ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbv àpilẹ̀kọ 56
  • Gálátíà 6:9—“Kí Á Má Ṣe Jẹ́ Kí Ó Sú Wa Láti Ṣe Rere”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gálátíà 6:9—“Kí Á Má Ṣe Jẹ́ Kí Ó Sú Wa Láti Ṣe Rere”
  • Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtumọ̀ Gálátíà 6:9
  • Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Gálátíà 6:9
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Pọ́ọ̀lù Kọ Lẹ́tà Sáwọn Ìjọ
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Róòmù 12:12—“Ẹ Ma Yọ̀ ni Ireti; Ẹ Ma Mu Suru Ninu Ipọnju; Ẹ Ma Duro Gangan Ninu Adura”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
ijwbv àpilẹ̀kọ 56

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Gálátíà 6:9​—“Kí Á Má Ṣe Jẹ́ Kí Ó Sú Wa Láti Ṣe Rere”

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, torí tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.”​—Gálátíà 6:9, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

“Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá.”​—Gálátíà 6:9, Yoruba Bible.

Ìtumọ̀ Gálátíà 6:9

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n má jẹ́ kó sú wọn láti máa ṣe ohun tó dáa lójú Ọlọ́run. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa san wọ́n lẹ́san.

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́.” A tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “kí á ma ṣe jẹ́ kí ó sú wa.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tún lè túmọ̀ sí kéèyàn má rẹ̀wẹ̀sì tàbí kó má jẹ́ kí ìtara ẹ̀ dín kù. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe pe ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ara ẹ̀ jẹ́ ká rí i pé àwọn ìgbà kan wà tí òun náa ní láti jà fitafita kó má bàa rẹ̀wẹ̀sì.​—Róòmù 7:21-24.

“Ṣíṣe rere,” tàbí ṣíṣe ohun tó dáa kan gbogbo ohun tó yẹ kí Kristẹni kan ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Lára irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun téèyàn bá ṣe láti ran àwọn Kristẹni àtàwọn mìí lówọ́.​—Gálátíà 6:10.

“Tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.” Pọ́ọ̀lù rán àwọn tó ń gbórọ̀ ẹ̀ létí pé bó ṣe máa ń gba àkókò kí ohun tí àgbẹ̀ kan gbìn tó méso jáde bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń gba àkókò kéèyan tó rí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe rere. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a máa kórè, ṣe ló ń fìdí ohun tó sọ ní ẹsẹ 7 múlẹ̀ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” Lédè míì tí Kristẹni kan bá ń ṣe ohun tó dáa lójú Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run fi máa san án lẹ́san, á sì fún un ní ìyè àìnípẹ̀kun.​—Róòmù 2:6, 7; Gálátíà 6:8.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Gálátíà 6:9

Nńkan bí ọdún 50 sí 52 Sànmánì Kristẹni ní Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sí àwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Gálátíà. Ó kọ lẹ́tà yìí kó lè kìlọ̀ nípa àwọn kan tó ń pera wọn ní Kristẹni àmọ́ tí wọ́n ń sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa Jésù. (Gálátíà 1:6, 7) Àwọn olùkọ́ èké yìí ń kọ́ni pé ó pọn dandan káwọn Kristẹni máa ṣègboràn sí Òfin Mósè tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Gálátíà 2:15, 16) Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé pé òfin náà ti parí iṣẹ́ ẹ̀ àti pé àwọn Kristẹ́ni ò sí lábẹ́ òfin yìí mọ́.​—Róòmù 10:4; Gálátíà 3:23-25.

Kì í ṣe ọ̀rọ̀ pípa Òfin Mósè mọ́ ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe “jáwọ́ nínú ṣíṣe rere.” Ohun tó ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n “mú òfin Kristi ṣẹ.” Ìyẹn sì gba pé kí wọ́n máa ṣègbọràn sí gbogbo ohun tí Jésù sọ nípa bá a ṣe lè máa ṣe rere fáwọn èèyàn.​—Gálátíà 6:2; Mátíù 7:12; Jòhánù 13:34.

Ka Gálátíà 6 nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bíbélì yìí rọrùn kà, ó sì ní àwọn àtẹ́tísí, àlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, atọ́ka etí ìwé, àwòrán, fídíò àti àwòrán ilẹ́.

Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Gálátíà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́