ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 106-111
  • 1945 sí 1990 ‘Mímú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wá sí Òdodo’—Dán. 12:3. (Apá Kejì)

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1945 sí 1990 ‘Mímú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wá sí Òdodo’—Dán. 12:3. (Apá Kejì)
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Bí A Ṣe Buyì Kún Ìgbéyàwó Tó Jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run
  • Ìyapa Ṣẹlẹ̀ Ní Ìlú Freetown
  • Bí A Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kọ́ Àwọn Kisi Lẹ́kọ̀ọ́
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 106-111

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

1945 sí 1990 ‘Mímú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wá sí Òdodo’—Dán. 12:3. (Apá Kejì)

Bí A Ṣe Buyì Kún Ìgbéyàwó Tó Jẹ́ Ẹ̀bùn Ọlọ́run

Nígbà tí Arákùnrin William Nushy bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà, ó kíyè sí pé àwọn akéde kan kò tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin jọ ń gbé bíi tọkọtaya láìfi orúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àṣà ìbílẹ̀ ni àwọn míì ń tẹ̀ lé, wọn kì í ṣe ìgbéyàwó láìjẹ́ pé àfẹ́sọ́nà wọn lóyún, kó lè dá wọn lójú pé wọ́n á rí ọmọ bí.

Nítorí èyí, ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ lẹ́tà sí gbogbo ìjọ ní oṣù May 1953, wọ́n sì ṣàlàyé ìlànà Bíbélì nípa ìgbéyàwó ní kedere. (Jẹ́n. 2:24; Róòmù 13:1; Héb. 13:4) Wọ́n fún àwọn tọkọtaya ní àsìkò pé kí wọ́n lọ forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n á yọ wọ́n lẹ́gbẹ́.—1 Kọ́r. 5:11, 13.

Inú èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ará dùn sí àtúnṣe yìí. Àmọ́, àwọn kan kò fara mọ́ ọn, wọ́n rò pé kò pọn dandan. Kódà, nínú ìjọ méjì kan, èyí tó ju ìdajì àwọn akéde ni kò wá sí ìpàdé mọ́. Àmọ́, àwọn tó tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, èyí fi hàn pé Jèhófà bù kún ìsapá wọn.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìsapá tí àwọn ará ṣe, ìjọba fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa fi orúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Freetown. September 3, 1954 ni wọ́n kọ́kọ́ fi orúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lábẹ́ òfin nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Nígbà tó yá, ìjọba fún àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ní àgbègbè méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè náà láṣẹ láti máa forúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún púpọ̀ sí i lára àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti fìdí ìgbéyàwó wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin, kí wọ́n sì di akéde Ìjọba Ọlọ́run.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 107]

Ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àmọ́ tí wọ́n ní ju ìyàwó kan lọ tún ṣe ohun tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. Arákùnrin Samuel Cooper tó ń gbé ní ìlú Bonthe báyìí sọ pé: “Ọdún 1957 ni èmi àti ìyàwó mi méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́jọ́ kan, wọ́n fún mi ní iṣẹ́ kan tó dá lórí ìgbéyàwó Kristẹni. Nígbà tí mo ṣe ìwádìí lórí iṣẹ́ náà, mo rí i pé ó yẹ kí n sọ fún ìyàwó mi kékeré pé kó máa lọ. Àwọn mọ̀lẹ́bí mi ta kò mí nígbà tí mo sọ fún wọn. Ìyàwó mi kékeré ti bí ọmọ kan fún mi, àmọ́ ìyàwó mi àgbà kò tíì rọ́mọ bí. Síbẹ̀, mo pinnu láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Ó yà mí lẹ́nu pé nígbà tí ìyàwó mi kékeré pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀, ìyàwó mi àgbà bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Ní báyìí, ìyàwó mi àgbà tí kò rọ́mọ bí tẹ́lẹ̀ ti wá bímọ márùn-ún fún mi.”

Ẹlòmíì tó tún ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn ni Honoré Kamano, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Guinea. Nígbà tó ní kí àwọn ìyàwó rẹ̀ kékeré méjì máa lọ, ìyàwó rẹ̀ àgbà mọyì ohun tó ṣe yìí gan-an, èyí sì mú kí òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn tòótọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kò dùn mọ́ ọ̀kan lára àwọn ìyàwó kékeré náà nínú, síbẹ̀ ó kan sáárá sí ọwọ́ pàtàkì tí ọkùnrin náà fi mú àwọn ìlànà Bíbélì. Ó ní kí wọ́n wá máa kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá.

Wọ́n mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa pé ọwọ́ pàtàkì la fi ń mú ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó

Lónìí, ibi gbogbo nílẹ̀ Sierra Leone àti Guinea ni wọ́n ti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ọwọ́ pàtàkì la fi ń mú ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Bí àwọn tọkọtaya ṣe jẹ́ olóòótọ́ síra wọn ń buyì kún ẹ̀kọ́ Ọlọ́run, ó sì ń fi ìyìn fún Jèhófà tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀.—Mát. 19:4-6; Títù 2:10.

Ìyapa Ṣẹlẹ̀ Ní Ìlú Freetown

Lọ́dún 1956, àwọn méjì míì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì dé sí ìlú Freetown, orúkọ wọn ni Charles àti Reva Chappell. Bí wọ́n ṣe ń lọ sílé tí àwọn míṣọ́nnárì ń gbé, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí àkọlé gàdàgbà kan tí wọ́n fi pe àwọn èèyàn wá sí àsọyé Bíbélì kan tó máa wáyé ní gbọ̀ngàn Wilberforce Memorial Hall. Arákùnrin Charles sọ pé: “Ẹni tí wọ́n sọ pé ó máa sọ àsọyé náà ni C.N.D. Jones, tó jẹ́ aṣojú àwọn kan tí wọ́n pera wọn ní ‘Ẹgbẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Ajẹ́rìí Jèhófà.’”

Jones tó pe ara rẹ̀ ní ẹni àmì òróró ni òléwájú lára àwọn kan tó yapa kúrò nínú ìjọ tó wà ní Freetown lọ́dún mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn. Àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ rẹ̀ yìí máa ń sọ pé àwọn ni “ojúlówó” Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń pe àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn tí kò pa dà lẹ́yìn àwọn aṣojú ètò Ọlọ́run ní “afàwọ̀rajà” tàbí “àwọn ará Gílíádì alákatakítí.”

Ọ̀rọ̀ yẹn le débi pé, wọ́n yọ Jones àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lẹ́gbẹ́. Arákùnrin Chappell sọ pé: “Ìfilọ̀ yìí ya àwọn arákùnrin kan lẹ́nu torí wọ́n rò pé ó yẹ ká ṣì fàyè gba àwọn tó ń dá ìyapa sílẹ̀. Àwọn mélòó kan tiẹ̀ sọ ọ́ ní gbangba pé kò tẹ́ àwọn lọ́rùn. Àwọn yìí àti àwọn míì ń bá àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn kẹ́gbẹ́, wọ́n sì gbìyànjú láti dí wa lọ́wọ́ ní ìpàdé àti lóde ẹ̀rí. Ṣe ni wọ́n máa ń jókòó pọ̀ sí apá kan nínú ìpàdé, ìjókòó àwọn oníyapa la máa ń pe ibi tí wọ́n ń jókòó sí. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló kúrò nínú òtítọ́ nígbà tó yá. Ṣùgbọ́n díẹ̀ lára wọn ṣẹ́rí pa dà, wọ́n sì di akéde tó ń fi ìtara wàásù.”

Bó ṣe jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jú lára àwọn ará ló dúró ṣinṣin mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀mí Ọlọ́run láti máa ṣiṣẹ́ fàlàlà láàárín wa. Nígbà tí Arákùnrin Harry Arnott, alábòójútó láti ilẹ̀ òkèèrè wá sí ìlú Freetown lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ó ní: “Látọdún bíi mélòó kan, ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tá a máa ní ìbísí rẹpẹtẹ lórílẹ̀-èdè Sierra Leone. Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé nǹkan tún máa dára ju báyìí lọ lọ́jọ́ iwájú.”

Bí A Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kọ́ Àwọn Kisi Lẹ́kọ̀ọ́

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìbẹ̀wò Arákùnrin Arnott tí Arákùnrin Charles Chappell gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Làìbéríà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sierra Leone. Arákùnrin yìí fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún àwọn ìbátan rẹ̀ tó wà ní Sierra Leone. Ara àwọn ẹ̀yà Kisi ni, wọ́n ń gbé ní àwọn òkè onígbó àtàwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà ní àgbègbè ibi tí orílẹ̀-èdè Sierra Leone, Làìbéríà àti Guinea ti pààlà. Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Kisi ló ń fẹ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Nítorí pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹ̀yà Kisi kò mọ̀wé kà, a ṣètò kíláàsì tí wọ́n á ti kọ́ àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ní ìlú Koindu. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló rọ́ wá sí àwọn kíláàsì náà. Arákùnrin Charles rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Láìpẹ́, iye akéde tuntun tó wà ní àwùjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i látorí márùn-ún sí mẹ́wàá, sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún títí dórí ogún. Bí àwọn èèyàn ṣe ń yára gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni wọ́n lè jẹ́ ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, torí pé èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló jẹ́ olóòótọ́, tí iná ìtara wọn sì ń jó lala!”

Kò pẹ́ tí àwọn akéde tuntun tó ní ìtara yìí fi wàásù ìhìn rere kọjá ìlú Koindu títí dé orílẹ̀ èdè Guinea tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sierra Leone. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n fi ń rìn gba àwọn ibi tó rí gbágungbàgun kọjá bí wọ́n ṣe ń lọ wàásù láwọn oko àtàwọn abúlé. Arákùnrin Eleazar Onwudiwe tó jẹ́ alábòójútó àyíká nígbà yẹn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù pàápàá máa ń kọjá tí a kì í gbọ́ ìró ọkọ̀ kankan.”

Bí àwọn ará tó jẹ́ ẹ̀yà Kisi ṣe ń fúnrúgbìn Ìjọba Ọlọ́run káàkiri, tí wọ́n sì ń bomi rin ín, Ọlọ́run mú kí ó dàgbà. (1 Kọ́r. 3:7) Nígbà tí ọkùnrin afọ́jú kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́, ó há gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé “Ihinrere Ijọba Yi” sórí, ojú ewé méjìlélọ́gbọ̀n [32] ni ìwé náà ní. Kò sì sí ìpínrọ̀ kankan nínú rẹ̀ tí kò lè rántí tó bá ń wàásù tàbí tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí máa ń ya àwọn tó wá ń wò ó lẹ́nu. Obìnrin adití kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìgbésí ayé rẹ̀ sì yí pa dà débi pé ìyàwó àbúrò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ní láti rìn tó kìlómítà mẹ́wàá kó tó lè débẹ̀.

Iṣẹ́ ìwàásù tètè gbilẹ̀ gan-an láàárín àwọn Kisi. Wọ́n dá ìjọ míì sílẹ̀, lẹ́yìn ìyẹn wọ́n tún dá òmíràn sílẹ̀. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] akéde ló di aṣáájú-ọ̀nà. Olórí ìlú Koindu nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, ó sì fún àwọn ará ní ilẹ̀ kékeré kan kí wọ́n lè fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] èèyàn tó wá sí àpéjọ àyíká tí wọ́n ṣe ní ìlú Kailahun, torí náà wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà tó yá, ìdajì iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Sierra Leone ló jẹ́ ẹ̀yà Kisi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà Kisi yìí kò tó ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbé ní Sierra Leone.

Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni inú wọn dùn sí ìlọsíwájú yìí, pàápàá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n jẹ́ Kisi. Owú mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe tẹ iṣẹ́ wa rì, torí wọ́n ń wò ó pé àwọn ò ní láṣẹ lórí àwọn èèyàn mọ́. Ohun tí a ò mọ̀ ni ọ̀nà tí wọ́n fẹ́ gbé e gbà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́