ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwfq àpilẹ̀kọ 48
  • Ṣé Èèyàn Lè Kúrò Nínú Ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Èèyàn Lè Kúrò Nínú Ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
  • Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tẹ́nì kan ò bá wàásù mọ́ tàbí tí kò wá sí ìpàdé yín mọ́ ńkọ́? Ṣé ẹ máa ka ẹni náà mọ́ ara àwọn tó ti kúrò nínú ẹ̀sìn yín ni?
  • Yóò Ṣẹ́ Ku Ìsìn Kan Ṣoṣo
    Jí!—1996
  • Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ Kristẹni
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwfq àpilẹ̀kọ 48
Ọkùnrin kan ń kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba

Ṣé Èèyàn Lè Kúrò Nínú Ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun méjì ni ẹnì kan lè ṣe tó bá fẹ́ kúrò nínú ẹ̀sìn wa:

  • Ó lè sọ fún wa. Tẹ́nì kan bá pinnu pé òun ò fẹ́ ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ó lè bá wa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ tàbí kó kọ̀wé sí wa.

  • Ó lè gbé ìgbésẹ̀. Ẹnì kan lè ṣe ohun kan tó máa fi hàn pé òun ò sí lára ẹgbẹ́ ará wa tó wà kárí ayé mọ́. (1 Pétérù 5:9) Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe ẹ̀sìn míì, kó sì jẹ́ kó hàn pé ẹ̀sìn yẹn lòun fẹ́ máa ṣe báyìí.​—1 Jòhánù 2:​19.

Tẹ́nì kan ò bá wàásù mọ́ tàbí tí kò wá sí ìpàdé yín mọ́ ńkọ́? Ṣé ẹ máa ka ẹni náà mọ́ ara àwọn tó ti kúrò nínú ẹ̀sìn yín ni?

Rárá, a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tó kúrò nínú ẹ̀sìn wa tàbí tó pinnu pé òun ò dara pọ̀ mọ́ wa mọ́ yàtọ̀ sí ẹni tó nígbàgbọ́, àmọ́ tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò lágbára mọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, tẹ́nì kan ò bá jọ́sìn déédéé tàbí ti ò jọ́sìn mọ́, kì í ṣe pé ó ti kúrò nínú ẹ̀sìn yẹn, ó lè jẹ́ pé onítọ̀hún ti ń rẹ̀wẹ̀sì ni. Dípò tá a fi máa wá pa ẹni náà tì, ṣe la máa ń gbìyànjú láti tù ú nínú, ká sì ràn án lọ́wọ́. (1 Tẹsalóníkà 5:​14; Júúdà 22) Tẹ́ni náà bá fẹ́ ká ran òun lọ́wọ́, àwọn alàgbà nínú ìjọ ló máa kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà sún mọ́ Ọlọ́run.​—Gálátíà 6:1; 1 Pétérù 5:​1-3.

Àmọ́, àwọn alàgbà ò láṣẹ láti fipá mú ẹnì kan pé kò gbọ́dọ̀ kúrò nínú ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kálukú ló máa pinnu ẹ̀sìn tó máa ṣe. (Jóṣúà 24:15) A gbà pé téèyàn bá fẹ́ sin Ọlọ́run, ó yẹ kó ṣe é látọkàn wá, kò yẹ kí wọ́n fipá mú un.​—Sáàmù 110:3; Mátíù 22:37.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́