Igbó Kìjikìji Amazon—Àròsọ Bò ó Mọ́lẹ̀
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRAZIL
OHUN tí àwọn ẹ̀yà Ámẹ́ríńdíà ti Irimarai tí ń gbé ní ipa Odò Napo ní Peru rí yà wọ́n lẹ́nu gan-an! Ọkọ̀ òkun tí a ta aṣọ ìgbòkun sí lọ́nà méjì, tí kò dà bí àwọn ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ pẹnpẹ tiwọn, ń bọ̀ ní abúlé wọn. Wọ́n gán-ánní àwọn jagunjagun abirùngbọ̀n-yẹ́úkẹ́ nínú ọkọ̀ náà—tí wọ́n yàtọ̀ sí ẹ̀yà èyíkéyìí mìíràn tí wọ́n tí ì rí rí. Àwọn ẹ̀yà Ámẹ́ríńdíà tí ṣìbáṣìbo bá náà sáré kìtìkìtì wá ibi lù mọ́, wọ́n sì ń wòye bí àwọn àjèjì aláwọ̀ funfun náà ṣe ń bẹ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ òkun, tí wọ́n jẹ ìpèsè oúnjẹ abúlé náà run, wọ́n sì wakọ̀ lọ pa dà—èrò pé yóò di ohun ìtàn gẹ́gẹ́ bí ìrìn àjò akọni àkọ́kọ́ la igbó kìjikìji náà kọjá lódindi, láti àwọn Òkè Ńlá Andes dé Òkun Àtìláńtíìkì ń ru wọ́n sókè.
Láàárín ọdún yẹn, 1542, ẹ̀yà Ámẹ́ríńdíà kan sí òmíràn jìyà irú ìkìmọ́lẹ̀ jíjọra bí àwọn olùyẹ̀wòkiri ará Europe wọ̀nyẹn, tí ń gbé ọfà àti ìbọn àgbétiǹkanyìn fìrìfìrì, ṣe ń rọ́ wọ igbó ilẹ̀ olóoru Gúúsù America jinlẹ̀jinlẹ̀.
Francisco de Orellana, ọ̀gákọ̀ ará Sípéènì tí ń darí àwọn aṣẹ́gun náà, mọ̀ láìpẹ́ pé ìròyìn ìpiyẹ́ àti ìbọn tí awọn ọmọ ogun rẹ̀ ń yìn ti ṣáájú wọn dé ibi tí ọkọ̀ òkun wọn kò tí ì gbé wọn dé. Àwọn ẹ̀yà Ámẹ́ríńdíà tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀ odò lọ́nà jíjìn lọ́hùn-ún (nítòsí ìlú ńlá Manaus ní Brazil lónìí) ti kó ọfà wọn lọ́wọ́ ní ìgbáradì de àwọn akóguntini tí iye wọ́n lé díẹ̀ ní 50 náà.
Àwọn Ámẹ́ríńdíà wọ̀nyẹn mọ nǹkan fojú sùn, ni Gaspar de Carvajal, ọ̀kan lára àwọn arìnrìn-àjò akọni náà jẹ́wọ́ gbà. Ó sọ̀rọ̀ nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i gan-an, nítorí pé ọ̀kan lára àwọn ọfà àwọn Ámẹ́ríńdíà náà bà á ní egungun ìhà. Ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé náà kọ ọ̀rọ̀ pé: “Bí kì í bá ṣe aṣọ oyè mi tí ó nípọn ni, ìyẹn ì bá ti fòpin sí ìwàláàyè mi.”
‘Àwọn Obìnrin Tí Ń Jà Bí Àpapọ̀ Ọkùnrin Mẹ́wàá’
Carvajal ń ṣàlàyé lọ nípa ohun tí ń ti àwọn Ámẹ́ríndíà agbójúgbóyà náà lẹ́yìn. ‘A rí àwọn obìnrin tí ń jà níwájú àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun obìnrin. Àwọn obìnrin wọ̀nyí funfun, wọ́n sì ga, wọ́n di irun wọn gígùn, wọ́n sì lọ́ wọn mọ́ orí. Àwọn obìnrin náà sanra, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń fi ọrun àti ọfà ọwọ́ rẹ̀ jà bí àpapọ̀ ọkùnrin mẹ́wàá.’
Yálà ó jẹ́ òtítọ́ pé àwọn olùyẹ̀wòkiri náà rí àwọn jagunjagun obìnrin tàbí, bóyá gẹ́gẹ́ bí orísun ìròyìn kan ti sọ ọ́ pé, “ìrànǹrán tí ibà fà” ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀, a kò mọ̀. Àmọ́, ó kéré tán, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn kan ti sọ, nígbà tí Orellana àti Carvajal dé ojúkò odò ńlá náà, tí wọ́n sì wakọ̀ wọnú Òkun Àtìláńtíìkì, wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ti gán-ánní abala àwọn Amazon ti Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé náà, àwọn jagunjagun obìnrin oníjàgídí-jàgan tí a ṣàpèjúwe nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ Gíríìkì.a
Ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé Carvajal pa ìtàn àwọn ará America tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Amazon mọ́ fún ìran ọjọ́ ọ̀la nípa fífi í kún ìròyìn olùfojúrí tí ó kọ nípa ìrìn àjò akọni olóṣù mẹ́jọ tí Orellana rìn. Ọ̀gákọ̀ Orellana, ní tirẹ̀, tukọ̀ lọ sí Sípéènì, níbi tí ó ti sọ ìròyìn kíkún nípa ìrìn àjò sí ibi tí ó fi ayọ̀ ìṣàwárí pè ní Río de las Amazonas, tàbí Odò Amazon. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn olùṣẹ̀dá àwòrán ilẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ń kọ orúkọ tuntun kan sórí àṣẹ̀ṣẹ̀ṣe àwòrán ilẹ̀ Gúúsù America—Amazon. Nítorí náà, igbó Amazon di èyí tí àròsọ bò mọ́lẹ̀, àmọ́, nísinsìnyí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gidi ti ń pọ́n igbó náà lójú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà “Amazon” wá láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a, tí ó túmọ̀ sí “láìsí,” àti ma·zosʹ, tí ó túmọ̀ sí “ọmú.” Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu ti sọ, àwọn Amazon gé ọmú ọ̀tún, kí ó lè túbọ̀ rọrùn fún wọn láti lo ọrun àti ọfà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Ọwọ́ ẹ̀yìn lókè: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck