Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìjíhìn Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Àwa Ni A Óò Jíhìn fún Ohun Tí A Bá Ṣe?” (September 22, 1996) Mo ti rí i pé àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí gbéṣẹ́ gan-an fún ìnílógberí ìjíròrò dáradára pẹ̀lú àwọn amòfin, àwọn aṣojú ìbánigbófò, àwọn ọ̀gá iṣẹ́, àwọn olùṣèwéjáde, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀, àti àwọn mìíràn tí mo ti bá sọ̀rọ̀ ní àgbègbè ìṣòwò ìlú wa. Mo fi àpilẹ̀kọ náà, “Kì í Ṣe Ẹ̀bi Mi,” han òṣìṣẹ́ kan ní ọ́fíìsì ìsanwó ìtanràn fún rírúfin ibi ìgbọ́kọ̀sí nílùú ńlá. Ó gba ìwé ìròyìn náà lọ́wọ́ mi, ó sì wí pé, “àwọn ènìyàn díẹ̀ kéréje ló ṣì ń gbà pé àwọn ṣàṣìṣe.” Ó wí pé, òun fẹ́ kí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ kà á.
B. S., United States
Àkókò Ìṣefàájì Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àkókò Ìṣefàájì?” (September 22, 1996) Ọmọ ọdún 15 ni mí, àwọn èwe sì pọ̀ ní ìjọ wa. A sábà máa ń ṣe nǹkan pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, a lè lọ wàásù ní òwúrọ̀, tí a óò sì lọ lúwẹ̀ẹ́ ní ìrọ̀lẹ́. Ìmóríyá gbáà ló jẹ́! Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn mìíràn láti inú ìjọ wa máa ń dara pọ̀ mọ́ wa. Ó sì ń tu àwọn òbí wa nínú láti mọ̀ pé a ní irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ó yẹ.
I. W., Germany
Àrùn Fòníkúfọ̀larùn Mo ti ka àpilẹ̀kọ náà, “Àrùn Arunmọléegun—Ìmọ̀ Ni Ààbò Dídára Jù Lọ” (October 8, 1996), lákàtúnkà. Ó ṣàpèjúwe ipò mi! Ó ti pé ọdún 18 báyìí tí mo ti ń mú àrùn yí mọ́ra. Bí mo ti ń kà á ni omijé ń bọ́ lójú mi. Inú mi dùn láti rí i pé ẹ ronú nípa àwọn tí wọ́n ní àìlera yìí.
R. S., Ítálì
Mo ní àrùn fòníkúfọ̀larùn. N kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ènìyàn púpọ̀ ní in pẹ̀lú. Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ara fi máa ń ro mí àti bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti máa mu ohun olómi púpọ̀ gan-an. Mọ́mì mi fún àwọn olùkọ́ mi ní àwọn ẹ̀dá mélòó kan kí wọ́n baà lè lóye àrùn mi.
A. H., United States
Àrùn fòníkúfọ̀larùn pa àbúrò mi ọkùnrin. Ní Nàìjíríà, 60,000 ènìyàn ló máa ń pa lọ́dọọdún. Nítorí náà, àpilẹ̀kọ náà sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro gidi kan. Ó yẹ kí olúkúlùkù ìdílé ní Nàìjíríà ka àpilẹ̀kọ yìí. Ó kún fún ẹ̀kọ́, wọ́n sì sọ ọ́ ní ọ̀tun.
F. A., Nàìjíríà
N kò lè ṣàìsọ ohun tí mo rò nípa àpilẹ̀kọ náà lórí àrùn fòníkúfọ̀larùn. Ọdún 26 nìyí tí mo ti ń mú àrùn náà mọ́ra láìní ìsọfúnni yìí. Ẹ ṣeun gan-an fún èyí.
D. C., Zambia
Ìfẹ́ Tí Ń Soni Pọ̀ Mo fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin ará ọ̀wọ́n, fún títẹ àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: Ìfẹ́ Tí Ń Soni Pọ̀.” (October 8, 1996) Mo ti kojú ọ̀pọ̀ ìdánwò ìgbàgbọ́ ní àwọn ọdún tó ti kọjá, títí kan ikú àwọn òbí mi tó ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Àmọ́, ìdánwò tí ó tí ì burú jù lọ wá láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan láàárín ìjọ. Àpilẹ̀kọ yìí ti fún mi lókun àti ìtùnú, bí mo ti rí i pé Jèhófà mọ̀, ó sì lóye omijé mi àti ìpalára àti ìrora ọkàn tí mo ní. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá jìyà irú ìpalára tí ó jọra. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà yóò wo àwọn ọgbẹ́ mi sàn.
S. B., Kánádà
Nínú ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí, ó rọrùn láti pàdánù àfiyèsí tí a fún àwọn ohun tẹ̀mí. Àpilẹ̀kọ náà fún mi níṣìírí gidigidi, ó sì sún mi gbégbèésẹ̀. Láìpẹ́ yìí, hílàhílo ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ti kó másùnmáwo bá mi. Àpilẹ̀kọ yìí ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì ìjẹ́pàtàkì fífọkàntẹ ìfẹ́ Jésù, dípò ti èrò ìmọ̀lára aláìpé tiwa.
A. M., United States
Ìsoríkọ́ tí àìwàdéédéé kẹ́míkà kan fà ń yọ mí lẹ́nu. Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ míràn ní kíkojú ìsoríkọ́ mi.
B. U., United States