À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ
Áfíríkà
ILẸ̀ 58
IYE ÈÈYÀN 979,685,702
IYE AKÉDE 1,363,384
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 3,265,314
“Mo Ti Ṣe Tán Báyìí Láti Kúrò Nínú Bábílónì Ńlá”
Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ti tojú sú ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Thomson lórílẹ̀-èdè Uganda. Inú rẹ̀ ò dùn sí bí àwọn olórí ẹ̀sìn ṣe máa ń béèrè owó ṣáá lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kó lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Síbẹ̀, ó ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Nígbà tó ka ìwé Ìṣípayá, ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ìtúmọ̀ ohun tó ń kà sínú ìwé kékeré kan. Nígbà tí arákùnrin kan pàdé Thomson ní ibi iṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn ibi iṣẹ́ ìkọ́lé kan tí kò tóbi púpọ̀, ó rí i tó ń ka Bíbélì. Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn, lẹ́yìn náà Thomson gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ó ka ìwé náà tán lóru mọ́jú. Lọ́jọ́ kejì, àtẹ̀jíṣẹ́ kan wọlé sórí fóònù arákùnrin náà, pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa fún ìwé tẹ́ ẹ fún mi. Mo ti ṣe tán báyìí láti kúrò nínú Bábílónì Ńlá.” Thomson ní kí arákùnrin náà fún òun ní gbogbo ìwé tá a tọ́ka sí nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé àti àfikún àlàyé tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Ó tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kò pẹ́ rárá tó fi ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ó sì ṣe ìrìbọmi ní Àpéjọ Àgbègbè “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!” ti ọdún 2012. Ní oṣù March ọdún 2013, Thomson di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá.
Arákùnrin Mẹ́jọ Ló Kọ́ Ọ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Ìlú Port Louis tó jẹ́ olú ìlú Mauritius ni wọ́n ti tọ́ Jimmy dàgbà. Látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í mutí, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í mutí yó lójoojúmọ́. Tó bá ti mutí yó, ó sábà máa ń ṣinú bí, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ti ṣẹ̀wọ̀n. Nígbà míì, ó máa ń mu tó ìgò ọtí líle mẹ́ta lójúmọ́, ó sì máa ń mu tó ọgọ́ta [60] sìgá lóòjọ́. Ọjọ́ tí kò bá ti sówó lọ́wọ́ rẹ̀, ó máa ń mu ọtí tí wọ́n fi ń nu wíńdò. Kódà, ó mu lọ́fíńdà ìyá rẹ̀. Nígbà tẹ́nì kan sọ fún un pé kò ní pẹ́ kú, ó lọ gba ìtọ́jú níbi tí wọ́n ti ń yọ àwọn èròjà olóró kúrò nínú ara. Ó sì wà níbẹ̀ fún ọdún kan àtààbọ̀, àmọ́ èyí kò yanjú ìṣòro rẹ̀.
Erékùṣù Rodrigues: Jimmy pinnu pé òun máa yí ìgbésí ayé òun pa dà
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jimmy pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́kọ̀ọ̀kan, ó máa pa ìkẹ́kọ̀ọ́ tì, á sì lọ mutí. Bó ṣe di pé arákùnrin mẹ́jọ ló kọ ọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Nígbà tó yá, Jimmy rí i pé ó yẹ kí òun yí ìgbé ayé òun pa dà. Ó sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé idà ẹ̀mí tí Hébérù 4:12 sọ̀rọ̀ rẹ̀ gún mi dọ́kàn. Lọ́jọ́ kan nígbà tí mò ń ka Bíbélì, mo ka ìwé Òwe 24:16, tó sọ pé: ‘Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.’ Ohun tó mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í yí ìgbésí ayé mi pa dà nìyẹn o!” Lẹ́yìn tí àwọn arákùnrin méje ti kọ́ Jimmy lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, síbẹ̀ tó ń “ṣubú,” ó wá pinnu nígbà tó dórí ẹni kẹjọ pé ó tí tó àkókò báyìí fún òun láti “dìde.” Jimmy gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún òun lókun, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, ó sì jáwọ́ nínú àwọn àṣà burúkú. Ó ṣe ìrìbọmi ní ọdún 2003, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé lọ́dún 2012. Ó ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí ní ìjọ kan ní erékùṣù Rodrigues.
“Jèhófà Àtàwọn Áńgẹ́lì Máa Di Ọ̀rẹ́ Mi”
Ẹni àádọ́rin [70] ọdún ni Mary tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian ló sì ń lọ látìgbà tí wọ́n ti bí i. Ó máa ń bá ṣọ́ọ̀ṣì pawó gan-an, òun ló sì kọ́ ọ̀kan lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ládùúgbò wọn. Nígbà tí ọmọ rẹ̀ kan di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú rẹ̀ ò dùn rárá. Ọmọ rẹ̀ máa ń pè é wá sáwọn ìpàdé ìjọ, àmọ́ kò gbà, ó sọ pé èdè ìbílẹ̀ òun, ìyẹn Kikuyu, lòun fẹ́ fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kì í ṣe èdè Swahili. Nígbà tó yá, Mary gbà láti lọ sí àpéjọ àgbègbè tí wọ́n máa ṣe lédè Kikuyu. Nígbà tó dé àpéjọ náà, ó jókòó síbi táwọn àgbàlagbà máa ń jókòó sí. Bí wọ́n ṣe bọ̀wọ̀ fún un, tí wọ́n sì fìfẹ́ hàn sí i wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Mary sọ pé òun ò rí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ rí nínú ṣọ́ọ̀ṣì òun. Ó tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí gbogbo àsọyé àpéjọ náà, inú rẹ̀ sì dùn sóhun tó gbọ́. Nígbà tí wọ́n bi í bóyá ó máa fẹ́ kí ẹnì kan fi ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run, kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó gbà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Lẹ́yìn tó ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mélòó kan, Mary pinnu pé òun máa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà ó kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sílẹ̀. Inú bí àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì náà gan-an. Wọ́n pe pásítọ̀ kan láti ìlú Nairobi tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè wọn, kó lè wá bá a sọ̀rọ̀. Pásítọ̀ náà pàrọwà fún un pé kó má ṣe fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀, àmọ́ kò yẹ ìpinnu rẹ̀. Pásítọ̀ náà wá bi í pé: “Ta lo rò pé ó máa bá ẹ ṣọ̀rẹ́ tó o bá fi ṣọ́ọ̀ṣì yìí sílẹ̀? O lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì yìí, àwọn aládùúgbò rẹ sì pọ̀ níbẹ̀.”
Mary dá a lóhùn pé: “Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì máa di ọ̀rẹ́ mi. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà sì máa dọ̀rẹ́ mi.”
Nígbà tí pásítọ̀ náà rí i pé òun ò lè yí Mary lérò pa dà, ó fi í sílẹ̀. Mary ń bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé rẹ̀ jìnnà sí ibi tá a ti ń ṣèpàdé, ó ń lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ. Láìpẹ́ yìí, nígbà tí kò ṣeé ṣe fún un láti wọ ọkọ̀ èrò lọ sípàdé, ó torí bòjò, ó sì rìn fún wákàtí méjì kó lè wà nípàdé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aládùúgbò rẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí i, ó ti pinnu pé òun ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti ṣe ìrìbọmi.
Orílẹ̀-èdè Làìbéríà: À ń kó àwọn àga tá a máa lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Lọ́dún 2013, àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ 81,762. Iye akéde tó sì wà lórílẹ̀-èdè náà jẹ́ 6,148
Pásítọ̀ Fún Un Ní Ìfásẹ̀!
Orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ni ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] kan tó ń jẹ́ Ashton ń gbé. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀ àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí i, ọ̀dọ̀ wọn ló sì ń gbé. Wọ́n ní ó gbọ́dọ̀ máa bá àwọn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Gba-Jésù táwọn ń lọ. Lọ́jọ́ kan nígbà tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́, pásítọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ sórí àwọn tó wá sí ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n ní ó máa jẹ́ kí ẹ̀mí gbé wọn, wọ́n á sì ṣubú. Àmọ́, Ashton ò ṣubú o. Ni pásítọ̀ bá túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà kíkankíkan, síbẹ̀ Ashton ò ṣubú. Bí pásítọ̀ ṣe fọgbọ́n fún un ní ìfásẹ̀ nìyẹn, ó sì gbé e ṣubú! Nígbà tí wọ́n délé, ó sọ fún ẹ̀gbọ́n bàbá rẹ̀ àti ìyàwó rẹ̀ pé ṣe ni pásítọ̀ yẹn fún òun ní ìfásẹ̀, àmọ́ wọn ò gbà á gbọ́. Ó pinnu lójú ẹsẹ̀ pé òun ò ní lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Ní báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò ń ṣe inúnibíni sí i, wọ́n sì ń kàn án lábùkù, Ashton ò yéé lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Ọmọ Kékeré Kan Fún Un Ní Ìwé Ìkésíni
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Anilpa kò tíì ju ọmọ ọdún kan àti oṣù márùn-ún lọ, òun náà fìtara kópa nínú fífi ìwé ìkésíni pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ àgbègbè lọ́dún tó kọjá ní orílẹ̀-èdè Àǹgólà. Anilpa máa ń kan ilẹ̀kùn, á sì dúró kí onílé jáde wá kó lè fún un ní ìwé ìkésíni náà. Ìyá rẹ̀ ló máa wá ṣàlàyé ní ṣókí ìdí tí wọ́n fi wá fún onílé. Bí Anilpa ṣe nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ yìí tó, kì í sábà dúró kí ìyá rẹ̀ parí ọ̀rọ̀ kó tó lọ kan ilẹ̀kùn tó kàn. Ohun tó ṣe yìí jọ àwọn onílé lójú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ náà obìnrin kan wá bá Anilpa ó sì sọ fún un pé: “Mo ti ń wá ẹ. Inú mi dùn pé mo rí ẹ torí pé ìwọ lo pè mí wá sí àpéjọ yìí.”
Ọ̀rọ̀ Àwọn Aṣáájú Wọn Ti Sú Wọn
Ní oṣù August, ọdún 2012, àwọn akéde láti ìjọ Antaviranambo ní orílẹ̀-èdè Madagásíkà pàdé àwùjọ kan tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìdí sì ni pé ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ti sú wọn, ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n ń sọ lẹ́nu, ọ̀tọ̀ sì lóhun tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n sọ pé wọn kì í kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọn ò sì ní ìwé tó máa ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Owó gegere ni ṣọ́ọ̀ṣì ń bù lé wọn, kò sí ìṣọ̀kan láàárín wọn, wọn ò sì ní ojúlówó ìfẹ́ tó yẹ káwọn Kristẹni ní láàárín ara wọn. Àwọn èèyàn náà sọ pé àwọn mọ̀ pé irú ìṣòrò yìí kò sí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Nígbà tó yá àwùjọ náà kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ohun tí wọ́n sọ nínú lẹ́tà náà ni pé: “A kọ ìwé yìí sí yín kẹ́ ẹ lè mọ̀ pé a fẹ́ sin Jèhófà. Àmọ́, ibi tí à ń gbé jìnnà. Àwọn kan nínú wa máa ń rin ìrìn wákàtí mẹ́sàn-án sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ká tó lè dé ìpàdé. Torí náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ rán ẹnì kan kó wá máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò sí bá a ṣe lè fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà bá a ṣe fẹ́ àyàfi tẹ́ ẹ bá ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wa jẹ́ igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [215], abúlé mẹ́ta ó kéré tán la sì ti wá. Ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ là ń ṣe àmọ́ ní báyìí gbogbo wa la fẹ́ máa sin Jèhófà ká sì máa ṣègbọràn sí i tọkàntọkàn. Ó dá wa lójú pé ẹ máa ràn wá lọ́wọ́.”
Àwọn ará lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn yìí, wọ́n rin ìrìn wákàtí mẹ́sàn-án kí wọ́n tó dé abúlé àkọ́kọ́. Wọ́n ṣe ìpàdé kan níbẹ̀, àwọn èèyàn márùndínláàádọ́rin [65] tí wọ́n fẹ́ sin Jèhófà ló sì wá síbẹ̀. Kò pẹ́ tàwọn èèyàn tó wà lágbègbè yẹn fi gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn tó wà láwọn abúlé míì sì sọ pé àwọn náà fẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí wá sọ́dọ̀ àwọn kí wọ́n lè kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí náà, àwọn ará wa tún rin ìrìn wákàtí mẹ́rin míì lọ sí abúlé kejì, wọ́n sì ṣe ìpàdé kan lábúlé náà, ó ju ọgọ́rin [80] èèyàn tó wá. Ní abúlé yẹn wọ́n tún pàdé àwọn kan táwọn náà tún bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sí abúlé tàwọn náà tó máa gba ìrìn wákàtí méjì míì. Tayọ̀tayọ̀ làwọn ará fi gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ṣe ìpàdé míì níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn tó wá sí ìpàdé níbẹ̀ lé ní àádọ́ta [50].
Nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn èèyàn tó lé ní ọgbọ̀n [30] láti abúlé wọ̀nyí ló wá sí àpéjọ kan tá a ṣe ní ìlú Mahanoro. Wọ́n rìn fún odindi ọjọ́ kan àtààbọ̀ láti débẹ̀, bí wọ́n sì tún ṣe rìn ín pa dà sílé nìyẹn. Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lára wọn ló wá nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Àwọn tó jẹ́ tọkọtaya, àwọn onídìílé àtàwọn àgbàlagbà sì wà lára wọn. Inú ilé kan ni gbogbo wọn sùn. Ilẹ̀ sì ṣú gan-an kí wọ́n tó sùn torí wọ́n ń sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́, wọ́n sì ń béèrè àwọn ìbéèrè. Àwọn èèyàn abúlé náà sọ pé ọ̀pọ̀ ló ṣì máa fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ti sú wọn.