ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/22 ojú ìwé 3-4
  • Ìjíròrò Nípa Ojú Ọjọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjíròrò Nípa Ojú Ọjọ́
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ojú Ọjọ́ Tó Ń Yí Pa Dà àti Ọjọ́ Ọ̀la Wa
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Fara Da Àjálù Tí Ojú Ọjọ́ Máa Ń Fà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ayé Ń Móoru O!—Ǹjẹ́ Àtúnṣe Kankan Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ojú Ọjọ́ Júujùu
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 5/22 ojú ìwé 3-4

Ìjíròrò Nípa Ojú Ọjọ́

IBI yòówù kí o máa gbé, ẹni yòówù kí o sì jẹ́, ojú ọjọ́ ní nǹkan láti ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé rẹ. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ooru àti oòrùn yóò mú lọ́jọ́ kan, ìwọ yóò wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́. Bí ó bá jẹ́ òtútù ni, ìwọ yóò wọ kóòtù, ìwọ yóò sì dé fìlà. Bí ó bá jẹ́ òjò ńkọ́? Ìwọ yóò nawọ́ mú agbòjò rẹ.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ojú ọjọ́ máa ń mú inú wa dùn; ní àwọn ìgbà mìíràn, ó máa ń já wa kulẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń jẹ́ aṣekúpani tí ń wá bí ìjì líle, ẹ̀fúùfù ńlá, ọ̀dá, afẹ́fẹ́ olójò-dídì kéékèèké, tàbí ẹ̀fúùfù olójò-ńlá. Yálà o nífẹ̀ẹ́ sí ojú ọjọ́ tàbí o kórìíra rẹ̀, yálà o kẹ́gàn ojú ọjọ́ tàbí o kò kọbi ara sí i, kò kúkú níbi í rè, ó ń nípa lórí ìgbésí ayé wa láti ìgbà tí wọ́n ti bí wa títí di ìgbà tí a bá kú.

Ẹnì kan fọgbọ́n sọ nígbà kan pé: “Gbogbo ènìyàn ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ojú ọjọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.” Ní gidi, ó ti sábà máa ń jọ pé ojú ọjọ́ kọjá ohun tí agbára wá ká láti yí padà lọ́nàkọnà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, púpọ̀púpọ̀ sí i àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni kò gba ìyẹn gbọ́ mọ́. Wọ́n sọ pé, títú tí gáàsì carbon dioxide àti àwọn gáàsì mìíràn ń tú jáde yàà sínú afẹ́fẹ́ àyíká wa ń mú ìyípadà bá àwọn ìrísí onígbàpípẹ́ ti ojú ọjọ́ wa.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ògbógi ti sọ, báwo ni ìyípadà tí ń bọ̀ yìí yóò ṣe rí? Bóyá láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Ọlọ́pọ̀ Orílẹ̀-Èdè Lórí Ìyípadà Ipò Ojú Ọjọ́ (IPCC), tí ń rí ìsọfúnni láti inú òye iṣẹ́ àwọn onímọ̀ nípa ipò ojú ọjọ́, àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé, àti àwọn ògbóǹtagí nínú ìṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ewu tí iye wọ́n lé ní 2,500 láti 80 orílẹ̀-èdè, ni ìdáhùn tí kò ṣeé jà níyàn jù lọ yóò ti wá. Nínú ìròyìn wọn ti 1995, ìgbìmọ̀ IPCC sọ pé ipò ojú ọjọ́ ilẹ̀ ayé ti ń móoru sí i. Láàárín ọ̀rúndún tí ń bọ̀, bí nǹkan bá ń bá a lọ bí ó ṣe rí yìí, ó ṣeé ṣe kí ìwọ̀n ìgbóná náà fi iye tí ó tó ìwọ̀n 3.5 lórí òṣùwọ̀n Celsius pọ̀ sí i.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àfikún ìwọ̀n díẹ̀ lè má dà bí èyí tí a ní láti dààmú jù nípa rẹ̀, ìyípadà ìwọ̀n ìgbóná díẹ̀ nínú ipò ojú ọjọ́ àgbáyé lè yọrí sí ìjábá. Àwọn ohun tí a tò tẹ̀ lé e yìí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn rí tẹ́lẹ̀ pé yóò wá ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún tí ń bọ̀.

Ojú ọjọ́ tí kò bára dé lọ́nà lílégbákan ní ẹkùnjẹkùn. Ní àwọn àgbègbè kan, ọ̀dá lè wà pẹ́ jù, tí òjò sì lè pọ̀ jù ní àwọn ibòmíràn. Ìjì àti ìkún omi lè wá di púpọ̀ gan-an; kí àwọn ìjì líle sì túbọ̀ máa ba nǹkan jẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ni ìkún omi àti ìyàn ti pa, ìmóoru ilẹ̀ ayé lè mú kí iye àwọn tí ń kú náà túbọ̀ pọ̀ sí i.

Ewu ìlera púpọ̀ sí i. Àìsàn àti ikú tí okùnfà rẹ̀ tan mọ́ ooru lè pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ, ìmóoru ilẹ̀ ayé tún lè mú kí àgbègbè tí àwọn kòkòrò tí ń gbé àwọn àrùn ilẹ̀ olóoru, bí ibà àti dengue, kiri ń gbé pọ̀ sí i. Ní àfikún, ìpèsè omi tí kò níyọ̀ tí ó dín kù nítorí ìyípadà nínú bí òjò dídì àti òjò ti ń rọ̀ sí ní ẹkùnjẹkùn, lè mú kí àwọn àrùn kan tí ń gbé inú omi àti oúnjẹ àti àwọn kòkòrò àfòmọ́ pọ̀ sí i.

Àwọn ibùgbé àdánidá tí a wu léwu. Àwọn igbó àti ilẹ̀ àbàtà, tí ń sẹ́ afẹ́fẹ́ àti omi wa, ni ìdíwọ̀n ìgbóná tí ó túbọ̀ móoru àti ìyípadà nínú bí òjò ti ń rọ̀ sí lè wu léwu. Dídánásungbó lè di lemọ́lemọ́, kí ó sì túbọ̀ légbá kan.

Ìtẹ́jú òkun tí ń ga sókè sí i. Àwọn tí ń gbé àwọn àgbègbè etíkun tí ó relẹ̀ yóò ní láti kó kúrò níbẹ̀ àyàfi tí a bá gbé àwọn iṣẹ́ tí ó gbówó lórí ṣe láti fi sé òkun mọ́. Omi yóò bo àwọn erékùṣù kan bámúbámú.

Irú àwọn ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ ha bẹ́tọ̀ọ́ mu bí? Ojú ọjọ́ ilẹ̀ ayé ha ń móoru sí i bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀dá ènìyàn ló ha ni ẹ̀bi náà bí? Níwọ̀n bí ohun tó wà nílẹ̀ ti pọ̀ tó báyìí, kò yani lẹ́nu pé àwọn ògbógi ń jiyàn lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí gan-an. Àwọn àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé èyí gbé díẹ̀ lára àwọn ọ̀ràn nípa rẹ̀ yẹ̀ wò, wọ́n sì jíròrò lórí ìbéèrè nípa bóyá a ní láti dààmú nípa ọjọ́ iwájú pílánẹ́ẹ̀tì wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́