À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ
Áfíríkà
ILẸ̀ 58
IYE ÈÈYÀN 994,839,242
IYE AKÉDE 1,421,375
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 3,516,524
Wọ́n Tẹ̀ Lé Olùkọ́ Wọn
Etí ìlú Luanda lórílẹ̀-èdè Àǹgólà ni ọ̀dọ́kùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ José ń gbé. Ó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ níléèwé kan tó wà nítòsí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó ṣe máa ń hùwà tó yẹ Kristẹni àti bó ṣe jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá mú kí àwọn ọmọ mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] tó ń kọ́ ní iléèwé náà fẹ́ràn rẹ̀, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un. Aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ni ìpàdé ìjọ rẹ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀, torí náà, ó máa ń tọrọ àyè kó lè tètè ṣíwọ́ iṣẹ́ lọ́jọ́ ìpàdé. Á sì forí lé Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn iṣẹ́.
Àwọn kan lára àwọn ọmọ tí José ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ mọ ìdí tó fi máa ń tètè ṣíwọ́ iṣẹ́ àti ibi tó máa ń lọ. Torí pé méjì lára àwọn ọmọ náà fẹ́ wá fìn-ín ìdí kókò, wọ́n tẹ̀ lé e dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì dúró ṣèpàdé. Nígbà tó yá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta míì tún lọ sí ìpàdé lọ́jọ́ kan tí José níṣẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Kò pẹ́ tí ìròyìn nípa èyí fi tàn kálẹ̀ nínú kíláàsì. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń wá sípàdé bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, látorí márùn-ún sí mọ́kànlélógún [21]. Àwọn ará ìjọ fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn ọmọ iléèwé náà, ọ̀pọ̀ lára wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà mú lára ìwé tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ wá síléèwé, ó wu àwọn míì lára wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Nígbà tí sáà ẹ̀kọ́ fi máa parí nílé ẹ̀kọ́ náà, mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] náà ló ti wá sípàdé. José sọ pé mẹ́tàlélógún [23] lára wọn ló ti ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ń wá sípàdé.
Ṣé Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Kò Tó Ni?
Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà: Joseph àti Evezi ń lo ẹ̀rọ DVD lóde ẹ̀rí
Nígbà tí Joseph àti ìyàwó rẹ̀ Evezi tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe dé ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn tuntun ní Nàìjíríà, àwọn akéde mélòó kan tí ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá sọ fún wọn pé: “Ìpínlẹ̀ ìwàásù wa kò tó. Lemọ́lemọ́ là ń ṣe é.” Lẹ́yìn ọdún kan, Joseph kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé: “Ojoojúmọ́ là ń ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, a sì ń borí ẹ̀tanú àti ìdágunlá. A máa ń gbé ẹ̀rọ kékeré kan tó ṣeé fi wo àwo DVD dání lọ sóde ẹ̀rí ká lè fi àwọn fídíò wa han tọmọdé tàgbà. Èyí ti mú kó ṣeé ṣe fún èmi àti ìyàwó mi láti máa kọ́ àwọn méjìdínlógún [18] lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìgbà míì sì wà tí a kì í lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ọmọdé ò sì yéé sọ pé ká fi ‘fídíò Kọ́lá’ han àwọn.”
Àwọn Tó Ń Gbé ní Erékùṣù Bẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́
Orílẹ̀-Èdè Kóńgò (Kinshasa): Wọ́n ń wàásù fún apẹja kan
Ní oṣù April ọdún 2014, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa) rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ àwùjọ àwọn apẹja tí wọ́n ń gbé ní Erékùṣù Ibinja tó wà níbi Adágún Kivu. Àwọn apẹja náà sábà máa ń ti erékùṣù yìí lọ sí àwọn ìlú tó yí wọn ká láti tajà. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n ń lọ sí ìlú Bukavu, wọ́n bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà wàásù ìhìn rere fún wọn, wọ́n sì fún wọn ní Bíbélì kan àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀.
Ohun tí àwọn apẹja yìí kà nínú ìwé náà mú inú wọn dùn, wọ́n sì sọ àwọn ohun tí wọ́n kọ́ fún àwọn míì ní erékùṣù náà. Torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ní erékùṣù yìí ló nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, àwọn apẹja náà rán ọ̀kan lára wọn pa dà lọ sí ìlú Bukavu pé kó lọ sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá rí níbẹ̀ pé kí wọ́n wá sí erékùṣù Ibinja. Àmọ́ ẹni tí wọ́n rán lọ kò rí wọn, torí náà, ó kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rán àwọn Ẹlẹ́rìí wá sílùú wa káwa náà lè mọ Bíbélì bíi tiwọn, ká sì mọ bá a ṣe lè wà láàyè títí láé. A ṣe tán láti gbà wọ́n lálejò. Màá tiẹ̀ fún yín ní ilẹ̀ tẹ́ ẹ lè kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì yín sí. Àwọn nǹkan tá a rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú àwọn ìwé yín ti jẹ́ ká mọ̀ pé irọ́ làwọn àlùfáà àtàwọn pásítọ̀ ń kọ́ wa. Ó dá wa lójú pé a ti rí ìsìn tòótọ́. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a jọ ń gbé ní erékùṣù Ibinja máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Lẹ́tà yìí fi hàn pé nǹkan bí ogójì [40] èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì ní erékùṣù náà. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún [18,000] èèyàn tó ń gbé níbẹ̀, àmọ́ kò sí Ẹlẹ́rìí kankan láàárín wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe méjì tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn lọ sí erékùṣù náà.
Pásítọ̀ Náà Ti Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Báyìí
“Mi ò ní pa Ìrántí Ikú Kristi jẹ mọ́ láé.” Ohun tí pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì kan tó gbajúmọ̀ lórílẹ̀-èdè South Africa sọ nìyẹn. Kí ló mú kí olórí ẹ̀sìn yìí wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe lóṣù April, ọdún 2014? Lọ́jọ́ kan, àwọn arákùnrin méjì tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra jọ ń wàásù lóde ẹ̀rí, wọ́n sì kan ilẹ̀kùn pásítọ̀ náà. Wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé pásítọ̀ yìí kì í dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóhùn. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adaine sọ pé: “Ẹnu yà wá nígbà tó ṣílẹ̀kùn rẹ̀, tó sì ní ká wọlé. A sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn. Ó yà á lẹ́nu láti rí aláwọ̀ funfun tó ń wàásù nílẹ̀ adúláwọ̀, tó sì ń sọ èdè ìbílẹ̀ adúláwọ̀. Bí pásítọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nìyẹn.”
Arákùnrin Adaine tún sọ pé: “Ó ti lé ní ogójì [40] ọdún tí ọkùnrin yìí ti ń ṣe míṣọ́nnárì àti pásítọ̀, àmọ́ ìgbà tó pé ẹni ọgọ́rin [80] ọdún ló ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀. Ó fẹ́ràn ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn. Tá a bá ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ó máa ń há àwọn ọ̀rọ̀ kan sórí, ó sì máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ náà wàásù ní ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀. Ó tún fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? han àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, ‘Tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá mú ìwé yìí wá sí ilé yín, ẹ gbà wọ́n láyè, kẹ́ ẹ sì tẹ́tí sí ìwàásù wọn torí pé ìṣúra tẹ̀mí ló kún inú ìwé yìí.’”
Pásítọ̀ náà sọ fún Adaine pé àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì òun ti bá òun wí gan-an, wọ́n sì ti kìlọ̀ fún òun pé òun ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ tí òun bá ń wàásù ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ọ̀rọ̀ náà tojú sú Pásítọ̀ yìí. Àmọ́, Adaine rántí ìrírí kan nínú Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013 nípa olùrànlọ́wọ́ àlùfáà kan lórílẹ̀-èdè Myanmar. Nígbà tí Adaine ka ìtàn yìí fún pásítọ̀ náà, ó sọ pé: “Ìtàn mi gan-an nìyí! Mo ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì ní kíámọ́sá.”
Pásítọ̀ náà wá síbi Ìrántí Ikú Kristi fún ìgbà àkọ́kọ́ ni April 14, ọdún 2014, ọjọ́ náà ló sọ pé òun ò ní pa Ìrántí kú Kristi jẹ mọ́ láé. Ó sì sọ pé òun ti pinnu láti jáwọ́ pátápátá nínú ìsìn èké.
À Ń Wá Àwọn Èèyàn Lọ Sínú Oko Kòkó
Orílẹ̀-Èdè Gánà: Arákùnrin Baffour àti Aaron ń wàásù ní oko kòkó
Ìlú Bokabo tí wọ́n ti ń ṣọ̀gbìn kòkó lápá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Gánà ni Arákùnrin Baffour àti Aaron ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn ò sí lójú kan náà, ilé kéékèèké ló sì wà níbẹ̀. Kéèyàn tó lè débẹ̀, àfi kó rin ojú ọ̀nà tó rí kọ́lọkọ̀lọ gba inú àwọn oko kòkó kọjá. Ó rọrùn láti ṣìnà téèyàn bá yà síbi tí kò yẹ kó yà sí! Lọ́jọ́ kan, Arákùnrin Baffour àti Aaron ṣìnà, wọ́n sì lọ já sí àwọn abà tí wọn kò tíì dé rí. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí Michael àti Patience tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, Michael sọ fún wọn pé: “Ó ti pé ọdún méjì báyìí tá a ti fi ẹsẹ̀ kan ṣọ́ọ̀ṣì gbẹ̀yìn torí àwọn nǹkan tá a rí níbẹ̀ kò bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu. Látìgbà yẹn ni èmi àti Patience ti máa ń dá nìkan ka Bíbélì nírọ̀lẹ́ ká lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa. A ti ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí òtítọ́.” Láìka ọ̀nà tó jìn tí wọ́n ní láti máa rìn gba inú oko kòkó náà kọjá, ojú ẹsẹ̀ làwọn méjèèjì ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Tọkọtaya náà ṣèrìbọmi lọ́dún tó kọjá, wọ́n sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ní báyìí, àwọn náà ti ń gba àwọn ọ̀nà tóóró tó rí kọ́lọkọ̀lọ nínú àwọn oko kòkó láti ṣàwárí àwọn tó ‘ti ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí òtítọ́.’
Michael àti Patience ń gba inú oko kòkó kọjá