tí A Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ (Apá Kẹta)
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Ìhìn Rere Dé Àwọn Ìlú Àtàwọn Ìgbèríko
  • Wọn Kò Ṣíwọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Nígbà Ìfòfindè
  • Kíkéde Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 94-98

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

1915 sí 1947 Ìgbà tí A Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ (Apá Kẹta)

Ìhìn Rere Dé Àwọn Ìlú Àtàwọn Ìgbèríko

Ọwọ́ àwọn ará Ìjọ Freetown “dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà” torí ìtara tí wọ́n ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́. (Ìṣe 18:5) Arákùnrin Alfred Joseph sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń so páálí àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́ alùpùpù mi. Arákùnrin Thomas tàbí Sylvester Grant sì máa jókòó sí ẹ̀yìn tá a bá ń lọ sí àwọn ìlú kéékèèké àtàwọn ìgbèríko tó wà ní àgbègbè ìlú Freetown láti fi àwọn ìwé náà lọ àwọn èèyàn, bí a ṣe máa ń ṣe nígbà yẹn.”

Títí di ọdún 1927, inú ìlú Freetown àti àgbègbè rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní The Colony ni àwọn akéde ti sábà máa ń wàásù. Àmọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1928 ni ìjọ ti wá ń háyà bọ́ọ̀sì lọ́dọọdún láti lọ sáwọn ìlú àtàwọn ìgbèríko kí àsìkò òjò tó dé. Àwọn tí kò bá lè lọ máa ń dáwó jọ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tó ń lọ. Arákùnrin Melbourne Garber ló máa ń bójú tó ètò yìí. Àwùjọ tó ń wọ bọ́ọ̀sì náà máa ń lọ wàásù ní àwọn ìlú àtàwọn abúlé tó wà ní apá ìlà oòrùn títí dé ìlú Kailahun, wọ́n tún máa ń lọ wàásù ní apá gúúsù dé tòsí ààlà orílẹ̀-èdè Làìbéríà. Wọ́n máa ń pa dà lọ ní Sunday àkọ́kọ́ lóṣooṣù kí wọ́n lè kọ́ àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Lásìkò yẹn, Arákùnrin Brown lọ sí erékùṣù West Indies, ó sì gbé ọkọ̀ kan bọ̀, ọkọ̀ yìí wà lára àwọn àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tó wọ orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Wọ́n dìídì ṣe ẹ̀rọ gbohùngbohùn tó lágbára gan-an sára ọkọ̀ yìí láti máa fi wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí. Arákùnrin Brown máa ń gbé ọkọ̀ náà lọ sí ibi tó bá jẹ́ gbàgede, á gbé àwo orin tó ládùn kan sí i, orin yìí máa ń mú kí ọ̀pọ̀ èrò wá síbẹ̀. Yóò wá sọ àsọyé kúkúrú kan tàbí kó lo àsọyé tó ti fi ẹ̀rọ gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, á sì wá sọ fún àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọ́n wá gba àwọn ìwé tí wọ́n lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkọ̀ tí wọ́n so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́ yìí di ìran àpéwò. Àwọn èrò sì máa ń rọ́ wá láti gbọ́ ohun tó ń sọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 95]

Wọ́n ń fi ìgboyà wàásù

Arákùnrin Brown wá bẹ̀rẹ̀ sí í forí lé àwọn ilẹ̀ míì tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, àmọ́ tí iṣẹ́ ìwàásù kò tíì dé. Ní ọdún 1927 sí 1929, ó rìnrìn àjò lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gáńbíà, Gánà, Làìbéríà àti Nàìjíríà láti lọ wàásù. Arákùnrin Brown rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan tó ti lọ wàásù, àmọ́ ó jọ pé iye àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Nàìjíríà pọ̀ yàtọ̀. Lọ́dún 1930, òun àti ìdílé rẹ̀ ṣí láti ìlú Freetown wá sí ìlú Èkó. Láti ibẹ̀ ló ti wá ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ló ń sin Jèhófà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà

Nígbà tó fi máa di 1950, àìlera mú kó di dandan fún Arákùnrin Brown láti pa dà sí orílẹ̀-èdè Jàmáíkà, àmọ́ a ò jẹ́ gbàgbé iṣẹ́ tó ṣe. Ó lé ní ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tí òun àti ìyàwó rẹ̀ fi ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì rí bí iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ṣe pọ̀ sí i látorí ẹni méjì títí tí wọ́n fi lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá [11,000]. Wọ́n ti fojú ara wọn rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Aísáyà pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.” (Aísá. 60:22) Ní báyìí tó ti lé díẹ̀ ní ọgọ́ta [60] ọdún tí wọ́n ti lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ló dà bí “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè,” tó ń sin Jèhófà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà.

Wọn Kò Ṣíwọ́ Iṣẹ́ Ìwàásù Nígbà Ìfòfindè

Ní gbogbo àsìkò tí Ogun Àgbáyé Kejì fi jà ní ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Sierra Leone kò bá wọn lọ́wọ́ sí ogun. (Míkà 4:3; Jòh. 18:36) Àwọn alákòóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rò pé wọ́n ń dìtẹ̀ sí ìjọba, torí náà wọ́n ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, wọ́n sì fòfin de àwọn ìwé wọn. Àwọn ọlọ́pàá aṣọ́bodè ní ìlú Freetown gba àwọn ìwé wa kan tó dé sí ìlú náà, wọ́n sì dáná sun ún. Wọ́n mú àwọn arákùnrin kan torí pé wọ́n rí àwọn ìwé wa tí ìjọba fòfin dè lọ́wọ́ wọn, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi dá wọn sílẹ̀.a

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù, àwọn Ẹlẹ́rìí kò ṣíwọ́ wíwàásù. Arábìnrin Pauline Cole sọ pé: “Arákùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ ojú omi kan tó máa ń wá lóòrèkóòrè máa ń kó Ilé Ìṣọ́ wá fún wa. A máa ń ṣe àtúntẹ̀ àwọn ẹ̀dà ìwé náà, kí àwọn ará lè rí i lò fún ìpàdé. A tún tẹ àwọn ìwé ìléwọ́ tó ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú Bíbélì, a sì pín wọn fún àwọn èèyàn. Àwọn arákùnrin ń sọ àsọyé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń mú kí àwọn èèyàn gbọ́ àwọn àsọyé Arákùnrin Rutherford tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ lórí rédíò, pàápàá ní àwọn abúlé tí kò jìnnà.”

Ó dájú pé Jèhófà bù kún gbogbo ìsapá yìí. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ James Jarrett, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, sọ pé: “Nígbà ogun yẹn, ẹnu iṣẹ́ ni mo wà níbi tí mo ti ń fọ́ òkúta nígbà tí màmá àgbàlagbà kan wá fún mi ní ìwé kékeré kan tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní Refugees. Nígbà tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń dé sí ìlú Freetown láti oko ẹrú nígbà yẹn, àkòrí náà mú kí n fẹ́ láti kà á. Alẹ́ ọjọ́ yẹn ni mo ka ìwé kékeré náà, ojú ẹsẹ̀ ló sì ṣe kedere sí mi pé mo ti rí òtítọ́. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, mo wá màmá náà lọ, mo sì gba ẹ̀dà ìwé náà fún ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn àbúrò mi méjì. Àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Nígbà tí ogun yẹn fi máa parí lọ́dún 1945, akéde tó wà nínú Ìjọ Freetown ti di méjìlélọ́gbọ̀n [32]. Àwọn akéde yìí jẹ́ olóòótọ́, wọn kò sì dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Gbogbo wọn ló fẹ́ tẹ̀ síwájú.

Kíkéde Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn

Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí Ìjọ Freetown ṣe ní August 29, 1945, wọ́n jíròrò ọ̀nà tuntun tí wọ́n fẹ́ máa gbà kéde ìpàdé ìjọ bó ṣe wà nínú ìwé Informant (tí a wá mọ̀ sí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa) ti oṣù December 1944. Ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò máa lọ kéde àsọyé mẹ́rin-mẹ́rin ní “gbogbo ìlú àtàwọn abúlé kéékèèké “ tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, wọ́n á sì sọ àwọn àsọyé náà níbẹ̀. Ní ìpàdé kọ̀ọ̀kan, arákùnrin kan máa sọ àsọyé oníwákàtí kan (ó lè jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún tàbí kó jù bẹ́ẹ̀), ó sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ṣe dáadáa ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ìpàdé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí, àwọn ará máa ṣètò àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ní àgbègbè kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́.

Báwo ni ìtọ́ni tuntun yìí ṣe rí lára àwọn akéde? Díẹ̀ lára àkọsílẹ̀ tí wọ́n ṣe nígbà Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn nínú ìjọ Freetown rèé:

Alága: “Ọ̀nà wo lẹ rò pé ó yẹ ká gbà ṣe ìpolongo yìí?”

Arákùnrin Àkọ́kọ́: “A ò lè retí pé kó méso jáde bó ṣe rí nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Àwọn èèyàn tó wà níbí yàtọ̀.”

Arákùnrin Kejì: “Bẹ́ẹ̀ ni.”

Arákùnrin Kẹta: “Ẹ ò ṣe jẹ́ ká gbìyànjú ẹ̀ wò?”

Arákùnrin Kẹrin: “Àmọ́, á nira díẹ̀ o.”

Arákùnrin Karùn-ún: “Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ètò Jèhófà fún wa.”

Arákùnrin Kẹfà: “Kò dá mi lójú pé ó máa ṣeé ṣe lórílẹ̀-èdè wa yìí.”

Arábìnrin Àkọ́kọ́: “Bó bá tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìtọ́ni inú ìwé Informant yìí ṣe kedere. Ẹ jẹ́ ká gbìyànjú ẹ̀ wò!”

Ohun tí wọ́n ṣe gan-an nìyẹn. Láti etíkun ìlú Freetown, títí dé ìlú Bo ní gúúsù ìlà oòrùn àti ìlú Kabala tó wà lórí òkè tó tẹ́jú pẹrẹsẹ lápá àríwá, àwọn ará ń ṣe ìpàdé nínú àwọn kíláàsì ilé ìwé, níbi ọjà àti nínú ilé àwọn èèyàn. Iṣẹ́ náà mú kí ìtara wọn pọ̀ sí i, “ọ̀rọ̀ Jèhófà [sì] ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀ àti ní títànkálẹ̀.”—Ìṣe 12:24.

Síbẹ̀, àwọn akéde nílò kí ètò Ọlọ́run dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ohun tí Jèhófà sì ṣe fún wọn nìyẹn.

a Ọdún 1948 ni ìjọba mú ìfòfindè náà kúrò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́