BalanceFormcreative/iStock via Getty Images Plus
Máa Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kó O Má Bàa Dá Wà—Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló máa ń dá wà, tí wọn ò sì rẹ́ni fojú jọ. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan lórí ọ̀rọ̀ ìlera gbà pé téèyàn bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kéèyàn máa rò pé òun dá wà.
“Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó máa jẹ́ ká gbà pé à ń gbélé ayé ṣe nǹkan ire, kò sì ní jẹ́ ká máa rò pé a ò rẹ́ni fojú jọ.”—Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlera Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn lórí àwọn nǹkan tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Tá a bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, kò ní jẹ́ ká máa wo ara wa bíi pé a ò rẹ́ni fojú jọ.
Ohun tó o lè ṣe
Máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan. Máa wáyè fáwọn èèyàn, bóyá kó o lọ kí wọn nílé tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣeré jáde. Múra tán láti pín ohun tó o ní pẹ̀lú wọn. Àwọn tó o ṣe lóore á fẹ́ fi hàn pé àwọn mọyì ohun tó o ṣe, ìyẹn sì lè jẹ́ kẹ́ ẹ dọ̀rẹ́.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ sọ ọ́ di àṣà láti máa fúnni, àwọn èèyàn sì máa fún yín.”—Lúùkù 6:38.
Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Wá ọ̀nà láti ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè tẹ́tí sí wọn tí wọ́n bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, o sì lè bá wọn ṣe àwọn nǹkan kan tó máa jẹ́ kára tù wọ́n.
Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo.”—Òwe 17:17, Yoruba Bible.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, ka àpilẹ̀kọ náà, “Ìdílé Aláyọ̀ àti Ọ̀rẹ́ Àtàtà.”