“Ìfẹ́ Kì Í Kùnà Láé”—Ìwọ Ńkọ́?
KÍ NI ìfẹ́? Jákèjádò ayé ni a ti rí àwọn òwe tí ń fi ìjẹ́pàtàkì ìníyelórí ìfẹ́ tòótọ́ hàn. Òwe Zulu kan sọ pé, “Ìfẹ́ kì í mú igun koríko tí ó bá ṣubú lé.” Ní Philippines, àwọn ènìyàn ń sọ pé, “Ìfẹ́ ni iyọ̀ ìgbésí ayé.” Òwe ilẹ̀ Lẹ́bánónì kan sọ pé, “Ìfẹ́ máa ń gbójú fo àbùkù, àmọ́ ìkórìíra máa ń fẹ àbùkù lójú.” Bákan náà ni òwe ilẹ̀ Ireland kan sọ pé, “Ìfẹ́ ń bo àìbójúmu mọ́lẹ̀.” Àwọn ará Wales sọ pé, “Ìfẹ́ lágbára ju òmìrán lọ.” Àwọn ará Norway sọ pé, “Ohun tí a nífẹ̀ẹ́ sí sábà máa ń jojú ní gbèsè.” Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan lè sọ pé, “Ìfẹ́ eléépìnnì tẹ̀wọ̀n tó òfin pọ́n-ùn kan.” Ní ilẹ̀ Sípéènì, wọ́n máa ń pa òwe kan pé, “Ìfẹ́ tòótọ́ ń báni kalẹ́.”
Láìsí àní-àní, àwọn ènìyàn mọrírì ìfẹ́ tòótọ́ níbi yòó wù kí a lọ. Ìfẹ́ tí ó ṣe pàtàkì ní gidi nínú ìgbésí ayé ni èyí tí òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Pọ́ọ̀lù, ṣàpèjúwe báyìí pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:4-8.
Òtítọ́ ni, “ìfẹ́ kì í kùnà láé.” Ìfẹ́ a máa woni sàn. Ìfẹ́ a máa múni ṣọ̀kan. Kì í ṣe lọ́rọ̀ ẹnu nìkan ni a fi ń fi ìfẹ́ hàn àmọ́ ní ìṣe aláìmọtara-ẹni-nìkan. Ìfẹ́ ní ìsúnniṣe tí kò ní màgòmágó nínú. Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé: “Bí mo bá sì yọ̀ǹda gbogbo nǹkan ìní mi láti fi bọ́ àwọn ẹlòmíràn, tí mo sì fi ara mi léni lọ́wọ́, kí èmi bàa lè ṣògo, ṣùgbọ́n tí èmi kò ní ìfẹ́, èmi kò ní èrè rárá.” Bí a bá ṣe àwọn ìrúbọ tàbí tí a fún àwọn ènìyàn ní ẹ̀bùn kìkì nítorí kí àwọn ẹlòmíràn baà lè rí wa, nígbà náà òfo ló já sí ní ojú Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 13:3.
Jésù sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Nígbà tí o bá ń lọ fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni, má ṣe fun kàkàkí níwájú rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn alágàbàgebè ti ń ṣe . . . kí àwọn ènìyàn lè yìn wọ́n lógo. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n ìwọ, nígbà tí o bá ń fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe.” Òtítọ́ ni, ìfẹ́ kì í yangàn tàbí kí ó fọ́nnu.—Mátíù 6:2, 3.
Ìfẹ́ tí kò ní àgàbàgebè kì í wá ire ara rẹ̀. Ìfẹ́ tòótọ́ ń mú kí ara tuni nígbà tí a bá sún mọ́ ẹnì kan. (Mátíù 11:28-30) Ọ̀rọ̀ tí a kò dárúkọ ẹni tí ó sọ ọ́, tí a fà yọ tẹ̀ lé e yìí lè mú kí a ronú nípa irú ìfẹ́ tí a ní fún àwọn ẹlòmíràn: “Òdodo láìsí ìfẹ́ ń sọni di aláìgbatẹnirò. Ìgbàgbọ́ láìsí ìfẹ́ ń sọni di aláṣejù. Agbára láìsí ìfẹ́ ń sọni di òkú òǹrorò. Iṣẹ́ láìsí ìfẹ́ ń múni kẹ̀yìn sí ohun títọ́. Ìwàlétòlétò láìsí ìfẹ́ ń sọ wá di ẹni tí àníyàn rẹ̀ kò ní láárí.”
Àwọn tí ó jẹ́ ìlànà nìkan ni wọ́n ń tẹ̀ lé lè kó sínú ọ̀fìn dídi ẹni tí kò ní ìfẹ́. Ẹ wo bí gbogbo wa ì bá ti jẹ́ ẹni tí ń gbéni ró tó, ká ní a ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:12-14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi ìfẹ́ hàn bí Jésù ṣe fi kọ́ni