ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 30
  • Ohun Méjì Wo Ni Kì Í Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dáhùn Àwọn Àdúrà Kàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Méjì Wo Ni Kì Í Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dáhùn Àwọn Àdúrà Kàn?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kì Í Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Adura Awọn Wo Ni A Ndahun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣé Jèhófà Máa Dáhùn Àdúrà Mi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 30

Ohun Méjì Wo Ni Kì Í Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dáhùn Àwọn Àdúrà Kan?

Ohun tí Bíbélì sọ

Àwọn àdúrà kan wà tí Ọlọ́run kì í dáhùn. Wo ohun méjì tó lè mú kí ẹnì kan gbàdúrà kí Ọlọ́run má sì gbọ́.

1. Tí àdúrà yẹn bá ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run

Ọlọ́run kì í gbọ́ àwọn àdúrà tó bá ta ko ìfẹ́ rẹ̀ tàbí àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe. (1 Jòhánù 5:14) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ká má ṣe jẹ́ oníwọra. Ńṣe ni tẹ́tẹ́ títa máa ń sọni di oníwọra. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Torí náà, Ọlọ́run kò ní dá ọ lóhùn tó o bá ń gbàdúrà pé kó jẹ́ kó o jẹ tẹ́tẹ́. Ọlọ́run kì í ṣe àǹjọ̀nnú téèyàn kàn lè máa pè láti máa ṣe gbogbo ohun tó bá ṣáà ti wù ú. Ó sì yẹ kéyìí máa dùn mọ́ ẹ nínú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ńṣe lò bá máa bẹ̀rù pé bóyá ẹnì kan máa rán Ọlọ́run kó wá bá ọ jà.—Jákọ́bù 4:3.

2. Tẹ́ni tó ń gbàdúrà bá jẹ́ aṣetinú-ẹni

Ọlọ́run kì í gbọ́ àdúrà àwọn tó bá ti pinnu láti máa ṣe ohun tó ń dun Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún àwọn kan tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́rùn àmọ́ tó jẹ́ pé ìfẹ́ inú ara wọn ni wọ́n ń ṣe pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Aísáyà 1:15) Àmọ́ ká ní wọ́n ti yí pa dà ni tí wọ́n sì “mú àwọn ọ̀ràn [wọn] tọ́” lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ì bá gbọ́ wọn nígbà tí wọ́n gbàdúrà sí i.—Aísáyà 1:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́