Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà ní Ayé?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Gbogbo ìsapá àwọn èèyàn láti mú kí àlàáfíà wà ní ayé ló ń já sí pàbó, bí yóò sì ṣe máa rí nìyẹn torí pé:
- “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ọlọ́run kò dá àwọn èèyàn wọn pé kí wọ́n máa ṣàkóso ara wọn, torí náà, àlàáfíà tí wọ́n bá jàjà ní kò ní wà pẹ́ títí. 
- “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:3, 4) Tá a bá tiẹ̀ rí lára àwọn olórí ìjọba èèyàn tó fẹ́ ṣe ohun tó tọ́, wọ́n ò lè mú àwọn ohun tó ń fa ogun kúrò pátápátá. 
- “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:1–4) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú yìí la wà, àwọn ìwà tí àwọn èèyàn ń hù mú kó ṣòro láti ní àlàáfíà. 
- “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Wọ́n ti lé Èṣù, tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́rún, wá sí sàkáání ilẹ̀ ayé. Òun ló ń mú kí àwọn èèyàn máa hùwà ìkà bíi tiẹ̀. A kò lè ní àlàáfíà níwọ̀n ìgbà tó bá jẹ́ òun ṣì ni “olùṣàkóso ayé yìí.”—Jòhánù 12:31. 
- “[Ìjọba Ọlọ́run] yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [tó ń ta ko Ọlọ́run] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba Ọlọ́run ló máa fún wa ní ohun táá tẹ́ wa lọ́rùn, ìyẹn àlàáfíà tí kò lópin kárí ayé, kì í ṣe ìjọba èèyàn.—Sáàmù 145:16.