ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 74-77
  • Àgbègbè Oceania

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àgbègbè Oceania
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • “Ó Ti Wá Ń Yé Mi Báyìí”
  • Ó Ṣi Ọkọ̀ Wọ̀
  • “Ọlọ́run Ló Kọ Àwọn Lẹ́tà Náà”
  • Ó Kà Nípa Àwọn Òdòdó
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 74-77
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 74]

À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Àgbègbè Oceania

  • ILẸ̀ 29

  • IYE ÈÈYÀN 39,508,267

  • IYE AKÉDE 96,088

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 63,333

“Ó Ti Wá Ń Yé Mi Báyìí”

Inú adití kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Freda dùn gan-an nígbà tó gbọ́ pé òun àti arábìnrin tó ń kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa wà nínú ìjọ àkọ́kọ́ táá máa lo èdè àwọn adití ní orílẹ̀-èdè Papua New Guinea. Wọ́n dá ìjọ náà sílẹ̀ ní March 1, ọdún 2013. Freda wá rí i pé nígbà tóun ò lo ìwé mọ́, tóun sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn sí ohun tí ẹni tó ń fọwọ́ sọ̀rọ̀ lórí pèpéle ń sọ àti sí fídíò tí wọ́n ṣe lédè àwọn adití, òun túbọ̀ lóye ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé. Inú rẹ̀ dùn láti rí i pé òun ò tijú láti dáhùn nípàdé mọ́, ó tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn léraléra pàápàá. Ní oṣù April 2013, ó kúnjú ìwọ̀n láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ó sì máa ń pe àwọn adití míì wá sí ìpàdé. Nígbà tí wọ́n béèrè ìdí tí omi fi sábà máa ń bọ́ lójú rẹ̀ tó bá wà nípàdé, ó ní, “Ìdí ni pé, ó ti wá ń yé mi báyìí.”

Ó Ṣi Ọkọ̀ Wọ̀

Ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, nígbà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Barbara ń wa ọkọ̀ lọ sí ibi tí àwùjọ wọn ti máa ń pàdé fún òde ẹ̀rí, ó yà sí ẹ̀gbẹ́ títì láti wò ó bóyá òun rántí mú ìwé tóun ń kọ orúkọ àwọn tóun fẹ́ pa dà lọ bẹ̀ wò sí. Lójijì, obìnrin kan ṣí ilẹ̀kùn ọkọ̀, ó sì wọlé.

Barbara sọ fún un pé: “Ẹ jọ̀ọ́, mi ò rò pé ọkọ̀ tẹ́ ẹ fẹ́ wọ̀ nìyí o.”

Obìnrin náà dáhùn pé, “Ẹ máà bínú, mo rò pé ẹ̀yin lẹ fẹ́ wá gbé mi ni.” Nígbà tó rí àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó wà lọ́wọ́ Barbara, obìnrin náà sọ pé, “Àwọn obìnrin méjì kan máa ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n sì máa ń fún mi láwọn ìwé yìí.” Inú Barbara dùn láti fún obìnrin náà ní àwọn ìwé ìròyìn yẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó yá.

“Ọlọ́run Ló Kọ Àwọn Lẹ́tà Náà”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 76]

Orílẹ̀-èdè New Zealand: Violet ń lo lẹ́tà láti kọ́ ọ̀pọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin [82] ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Violet, ara rẹ̀ kò sì le rárá. Ìlú Christchurch, lórílẹ̀-èdè New Zealand ló ń gbé. Ó sábà máa ń kọ lẹ́tà sí àwọn ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà àti ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó lárùn tí kò gbóògùn tó wà ládùúgbò rẹ̀, ó sì tún máa ń fi àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́. Àwọn nọ́ọ̀sì ló máa ń bá a fi àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé náà jíṣẹ́. Àwọn nọ́ọ̀sì náà sọ pé ara àwọn àgbàlagbà táwọn ń tọ́jú ti máa ń wà lọ́nà láti ka àwọn lẹ́tà náà, wọ́n máa ń sọ pé Ọlọ́run ló ń kọ àwọn lẹ́tà náà sáwọn. Àwọn kan nínú wọn máa ń gba àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé náà kà lọ́wọ́ ara wọn tàbí kí wọ́n kà á sétí àwọn yòókù tí kò ríran dáadáa. Àwọn nọ́ọ̀sì náà sọ pé ìwà àwọn tó ń ka àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé ìròyìn náà yàtọ̀ sí ti àwọn tí kì í kà á. Àwọn tó ń kà á máa ń hùwà pẹ̀lẹ́, wọ́n máa ń lẹ́mìí tó dáa, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ ju àwọn tí kì í kà á lọ. Nígbà tí Violet ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe ń wàásù, ó sọ pé: “Mo gbà pé Jèhófà ṣì ń lò mí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ó sì dùn mọ́ mi pé mo lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà yìí.”

Ó Kà Nípa Àwọn Òdòdó

Láàárọ̀ ọjọ́ Sátidé kàn, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Bernie kan ilẹ̀kùn kan nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní erékùṣù Saipan, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama kan tó ń jẹ́ Bernadette ló sì ṣílẹ̀kùn. Nígbà tí Bernie fi Ilé Ìṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọ̀ ọ́, ó fèsì pé, “Mo ti kà á.” Ó ya Bernie lẹ́nu pé Bernadette ti ka ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé náà. Bernie bá tún mú ìwé ìròyìn míì jáde látinú báàgì rẹ̀. Bernadette tún sọ pé: “Mo ti ka ìyẹn náà.” Ó ya Bernie lẹ́nu, ó wá béèrè pé: “Ibo lo ti ka àwọn ìwé ìròyìn yìí? Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, tó o kàn wá lo ọlidé níbí?” Bernadette sọ pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ òun ti ka àwọn ìwé ìròyìn náà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó sọ pé lọ́jọ́ kan, nígbà tóun ń wá ìsọfúnni nípa àwọn òdòdó lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, òun tẹ ọ̀rọ̀ náà “òdòdó” sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ọ̀kan lára àwọn èsì tóun sì rí wọ òun lọ́kàn, ìyẹn àpilẹ̀kọ tó sọ pé: “Alluring Roses From Africa,” tó jáde nínú Jí! kan lédè Gẹ̀ẹ́sì lórí ìkànnì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bernadette sọ pé òun gbádùn àwọn àpilẹ̀kọ náà débi pé òun pinnu láti yẹ ìkànnì náà wò síwájú sí i. Àwọn nǹkan tí wọ́n sọ nípa ewéko àtàwọn ẹranko ló kọ́kọ́ ń kà, àmọ́ kò pẹ́ tí ọkàn rẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí àwọn nǹkan tó dá lé Bíbélì. Nígbà tí Bernie rí i pé Bernadette nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, ó fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ̀ ọ́, ó sì pa dà wá fún un ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Nígbà kẹta tí Bernie máa pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò orí àkọ́kọ́ ìwé náà. Bernadette ṣèrìbọmi ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ìyẹn ní November 2012. Ó yára tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́ débi pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń sọ pé ńṣe ni Bernadette “sáré” wọ inú òtítọ́. Ó dájú pé ìkànnì wa ló mú kí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ yá tó bẹ́ẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́