“Wulẹ̀ La Ojú Rẹ Kí O sì Wò Ó”
KÍ NI àwọn ọmọ rẹ ń rí? Ṣé ogun ni? Ìwà ọ̀daràn ni? Ìbàyíkájẹ́ ni? Ipò òṣì ni? Àìsàn ni? Òtítọ́ ni pé àwọn ohun ti a ń rí nígbà gbogbo nìwọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, o ha ti kọ́ wọn pé kí wọ́n máa wò ré kọjá àwọn nǹkan wọ̀nyí sínú ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu tí a ṣèlérí rẹ̀ nínú Bíbélì bí? Àwọn òbí ọmọ ọdún mẹ́sàn-án tí ń jẹ́ Joel Pierson ti ṣe èyí. Kí ni ìyọrísí rẹ̀?
Ṣàyẹ̀wò ohun tí Joel kọ lórí kókó náà, “Wulẹ̀ La Ojú Rẹ Kí O sì Wò Ó.” Àkọlé yìí ni wọ́n fún àwọn èwe ní àgbègbè ilé ẹ̀kọ́ kan ní Virginia, U.S.A., pé kí wọ́n kọ àròkọ lé lórí. Kíyè sí bí àròkọ tí Joel kọ, tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé agbéròyìnjáde náà, The Central Virginian, August 22, 1996, ṣe fi hàn pé ó gbé ìrètí rẹ̀ karí ohun tí ó ti kọ́ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé:
“Wulẹ̀ la ojú rẹ kí o sì wò ó, gbogbo ẹwà tí ó yẹ kí ó wà.
“Kì yóò ha jẹ́ àgbàyanu pé kí a jí lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, kí a sì gbọ́ pé kò sí ìbàyíkájẹ́ mọ́ bí? Kàkà kí a máa gbọ́ ìròyìn nípa ìpànìyàn àti ìwà ọ̀daràn, ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní àlàáfíà àti ayọ̀ nínú.
“Àwọn aládùúgbò ń jùmọ̀ ṣe iṣẹ́ pọ̀ láti bá ọ̀rẹ́ kan kọ́ ilé rẹ̀. A rí àwọn mìíràn tí ń gbin irúgbìn nínú ọgbà ọ̀gbìn nítòsí. Èyí nìkan kọ́, àmọ́ àwọn ète ìsúnniṣe wọn ń gbéni ró. Olúkúlùkù ń pawọ́ pọ̀ láti ran èkíní-kejì lọ́wọ́. Kì yóò sí àwọn tálákà mọ́, oúnjẹ yóò sì kárí lọ́pọ̀ yanturu. Ìṣọ̀kan àti àlàáfíà yóò wà kárí ayé. Kì yóò sí ẹni tí ebi ń pa tàbí ẹni tí ń ṣàìsàn mọ́. Àwọn àyíká rírẹwà ló wà fún ẹni gbogbo láti wò, sì wò ó, ọmọdé kan ń gun ẹkùn kiri! Ẹkùn nìkan kọ́, ṣùgbọ́n gbogbo ẹranko ló wà lálàáfíà pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn.
“Èmi yóò fẹ́ láti gbé níbì kan tí ó rí báyìí. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti bá mi gbé ibẹ̀ bí?”
Ọlọ́run ha ṣèlérí irú àwọn ìbùkún tí Joel ọ̀dọ́ ṣàpèjúwe níhìn-ín ní tòótọ́ bí? Dájúdájú, ó ṣe bẹ́ẹ̀! Jọ̀wọ́ ṣí Bíbélì rẹ, kí o sì kà nípa irú àwọn ìlérí bẹ́ẹ̀ tí a rí nínú Orin Dáfídì 46:8, 9; 67:6; 72:16; Aísáyà 2:3, 4; 11:6-9; 33:24; 65:17-25; Mátíù 6:9, 10; Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.