ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 113
  • Ìwà Ọmọlúàbí Ti Ṣọ̀wọ́n—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Ọmọlúàbí Ti Ṣọ̀wọ́n—Kí Ni Bíbélì Sọ?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí tí kò fi sí ìwà ọmọlúàbí mọ́?
  • Ohun táá jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní ìwà ọmọlúàbí
  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ń Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
  • Àwọn Ìlànà Rere Ń jó Àjórẹ̀yìn
    Jí!—2003
  • Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ìdí Tí Ìwà Ọmọlúwàbí Fi Ṣe Pàtàkì
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 113
Ọ̀dọ́bìnrin kan ran ìyá àgbàlagbà kan lọ́wọ́ kó lè jókòó nínú bọ́ọ̀sì.

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ìwà Ọmọlúàbí Ti Ṣọ̀wọ́n​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ìwà ọmọlúàbí kò wọ́pọ̀ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ló máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn dókítà. Àwọn tó lọ ń jẹun nílé oúnjẹ sábà máa bú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Kò tán síbẹ̀ o, lára àwọn tó ń wọ ọkọ̀ òfúrufú máa ń kanra mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òfúrufú. Bákan náà, àwọn ọmọ ilé ìwé tó ti yàyàkuyà máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn olùkọ́ wọn, wọ́n sì máa n lù wọ́n nígbà míì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn olóṣèlú kan máa ń ṣe ohun májẹ̀ágbọ́, àwọn olóṣèlú míì sì máa ṣojú ayé bíi pé ọmọlúàbí ni wọ́n.

Bíbélì sọ ohun tó túmọ̀ sí láti ní ìwà ọmọlúàbí. Ó sì tún jẹ́ ká mọ ìdí tí ìwà ọmọlúàbí fi ṣọ̀wọ́n nínú ayé lónìí.

Kí nìdí tí kò fi sí ìwà ọmọlúàbí mọ́?

Kárí ayé ni àwọn èèyàn ò ti ní ìwà ọmọlúàbí mọ́, wọn kì í ka àwọn èèyàn sí, wọn kì í sì í pọ́n wọn lé.

  • Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, wọ́n rí i pé àsìkò yìí ni ìwà ọmọlúàbí tíì ṣọ̀wọ́n jù lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti nǹkan bí ọdún méjìlélógún (22) sẹ́yìn.

  • Nínú ìwádìí míì, wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) láti orílẹ̀-èdè méjìdínlọ́gbọ̀n (28), àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méje nínú mẹ́wàá ló sọ pé bí ìwà ọmọlúàbí ṣe pòórá láwùjọ ń kọni lóminú gan-an.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìwà táwọn èèyàn á máa hù lónìí.

  • “Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, . . . aláìnífẹ̀ẹ́, [àti] aláìlè-kó-aràwọn-níjánu.”​—2 Tímótì 3:1-3, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-òní.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?”

Ohun táá jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní ìwà ọmọlúàbí

Nínú ayé tí ìwà ọmọlúàbí ti ṣọ̀wọ́n, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé Bíbélì ṣàlàyé ohun tí èèyàn lè ṣe kó lè ní ìwà ọmọlúàbí. Àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ ṣeé “gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé.” (Sáàmù 111:8) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀:

  • Ohun tí Bíbélì sọ: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.”​—Mátíù 7:12.

    Ohun tó túmọ̀ sí: Torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà dáadáa sí wa, ṣe ló yẹ káwa náà máa bọ̀wọ̀ fún wọn ká sì máa hùwà dáadáa sí wọn.

  • Ohun tí Bíbélì sọ: “Ní báyìí tí ẹ ti fi ẹ̀tàn sílẹ̀, kí kálukú yín máa bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́.”​—Éfésù 4:25.

    Ohun tó túmọ̀ sí: Ó yẹ ká máa sọ òótọ́ nígbà gbogbo, ká sì máa hùwà tó fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, o lè lọ ka:

  • Ilé Ìṣọ́ tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa.”

  • Àpilẹ̀kọ “Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́