Ṣé Pọ́gátórì Wà Nínú Bíbélì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Rárá, kò sí níbẹ̀. A ò lè rí ọ̀rọ̀ náà, “pọ́gátórì” nínú Bíbélì, Bíbélì ò sì fi kọ́ni pé a máa ń yọ́ ọkàn àwọn tó ti kú mọ́ ní pọ́gátórì.a Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, àti bí ohun tó sọ ṣe ta ko ẹ̀kọ́ pọ́gátórì.
Ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù ló máa ń wẹ èèyàn mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, kì í ṣe pọ́gátórì. Bíbélì sọ pé “ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ [Ọlọ́run] . . . ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀” àti pé “Jésù Kristi . . . dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 1:7; Ìṣípayá 1:5, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Jésù fi “ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan” láti gbà wọ́n kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.—Mátíù 20:28, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.
Àwọn tó ti kú kò mọ nǹkan mọ́. “Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́.” (Oníwàásù 9:5, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ẹni tó ti kú ò lè mọ nǹkan kan lára, torí náà, kò sí nǹkan tó ń jẹ́ pé iná pọ́gátórì kan ń yọ́ ẹni tó ti kú mọ́.
Téèyàn bá ti kú, ó ti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìyẹn. Bíbélì sọ pé “ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀” àti pé “ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:7, 23, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, téèyàn bá ti kú, ó ti jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.
a Ìwé Orpheus: A General History of Religions sọ̀rọ̀ nípa pọ́gátórì, ó ní “kò sírú ọ̀rọ̀ yẹn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.” Bákan náà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ibi tá a parí èrò sí ni pé, ọ̀rọ̀ pọ́gátórì tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ń kọ́ni kò sí nínú Ìwé Mímọ́, inú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ló ti wá.”—Ẹ̀dà Kejì, Ìdìpọ̀ 11, ojú ìwé 825.
b Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia, Ẹ̀dà Kejì, Ìdìpọ̀ 11, ojú ìwé 824.