Wàhálà Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lágbo Òṣèlú Fi Hàn Pé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ń Ṣẹ
Lónìí èrò àwọn èèyàn ò ṣọ̀kan tó bá di ọ̀rọ̀ òṣèlú. Tí ìjọba bá gbé òfin tí kò bá wọn lára mu kalẹ̀, ṣe làwọn èèyàn máa ń fàáké kọ́rí, wọ́n á sì fi ẹ̀hónú wọn hàn. Àìgbọ́ra-ẹni-yé máa ń wáyé láàárín àwọn aṣòfin àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, wọn ò sì ṣe tán láti gbà fún ra wọn. Àwọn nǹkan yìí máa ń dá wàhálà sílẹ̀ lágbo òṣèlú kì í sì í jẹ́ kí ìjọba lè ṣiṣẹ́ wọn dáadáa.
Àpẹẹrẹ kan tó gba àfiyèsí ni wàhálà tó ń lọ lágbo àwọn olóṣèlú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Britain. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wàhálà á máa ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn olóṣèlú láwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí, ìyẹn sì máa ṣẹlẹ̀ lákòókò tí Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ máa dá sí ọ̀rọ̀ aráyé.
Wàhálà lágbo òṣèlú ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́”
Àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan wà nínú ìwé Dáníẹ́lì. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, Ọlọ́run jẹ́ ká mọ “ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” Lákòókò tí Dáníẹ́lì kọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sílẹ̀, ṣe ló ń sọ̀rọ̀ nípa ohun pàtàkì kan tó máa ṣẹlẹ̀ sí ìjọba èèyàn lọ́jọ́ iwájú.—Dáníẹ́lì 2:28.
Ọlọ́run fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí han ọba Bábílónì lójú àlá. Nínú àlá yẹn ọba náà rí ère ràgàjì kan. Nígbà tó yá, wòlíì Dáníẹ́lì ṣàlàyé pé ère náà látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀ dúró fún gbogbo ìjọba alágbára tó máa ṣàkóso ayé.a Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, òkúta kan tó ṣàpẹẹrẹ Ìjọba Ọlọ́run kọlu ère náà, ó sì fọ́ ọ túútúú.—Dáníẹ́lì 2:36-45.
Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn. Ìjọba yìí ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún nígbà tó sọ pé: “Kí Ìjọba rẹ dé.”—Mátíù 6:10.
Àmọ́ apá ibo nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló jẹ́ ká mọ̀ pé wàhálà á máa ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn olóṣèlú? Ẹ máa kíyè sí i pé, àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà jẹ́ “apá kan irin àti apá kan amọ̀.” (Dáníẹ́lì 2:33) Bó ṣe jẹ́ pé oríṣi nǹkan méjì ni wọ́n fi ṣe àtẹ́lẹsẹ̀ yẹn mú kó yàtọ̀ sí gbogbo apá tó kù lára ère náà. Ìyẹn fi hàn pé, ọ̀kan lára àwọn ìjọba alágbára tó máa ṣàkóso ayé yìí máa yàtọ̀ sáwọn tó kù. Báwo la ṣe mọ̀? Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣàlàyé pé:
Bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, wàhálà á máa ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn olóṣèlú ní orílẹ̀-èdè alágbára tí àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà ṣàpẹẹrẹ. Ohun táwọn aráàlú á máa ṣe kò ní jẹ́ kí orílẹ̀-èdè alágbára yìí lè lo agbára ẹ̀ bó ṣe fẹ́.
Bí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣe ṣẹ lónìí
Àtẹ́lẹsẹ̀ ère yẹn ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba tó lágbára jù lónìí, ìyẹn sì ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Britain. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lónìí tó mú ká gbà bẹ́ẹ̀?
Torí pé “apá kan irin àti apá kan amọ̀” ni àtẹ́lẹsẹ̀ ère náà, kò ní lágbára. (Dáníẹ́lì 2:42) Lónìí, ìjọba Amẹ́ríkà àti Britain ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára torí pé ìṣọ̀kan ò sí láàárín àwọn aráàlú. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè méjèèjì, ẹnu àwọn aráàlú ò kò, wọ́n sì máa ń ta ko ara wọn lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìlú. Bákan náà, àwọn èèyàn máa ń fẹ̀hónú hàn tí wọ́n bá ń jà fẹ́tọ̀ọ́ wọn. Kódà, àwọn tí wọ́n yàn sípò ìjọba pàápàá kì í gbọ́ra wọn yé lórí àwọn ìlànà tó yẹ kí ìjọba gbé kalẹ̀. Báwọn aráàlú ò ṣe wà níṣọ̀kan yìí máa ń jẹ́ kó ṣòro fún orílẹ̀-èdè méjèèjì láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.
Dáníẹ́lì orí 2 sọ bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn ìjọba tó ń ṣàkóso
Ẹ jẹ́ ká tún wo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì nípa àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì yìí àti bó ṣe ń ṣẹ lónìí:
Àsọtẹ́lẹ̀: “Ìjọba náà máa pínyà, àmọ́ ó ṣì máa le bí irin lápá kan.”—Dáníẹ́lì 2:41.
Ohun tó túmọ̀ sí: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹnu àwọn olóṣèlú ò kò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Britain, wọ́n ṣì lágbára torí wọ́n láwọn ọmọ ogun àtohun ìjà ogun tó pọ̀ gan-an. Torí náà, wọ́n lè lo agbára tó le bí irin láti ṣe àwọn nǹkan tó máa kan gbogbo ayé.
Bó ṣe ṣẹ
Nígbà tí wọ́n wo iye táwọn orílẹ̀-èdè ná lórí nǹkan ìjà ogun lọ́dún 2023, wọ́n rí i pé àpapọ̀ iye tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Britain ná ju àpapọ̀ iye tí àwọn orílẹ̀-èdè méjìlá (12) tó tẹ̀ lé wọn ná.—Stockholm International Peace Research Institute.
“Bí Britain àti Amẹ́ríkà ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti . . . dáàbò bo orílẹ̀-èdè wọn ti jẹ́ kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín wọn. . . . A jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, à ń ti ara wa lẹ́yìn, a sì jọ ń bá àwọn ọ̀tá wa jà.”—Strategic Command, U.K. Ministry of Defence, April 2024.
Àsọtẹ́lẹ̀: “Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ sì ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba náà ṣe máa lágbára lápá kan, tí kò sì ní lágbára lápá kan.”—Dáníẹ́lì 2:42.
Ohun tó túmọ̀ sí: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára, wọ́n sì láwọn ohun ìjà ogun tó pọ̀ gan-an, kì í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe ni wọ́n lè ṣe torí bí wọ́n ṣe ń ṣèjọba. Tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn aráàlú ò bá fọwọ́ sí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, kì í rọrùn fún wọn láti ṣe ohun tí wọ́n ní lọ́kàn.
Bó ṣe ṣẹ
“Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ò wà níṣọ̀kan, ìyẹn ni ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láṣeyọrí tó bá dọ̀rọ̀ ààbò àti ọrọ̀ ajé.”—“The Wall Street Journal.”
“Àwọn ìṣòro tí ò ṣẹlẹ̀ rí ló ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn olóṣèlú ní Britain, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ní lọ́kàn fáwọn aráàlú.”—Institute for Government.
Àsọtẹ́lẹ̀: “Wọ́n [ìyẹn ìjọba yìí] máa dà pọ̀ mọ́ àwọn mẹ̀kúnnù; àmọ́ wọn ò ní lẹ̀ mọ́ra.”—Dáníẹ́lì 2:43, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Ohun tó túmọ̀ sí: Òótọ́ ni pé nínú ìjọba tiwa ń tiwa àwọn aráàlú lè sọ ohun tí wọ́n fẹ́, síbẹ̀ ohun tí ìjọba máa ṣe lè má tẹ́ wọn lọ́rùn.
Bó ṣe ṣẹ
“Lónìí, àwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ò fojú gidi wo àwọn olóṣèlú, wọn ò sì fara mọ́ ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣèjọba.”—Pew Research Center.
“Àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ fọkàn tán àwọn olóṣèlú mọ́ tá a bá fi wé bí wọ́n ṣe ń gbé wọn gẹ̀gẹ̀ ní nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún sẹ́yìn.”—“National Centre for Social Research.”
Bí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú
Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba Amẹ́ríkà àti Britain lá máa ṣàkóso lọ́wọ́ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn.—Dáníẹ́lì 2:44.
Ìwé Ìfihàn sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jọ èyí, níbẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” máa kóra jọ láti bá Jèhófàb Ọlọ́run jà nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìfihàn 16:14, 16; 19:19-21) Nígbà ogun náà, Jèhófà máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run, á sì fòpin sí gbogbo ìjọba alágbára tí apá kọ̀ọ̀kan ère tí Dáníẹ́lì rí ṣàpẹẹrẹ.
Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?”
Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì lè ṣe ẹ́ láǹfààní
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé wàhálà á máa ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn olóṣèlú ní Amẹ́ríkà àti Britain, gbogbo ohun tó sọ ló sì ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí. Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí á túbọ̀ yé ẹ.
Wàá rí ìdí tí Jésù fi sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe dá sọ́rọ̀ òṣèlú. (Jòhánù 17:16) Wàá tún mọ ìdí tí Jésù, ìyẹn ẹni tí Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run fi sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”—Jòhánù 18:36.
Ó máa túbọ̀ dá ẹ lójú pé láìpẹ́ Jèhófà máa tún ayé yìí ṣe àti pé ó máa ṣe àwọn ohun rere fún aráyé bó ṣe ṣèlérí.—Ìfihàn 21:3, 4.
Ẹ̀rù ò ní máa bà ẹ́ nítorí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí á dá ẹ lójú pé wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ò ní pa ayé yìí run.—Sáàmù 37:11, 29.
Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì jẹ́ ká rí i pé ẹsẹ̀ ère náà ṣàpẹẹrẹ ìjọba Amẹ́ríkà àti Britain, òun sì ni ìjọba alágbára tó kẹ́yìn tó máa ṣàkóso ayé. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run máa fi Ìjọba rẹ̀ tí ò láfiwé rọ́pò ìjọba èèyàn!
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé, wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
a Wo àpótí náà “Àwọn Ìjọba Alágbára Tí Dáníẹ́lì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Wọn”
b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”