ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/22 ojú ìwé 3
  • Ìgbà Kan Tí Ìwà Ọ̀daràn Kò Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Kan Tí Ìwà Ọ̀daràn Kò Sí
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibo Ni Ìwà Ọ̀daràn Ti Pilẹ̀ Ṣẹ̀?
  • Ogun Àjàpàdánù Tí A Ń Bá Ìwà Ọ̀daràn Jà
    Jí!—1998
  • Jíjìjàdù Láti Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn
    Jí!—1996
  • Nígbẹ̀yìngbẹ́yín—Ìjọba Kan Tí Yóò Fòpin Sí Ìwà Ọ̀daràn
    Jí!—1996
  • Orílẹ̀-èdè Wo Ni Kò Ti Sí Ìwà Ọ̀daràn?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/22 ojú ìwé 3

Ìgbà Kan Tí Ìwà Ọ̀daràn Kò Sí

ÌWỌ ha lè finú wòye ayé kan tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn? Bóyá o kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ bí o bá ti ka àwọn ìròyìn bí èyí tí ó wà nínú ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany náà, Süddeutsche Zeitung, tí ó sọ pé: “Àwọn ògbóǹkangí onímọ̀ òfin nípa ìwà ọ̀daràn ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun ti bí ìwà ọ̀daràn ti pọ̀ tó. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ jẹ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ ibi, ìfojúsọ́nà wọn fún àtúnṣe sì jẹ́ ti àjálù tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe lọ́dọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Yúróòpù ní 1995, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ló ń dààmú nípa híhu ìwà ọ̀daràn sí wọn. Ní Germany, Netherlands, Poland, Rọ́ṣíà, àti United Kingdom, ìwà ọ̀daràn ló jẹ́ àkọ́kọ́ lára àwọn ohun tí àwọn ènìyàn bẹ̀rù jù lọ. Ìbẹ̀rù ìwà ọ̀daràn wà ní ipò kejì ní Denmark, Finland, àti Switzerland, òun ló sì wà ní ipò kẹta ní ilẹ̀ Faransé, Gíríìsì, àti Ítálì. Lára àwọn orílẹ̀-èdè 12 tí a ti ṣèwádìí náà, ilẹ̀ Sípéènì nìkan ni kò ní ìwà ọ̀daràn lára ohun mẹ́ta àkọ́kọ́ tí ń ba àwọn ènìyàn lẹ́rù.

Láàárín ọdún méje tí ó kọjá, ìwà ọ̀daràn ti pọ̀ sí i lọ́nà gbígbàfiyèsí ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Ní àwọn mélòó kan lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, ó ti fi nǹkan bí ìpín 50 sí ìpín 100 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i, nígbà tí ó jẹ́ pé ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ó tilẹ̀ ti tó nǹkan bí ìpín 193 sí ìpín 401 lórí ọgọ́rùn-ún!

Síbẹ̀, nígbà kan rí, ayé kan wà tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn. Ìgbà wo nìyẹn, báwo sì ni àwọn ènìyàn ṣe ba ayé yẹn jẹ́?

Ibo Ni Ìwà Ọ̀daràn Ti Pilẹ̀ Ṣẹ̀?

Ìwà ọ̀daràn, tí a túmọ̀ bíi “rírú òfin lọ́nà bíburújáì,” pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ilẹ̀ ọba ẹ̀mí. A kò dá ìtẹ̀sí oníwà ọ̀daràn mọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ náà, Ádámù àti Éfà, àwọn gan-an sì kọ́ ni wọ́n ṣokùnfà mímú ìwà ọ̀daràn wọ inú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Ẹ̀dá ẹ̀mí pípé kan lára àwọn ọmọkùnrin Ọlọ́run fàyè gba àwọn èrò òdì láti ta gbòǹgbò nínú ọkàn rẹ̀, èyí tí ó ṣamọ̀nà sí ìwà ọ̀daràn nígbà tí kò mú un kúrò lọ́kàn. Ẹni yẹn ni ó ṣokùnfà bíba ayé àkọ́kọ́ níbi tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn jẹ́. Nípa rírú òfin Ọlọ́run, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀daràn, a sì pè é ní Sátánì Èṣù nínú Bíbélì.—Jákọ́bù 1:13-15; Ìṣípayá 12:9.

Níwọ̀n bí ó ti ń tọpa ọ̀nà ìṣòdìsí Ọlọ́run nínú ọ̀run tí a kò lè fojú rí, Sátánì ti pinnu láti tàtaré àwọn ọ̀nà oníwà ọ̀daràn rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀dá ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Àkọsílẹ̀ Bíbélì tí ó sọ nípa bí Èṣù ṣe ṣe èyí kúrú, ó sì rọrùn, àmọ́ òtítọ́ ni. (Jẹ́nẹ́sísì orí 2 sí 4) Ádámù àti Éfà, tí ọ̀daràn ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, tí agbára rẹ̀ ju ti ènìyàn lọ yìí mú ṣìnà kọ̀ láti ṣègbọràn sí àwọn ìlànà Ọlọ́run. Wọ́n wá di ọ̀daràn nípa ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Nígbà tó yá, wọ́n fi ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ká ṣìọ̀ nígbà tí ọmọkùnrin àkọ́bí wọn, Kéènì, fipá gba ohun tí ó ṣeyebíye jù lọ fún àbúrò rẹ̀, Ébẹ́lì, ìwàláàyè gangan!

Nípa bẹ́ẹ̀, lára àwọn ènìyàn mẹ́rin tí wọ́n kọ́kọ́ gbé orí ilẹ̀ ayé, mẹ́ta di ọ̀daràn. Ádámù, Éfà, àti Kéènì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní wọn láti gbé ayé kan tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn. Èé ṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé irú ayé bẹ́ẹ̀ ti sún mọ́lé nísinsìnyí, lẹ́yìn gbogbo àkókò tó ti kọjá lọ yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́