Ojú Ìwòye Bíbélì
Báwo Ni Ọdún 2000 Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ni kò so ìjẹ́pàtàkì ti ìsìn mọ́ ohun tí àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn yóò dà ní ọdún 2000 páàpáà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Júù, àwọn Mùsùlùmí, àti àwọn Híńdù ní kàlẹ́ńdà ìsìn tiwọn tí kò dọ́gba pẹ̀lú àwọn ti Ìwọ̀ Oòrùn. Àwọn ará China ń tẹ̀ lé kàlẹ́ńdà àfòṣùpákà ní ti àwọn déètì tí ó kan ìsìn àti àṣà ìbílẹ̀. Nítorí náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lónìí, bóyá ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ayé, ni kò so ìjẹ́pàtàkì kan mọ́ ọdún 2000.a
Bí ó ti wù kí ó rí, ní pàtàkì ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fi ìfẹ́ ìtọpinpin retí ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún tí ń bọ̀ tí ó ti sún mọ́lé bí kàlẹ́ńdà ti Póòpù Gregory ṣe fi hàn. Ní ti àwọn kan, ó ju ìfẹ́ ìtọpinpin lásán lọ. Wọ́n wo ọdún 2000 bí èyí tí ń mú sànmánì tuntun kan wọlé bọ̀, bí àkókò ìyípadà pàtàkì kan. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́ so ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pọ̀ mọ́ ọdún 2000. Àwọn kan ń retí ìfarahàn àwọn ohun tẹ̀mí lọ́nà púpọ̀ jọjọ. Àwọn mìíràn ń bẹ̀rù àgbákò kan—òpin ayé. Bíbélì ha pèsè ìpìlẹ̀ èyíkéyìí nípa àwọn ìfojúsọ́nà wọ̀nyí bí?
Jèhófà, Olùṣètò-Àkókò
A ṣàpèjúwe Ọlọ́run ti Bíbélì bí “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé.” (Dáníẹ́lì 7:9) Ó ń ṣàkóso àkókò lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí, bí ó ti hàn kedere nínú bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́, láti orí bí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ṣe ń yípo dé orí ìṣíkiri àwọn èérún tí ó kéré ju átọ̀mù lọ. Ó ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò tirẹ̀ tí ó rọ̀ mọ́ lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí. Bíbélì sọ pé: “Ó . . . gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn. (Ìṣe 17:26) Olùṣàbójútó-àkókò tí ó péye ni Jèhófà.
Bí ó ti yẹ, Bíbélì fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ní àfiyèsí pàtó. Ó pèsè àkọsílẹ̀ tí ó so mọ́ra, tí ń jẹ́ kí a lè ka ọjọ́ padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn lọ́nà àfètòṣe. Irú ìṣirò bẹ́ẹ̀ kan tọ́ka sí ọdún 4026 ṣááju Sànmánì Tiwa gẹ́gẹ́ bí ọdún tí Ọlọ́run dá Ádámù. Nǹkan bí 2,000 ọdún lẹ́yìn náà ni wọ́n bí Ábúráhámù. Ó ṣẹlẹ̀ pé 2,000 ọdún mìíràn ti kọjá kí wọ́n tó bí Jésù.
Àwọn kan tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ Bíbélì ti ṣẹ̀dá àwọn ìṣirò àdábọwọ́ kan tí ó tọ́ka sí àwọn déètì kan pàtó lọ́jọ́ iwájú. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan lo àlàfo nǹkan bí 2,000 ọdún tí ó tẹ̀ léra, tí ó wà láàárín Ádámù, Ábúráhámù, àti Jésù bí ìpìlẹ̀ láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu kan tí yóò ṣẹ̀ ní òpin sáà 2,000 ọdún láti ìgbà tí wọ́n ti bí Jésù. Èyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan nínú àwọn ìlànà ìṣèṣirò àkókò bí mélòó kan tí a rò pé a gbé karí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì.
Òtítọ́ ni pé Bíbélì sọ nípa àkókò tí Jèhófà Ọlọ́run yóò dá sí àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn nípa mímú ìwà búburú kúrò kí ó sì mú ayé tuntun kan wá. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ nípa “àkókò òpin,” “ìparí ètò àwọn nǹkan,” “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àti “ọjọ́ Jèhófà.” (Dáníẹ́lì 8:17; Mátíù 24:3; 2 Tímótì 3:1; 2 Pétérù 3:12) Bí ó ti wù kí ó rí, “òpin” tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì kò ní í ṣe pẹ̀lú ọdún 2000 lọ́nàkọnà. Nínú Ìwé Mímọ́, kò sí ohunkóhun tí ó so ìjẹ́pàtàkì kan mọ́ òpin ẹgbẹ̀rúndún kejì gẹ́gẹ́ bí kàlẹ́ńdà ti Póòpù Gregory ṣe gbéṣirò lé e.
“Nígbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?”
Àwọn àpọ́sítélì Jésù fi ọkàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn nínú ìṣètò àkókò Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bi Jésù léèrè pé: “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ní irú ìyánhànhàn kan náà nípa ọjọ́ iwájú. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti ní ọkàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ó ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ àti àkókò tí wọn yóò ní ìmúṣẹ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà, kí a sì bọ̀wọ̀ fún ipò tí Ọlọ́run mú lórí ọ̀ràn náà.
Jèhófà ti fi èrò rẹ̀ hàn lórí ọ̀ràn yìí, ó sì ti pèsè ìdáhùn tààràtà nípa rẹ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. Nígbà tí ó kù fẹ́ẹ́rẹ́ kí Jésù gòkè re ọ̀run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa àkókò tí àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò ṣẹ. Jésù dáhùn pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 1:7) Jésù ti wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.”—Mátíù 24:36.
Ní kedere, “láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò,” ní pàtàkì nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lọ́jọ́ iwájú, kò sí lábẹ́ àṣẹ ẹ̀dá ènìyàn. Ọlọ́run ti yàn láti má ṣe fi irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ hàn wá. (Mátíù 24:22-44) A ha lè ní ipa kankan lórí ète Ọlọ́run nípa pípinnu “ọjọ́ àti wákàtí yẹn” fúnra wa, lòdì sí ìfẹ́ rẹ̀ bí? Ó dájú pé èyí kò lè ṣeé ṣe. (Númérì 23:19; Róòmù 11:33, 34) Bíbélì sọ pé: “Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ète Jèhófà yóò dúró.” (Sáàmù 33:11) Níwọ̀n bí òun ti jẹ́ Ọlọ́run alágbára gbogbo, gbogbo ìgbà ni ó máa ń ṣàṣeyọrí.—Aísáyà 55:8-11.
Láìka ti agbára Ọlọ́run láti fi ‘mímọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò . . . sábẹ́ òun fúnra rẹ̀’ sí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì fẹ́ láti méfò. Àwọn kan sọ ara wọn di wòlíì asàsọtẹ́lẹ̀ ìparun. Nítorí èyí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fún àwọn ará Tẹsalóníkà ní ìtọ́ni pàtó nípa ewu tí ó wà nínú títẹ́tísí àwọn tí wọ́n ń méfò nípa déètì. Ó kọ̀wé pé: “Àwa béèrè lọ́wọ́ yín kí ẹ má ṣe tètè mì kúrò nínú ìmọnúúrò yín tàbí kí a ru yín sókè yálà nípasẹ̀ àgbéjáde onímìísí tàbí nípasẹ̀ ìhìn iṣẹ́ àfẹnusọ tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà kan bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ wa, tí ń wí pé ọjọ́ Jèhófà ti dé. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan sún yín dẹ́ṣẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí.”—2 Tẹsalóníkà 2:1-3.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ pé àwọn ète Ọlọ́run nípa ọjọ́ iwájú yóò ní ìmúṣẹ dájúdájú ní àkókò tí ó ti pinnu tẹ́lẹ̀, ní ọjọ́ àti wákàtí tí ó ti pinnu tẹ́lẹ̀ gan-an. (Hábákúkù 2:3; 2 Pétérù 3:9, 10) A sì gbà gbọ́ pé àwọn ohun wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ láìjìnnà lọ́jọ́ iwájú. (2 Tímótì 3:1-5) Bí ó ti wù kí ó rí, a kò méfò nípa àwọn àbá èrò orí tí ń pọ̀ sí i lónìí, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ṣètìlẹ́yìn fún wọn.b Ní tòótọ́, ọdún 2000, tàbí ọdún 2001, tàbí ààlà àkókò èyíkéyìí tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀ kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìṣètò àkókò ti Jèhófà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí a bá fi ọgbọ́n wò ó, ìgbà tí a pè ní ẹgbẹ̀rúndún kẹta náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní January 1, 2001. Ẹgbẹ̀rúndún àkọ́kọ́ kò bẹ̀rẹ̀ ní ọdún oódo àmọ́, ní ọdún 1. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ará ìlú so ọ̀rọ̀ náà “ẹgbẹ̀rúndún kẹta” mọ́ ọdún 2000. Àpilẹ̀kọ yìí dá lórí ìfojúsọ́nà wíwọ́pọ̀ nípa ọdún 2000.
b Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́, September 1, 1997, ojú ìwé 21 àti 22, sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń hára gàgà láti mọ ìgbà ti ọjọ́ Jèhófà yóò dé. Nínú ìháragàgà wọn, wọ́n ti gbìdánwò nígbà míràn láti fojú díwọ̀n ìgbà ti yóò dé. Ṣùgbọ́n nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ti kùnà, bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí ti ṣe, láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọ̀gá wọn pé a “kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.” (Máàkù 13:32, 33) Àwọn olùyọṣùtì ti fi àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ṣẹlẹ́yà nítorí tí wọ́n ń retí ohun tí àkókò rẹ̀ kò tí ì tó. (2 Pétérù 3:3, 4) Síbẹ̀síbẹ̀, Pétérù mú un dáni lójú pé, ọjọ́ Jèhófà yóò dé, ní àkókò tí Òún ṣètò pé yóò dé.”