Ohun Àṣenajú ni Wọ́n Pè É
ARIWO ń sọ pùtù nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá náà. Ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn kóra jọ láti wo ọ̀kan lára àwọn ohun àfiṣèranwò amóríyá ti Róòmù ìgbàanì. Wọ́n fi àwọn àsíá, òdòdó rose, àti àwọn aṣọ ìkélé ọlọ́nà tí ó ní àwọ̀ mèremère ṣe àyíká ibi ìwòran náà lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn ìsun omi ń tú omi olóòórùn dídùn jáde, wọ́n sì fi òórùn dídùn kún inú afẹ́fẹ́. Àwọn ọlọ́rọ̀ ń mì lẹ̀ǹgbẹ̀ nínú aṣọ iyì wọn dídára jù lọ. Ẹ̀rín ń bọ́ láàárín ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ tí àwọn èrò náà ń sọ, àmọ́, ìhógèè àwọn èrò yí bo òtítọ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ mọ́lẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà, bíbú tí atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tubæ, bú gbẹ̀ẹ̀ pe àwọn ajàjàkú-akátá méjì kan jáde láti wà á kò. Ẹ̀mí àwọn èrò náà kó sókè bí àwọn olùdíje náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣá ara wọn níṣàákúṣàá. Ariwo àyẹ́sí kikankikan tí àwọn òǹwòran náà ń pa fẹ́rẹ̀ẹ́ máà jẹ́ kí a gbúròó idà tí ń kọlura náà. Lójijì, pẹ̀lú ìgbésẹ̀ yíyára kánkán, ọ̀kan lára àwọn méjì tí ń jà náà gbé èkejì rẹ̀ ṣubú. Kádàrá ajàjàkú-akátá tí ó ṣubú náà wá wà lọ́wọ́ àwọn òǹwòran báyìí. Bí wọ́n bá ń ju àwọn áńkáṣífì wọn, kò ní kú. Lápapọ̀, àwùjọ náà—tí ó ní àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdébìnrin nínú—pàṣẹ ìgbésẹ̀ ikú náà nípa gbígbé àtàǹpàkò wọn sókè. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n wọ́ òkú náà kúrò nílẹ̀ẹ́lẹ̀ ibi ìṣeré náà, wọ́n fi ṣọ́bìrì kó ilẹ̀ tí ẹ̀jẹ̀ rin náà, wọ́n sì da iyanrin tuntun sórí rẹ̀, àwọn èrò náà sì múra sílẹ̀ fún ìyókù ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà.
Lójú ọ̀pọ̀ àwọn tí ń gbé Róòmù ìgbàanì, ìyẹn jẹ́ ohun àṣenajú. Ìwé náà, Rome: The First Thousand Years, sọ pé: “Kódà, ẹni tí ó mú gbígbé ìgbésí ayé ìwà rere lógìírí jù lọ nígbà náà kò lòdì sí dídunnú lórí ìtàjẹ̀sílẹ̀ yí.” Eré ìdárayá ìjà àjàkú-akátá náà wulẹ̀ jẹ́ oríṣi eré àṣenajú kan tí kò bójú mu tí Róòmù pèsè nígbà náà. Wọ́n tún máa ń gbé ìjà ogun ojú omi gidi kalẹ̀ fún dídá àwọn òǹwòran tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ lára yá. Kódà, wọ́n máa ń ṣe ìfìyà-ikú-jẹni ní gbangba, níbi tí wọn óò ti so ọ̀daràn ti a dájọ́ ikú fún náà mọ́ òpó kan, tí ẹranko ẹhànnà kan, tí a ti febi pa, yóò sì fi jẹ.
Róòmù pèsè àwọn eré ìtàgé lóríṣiríṣi fún àwọn tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìtàjẹ̀sílẹ̀. Bí Ludwig Friedländer ṣe kọ ọ́ nínú ìwé náà, Roman Life and Manners Under the Early Empire, àwọn ibi eré ìtàgé ìfara-ṣàpẹẹrẹ—àwọn eré kéékèèké nípa ìgbésí ayé ojoojúmọ́—“panṣágà àti eré ìfẹ́ jẹ́ lájorí kókó ọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kún fún àsọgbà gbólóhùn ọ̀rọ̀ àsé, àwọn ọ̀rọ̀ adẹ́rìn-ín-pani rẹ̀ sì jẹ́ àlùfààṣá, tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe àyẹ́sí akóni-nírìíra, tí ó kún fún ọ̀rọ̀ àsé nínú, àti, lékè gbogbo rẹ̀, àwọn ijó ran-unràn-un sí orin tí a fi fèrè kọ.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ, “ẹ̀rí wà pé àwọn ènìyàn ń ṣe panṣágà gidi lórí ìtàgé níbi tí wọ́n ti ń ṣe eré ìfara-ṣàpẹẹrẹ náà lákòókò Ilẹ̀ Ọba Róòmù.” Pẹ̀lú ìdí rere, Friedländer pe eré ìfara-ṣàpẹẹrẹ náà ní “èyí tí ìwà pálapàla àti àlùfààṣá inú rẹ̀ burú jù lọ, ní ti gidi, lára àwọn eré ìtàgé,” ó sì fi kún un pé: “Àwọn ìran tí ó kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jù lọ ni àwọn ènìyàn ń yẹ́ sí jù lọ.”a
Lónìí ńkọ́? Ìfẹ́ tí ènìyàn ní nínú ohun àṣenajú ha ti yí pa dà bí? Gbé ẹ̀rí rẹ̀ yẹ̀ wò, bí a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìfìyà-ikú-jẹni kan ni a lè ṣe lórí ìtàgé láti fi ìjótìítọ́-gidi sínú eré ìtàgé kan tí a ń ṣe. Ìwé náà, The Civilization of Rome, sọ pé: “Ó wọ́ pọ̀ kí ọ̀daràn tí a ti dájọ́ ikú fún gba ipò olú eré ní ìparí eré tí ó jẹ́ eléwu.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck