ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/22 ojú ìwé 7-9
  • Ayé Kan Tí Kò Ti Ní Sí Ìwà Ọ̀daràn Kò Ní Pẹ́ Dé!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Kan Tí Kò Ti Ní Sí Ìwà Ọ̀daràn Kò Ní Pẹ́ Dé!
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Tí A Nílò
  • Bí Ayé Tuntun Kan Yóò Ṣe Dé
  • Ayé Tuntun Ọlọ́run Kò Ní Pẹ́ Dé
  • Ǹjẹ́ Ohun Kan Wà Tó Lè Fòpin Sí Ìwà Ìkà Bíburú jáì?
    Jí!—2003
  • Ibo Lọ̀rọ̀ Ayé Yìí Ń Lọ?
    Jí!—2007
  • Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ayé Yìí Yóò Ha Là á Já Bí?
    Ayé Yìí Yóò Ha Là Á Já Bí?
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/22 ojú ìwé 7-9

Ayé Kan Tí Kò Ti Ní Sí Ìwà Ọ̀daràn Kò Ní Pẹ́ Dé!

NÍGBÀ tí a bá wo ipò ayé òde òní, ó ṣe kedere pé ó ṣòro gidigidi láti yẹra fún dídi ẹni tí a sún ṣe ohun búburú. Ní gidi, gbogbo wa ni a bí ní aláìpé, tó ní ìtẹ̀sí láti ṣe àwọn ohun búburú. (1 Àwọn Ọba 8:46; Jóòbù 14:4; Sáàmù 51:5) Níwọ̀n bí a sì ti lé Sátánì Èṣù kúrò ní ọ̀run, ó ń sapá púpọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ láti dá wàhálà sílẹ̀.—Ìṣípayá 12:7-12.

Àwọn ìyọrísí rẹ̀ ti burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí a fi 4,000 ọmọdé ṣe ní Scotland fi hàn pé ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn tí ó wà láàárín ọmọ ọdún 11 sí 15 ti hùwà ọ̀daràn. Ìwádìí kan jákèjádò Britain fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdámẹ́ta gbogbo ọ̀dọ́langba tó wà níbẹ̀ ni ṣíṣọwọ́fẹ́rẹ́ nílé ìtajà kò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn. Àwọn tó sì lé ní ìdajì lára wọn ló jẹ́wọ́ pé bí a bá fún àwọn ní ṣẹ́ńjì tó pọ̀ ju ohun tó yẹ kí àwọn gbà lọ, àwọn kò ní dá a pa dà.

Ìwé tí a ṣe lédè Ítálì náà, Lʹoccasione e lʹuomo ladro (Àǹfààní àti Olè), fúnni ní òye ìdí tí àwọn ènìyàn fi ń jalè. Ìwé náà sọ pé àwọn olè ní “ìwọ̀n ìkóra-ẹni-níjàánu tó kéré,” wọn “kò” sì “lè sún ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn síwájú.” Ìwé náà fi kún un pé, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olè kì í ṣe akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n wulẹ̀ jẹ́ “ajìfà tó wulẹ̀ ń kófà àwọn ipò tó yí wọn ká.”

Ó wọni lọ́kàn pé ìwé náà tún ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe “ń yẹra fún rírú òfin.” Ó parí ọ̀rọ̀ sí pé, kì í ṣe pé nítorí pé wọ́n “bẹ̀rù ìbáwí tí ó bófin mu ni, àmọ́ nítorí pé wọ́n ní àwọn ìlànà ìwà rere tí ó ká wọn lọ́wọ́ kò láti má ṣe bẹ́ẹ̀.” Ibo ni àwọn ènìyàn ti lè kọ́ irú àwọn ìlànà ìwà rere bẹ́ẹ̀?

Ẹ̀kọ́ Tí A Nílò

Ó dára, ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí a ń kọ́ láti ọ̀pọ̀ orísun ìfìsọfúnni-ráńṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ìsọfúnni tí àwọn sinimá àti tẹlifíṣọ̀n ń gbé wá ní gbogbogbòò ni pé ìwà ipá, àgbèrè, àti ìwà ìfìyàjẹni ṣètẹ́wọ́gbà. Kò yani lẹ́nu, nígbà náà, pé àwọn ènìyàn ní ìwọ̀n ìkóra-ẹni-níjàánu tí kò tó nǹkan. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Bíbélì fi ọgbọ́n kọ́ wa pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.”—Òwe 16:32.

Ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò ìgbékèéyíde òde òní, kò yẹ kí ó yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni “kò lè fawọ́ ìtẹ́lọ́rùn sẹ́yìn.” Léraléra ni àwọn ènìyàn ń gbọ́ pé: “Rà á nísinsìnyí kí o sanwó tó bá yá.” “Ṣe ara rẹ lóore.” “O lẹ́tọ̀ọ́ sí ohun tí ó dára jù lọ.” “Ṣàníyàn nípa ire ara rẹ.” Títẹ́ra-ẹni-lọ́rùn ni a fi hàn bí ohun tí ó dára, tí ó sì bẹ́tọ̀ọ́ mu. Àmọ́ irú èrò ìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ lòdì sí ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa pé “kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílípì 2:4.

Ìwọ kì yóò ha gbà pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn tí wọ́n jẹ́ alábòsí ni wọ́n jẹ́ ajìfà? Ó ṣeni láàánú pé, ńṣe ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń fẹ́ láti kófà ń pọ̀ sí i. Wọn kì í béèrè bóyá irú ìwà kan tọ́ ní ti ìwà rere. Ohun kan ṣoṣo tó kàn wọ́n ni pé, ‘Ṣé mo lè mú un jẹ?’

Kí ni a nílò? Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ níṣàájú, a nílò àwọn ìlànà ìwà rere. Ìwọ̀nyí kò ní jẹ́ kí àwọn ènìyàn máa hùwà ọ̀daràn, kò ní jẹ́ kí wọ́n má ka ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè sí, kò ní jẹ́ kí wọ́n ba ìjẹ́mímọ́ ìgbéyàwó jẹ́, kò ní jẹ́ kí wọ́n ré àwọn ààlà ìwà yíyẹ kọjá, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn lójú. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àwọn tí wọn kò kẹ́kọ̀ọ́ irú àwọn ìlànà wọ̀nyẹn, “ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfésù 4:19) Ìwà ọ̀daràn tí irú àwọn ènìyàn aláìwà-bí-Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ń hù ló ń dí wa lọ́wọ́ láti gbádùn ayé kan tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn.

Bí Ayé Tuntun Kan Yóò Ṣe Dé

Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbìyànjú gan-an láti jẹ́ aláìlábòsí, láti fi ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò hàn fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, àti láti má ṣe hu àwọn ìwà tí kò bófin mu. Àmọ́ yóò jẹ́ ìwà àìnírònú láti ronú pé gbogbo ènìyàn tó wà láyé ni yóò sapá lọ́nà yìí. Ọ̀pọ̀ kò ní ṣe bẹ́ẹ̀, gan-an bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n ń gbé ní ọjọ́ Nóà kò ti fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Nínú ayé tí ó kún fún ìwà ipá yẹn, Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ni kò hùwà aláìwà-bí-Ọlọ́run, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ojú rere Ọlọ́run. Nípa fífi Ìkún Omi kárí ayé mú àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run kúrò, Ẹlẹ́dàá wa mú ayé kan tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn fún ìgbà díẹ̀ wá.

Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Ìkún Omi àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run ju ìtàn kan tí ó dùn mọ́ni lásán lọ. Jésù Kristi ṣàlàyé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí pẹ̀lú ní àwọn ọjọ́ Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 17:26; 2 Pétérù 2:5; 3:5-7) Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pa ayé oníwà ipá yẹn run ṣáájú Ìkún Omi, bẹ́ẹ̀ ni yóò pa ayé tí ó kún fún ìwà ọ̀daràn yìí run pẹ̀lú.

Òkodoro òtítọ́ tó tẹ̀ lé e yìí wá láti orísun kan tó ṣeé fọkàn tán, bí Jòhánù tí ó jẹ́ àpọ́sítélì ààyò olùfẹ́ Jésù náà ṣe sọ ọ́ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Òpin ayé yìí yóò ṣínà fún ayé tuntun kan nínú èyí tí, Bíbélì sọ pé, “[Ọlọ́run] yóò . . . máa bá [aráyé] gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Nígbà tí Bíbélì tún ń ṣàpèjúwe bí ayé tuntun náà yóò ṣe dé, ó sọ pé: “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” (Òwe 2:22) Pẹ̀lú kìkì àwọn adúróṣinṣin tí yóò ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí yóò ní ìmúṣẹ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àwọn ẹranko pàápàá kì yóò pani lára mọ́. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n. . . . Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:6-9; 65:17; 2 Pétérù 3:13.

Ayé Tuntun Ọlọ́run Kò Ní Pẹ́ Dé

Ìhìn rere náà ni pé irú àwọn ipò alálàáfíà bẹ́ẹ̀ kò ní pẹ́ dé jákèjádò ayé. Báwo ló ṣe dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀? Nítorí ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ ní kété ṣáájú òpin ayé. Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” Ó fi kún un pé: “Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”—Mátíù 24:7, 12.

Àpọ́sítélì Jésù kan pẹ̀lú sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn [ayé yìí], àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-5) Dájúdájú, a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé yìí! Nítorí náà, láìpẹ́, a óò fi ayé tuntun òdodo ti Ọlọ́run rọ́pò rẹ̀!

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti fi dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lójú pé ayé kan tí kò ti sí ìwà ọ̀daràn lè ṣeé ṣe, wọ́n sì ń dáhùn sí ìkésíni náà láti di ẹni tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ọ̀nà Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run. (Aísáyà 2:3) Ìwọ yóò ha fẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ wọn bí? Ìwọ ha ti múra tán láti sapá láti jèrè ìwàláàyè nínú ayé tuntun tí kò ti ní sí ìwà ọ̀daràn?

Jésù fi ohun àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ kòṣeémánìí hàn. Ó ṣàlàyé pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” Nípa bẹ́ẹ̀, ire ayérayé rẹ sinmi lórí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífi ohun tí o kọ ṣèwà hù.—Jòhánù 17:3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Bíbélì ṣàpèjúwe ayé tuntun kan tí kò ti ní sí ìwà ọ̀daràn, ó sì sọ bí a ṣe lè gbádùn rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́