ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 8/8 ojú ìwé 22-24
  • N Kò Ṣe Lè Pọkàn Pọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • N Kò Ṣe Lè Pọkàn Pọ̀?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Ìrònú Rẹ Tí Ń Yí Padà
  • Àwọn Ìmọ̀lára àti Àwọn Omi Ìsúnniṣe
  • Bí O Ṣe Ń Sùn Tó
  • Ipa Tí Oúnjẹ Ń Ní Lórí Ìpọkànpọ̀
  • Ìran Ènìyàn Onítẹlifíṣọ̀n òun Kọ̀ǹpútà
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Pọkàn Pọ̀?
    Jí!—1998
  • Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fún Àwọn Ọmọ Wọn Tó Ti Bàlágà
    Jí!—2011
  • Kí Nìdí Tára Mi Fi Ń Yí Pa Dà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 8/8 ojú ìwé 22-24

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

N Kò Ṣe Lè Pọkàn Pọ̀?

“Nígbà mìíràn, ó ń ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Mo ń gbọ́rọ̀ ní ìpàdé ìjọ kan, lójijì, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí lọ sórí nǹkan mìíràn. Ìṣẹ́jú mẹ́wàá kọjá kí n tó tún lè pọkàn pọ̀.”—Jesse.

“PỌKÀN PỌ̀!” Ǹjẹ́ o máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn déédéé lẹ́nu àwọn olùkọ́ tàbí òbí rẹ? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, bóyá o máa ń ní ìṣòro láti pọkàn pọ̀. Ó ṣeé ṣe kí o máà máa ṣe dáradára tó nítorí rẹ̀. O sì lè rí i pé àwọn ẹlòmíràn kì í fojúure wò ọ́, tàbí wọ́n ń pa ọ́ tì bí ẹni ọtí ń pa, tí iyè rẹ̀ ti ra, tàbí wọ́n ń wò ọ́ bí aláìmọ̀wàáhù.

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àìlèpọkànpọ̀ lè nípa búburú lórí ipò rẹ nípa tẹ̀mí. Ṣebí Bíbélì fúnra rẹ̀ pàṣẹ pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Ní gidi, a pàṣẹ fún àwọn Kristẹni láti “fún” àwọn ohun tẹ̀mí “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.” (Hébérù 2:1) Bí ó bá sì wá ṣòro fún ọ láti pọkàn pọ̀, ó lè ṣòro fún ọ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí.

Kí ló lè jẹ́ ìṣòro náà? Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àìpọkànpọ̀ lè jẹ́ nítorí àìsàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùwádìí kan gbà pé ìgbékalẹ̀ ètò ìfìsọfúnniránṣẹ́ iṣan inú ọpọlọ tí kò ṣiṣẹ́ dáadáa ló ń fa Àrùn Àìlèpọkànpọ̀.a Àwọn èwe kan ní àwọn àìsàn tí a kò ì mọ̀ dájú, bí àìgbọ́ròó tàbí àìríran. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú lè dí ẹnì kan lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀. Àwọn olùwádìí ti rí i pé ní gbogbogbòò, àwọn èwe ń ní ìṣòro láti pọkàn pọ̀ ju àwọn àgbà lọ. Àìpọkànpọ̀ tipa bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn èwe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í sábà jẹ́ nítorí àìsàn.

Ọ̀nà Ìrònú Rẹ Tí Ń Yí Padà

Bí o bá ń níṣòro láti pọkàn pọ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro tí ń bá ìdàgbà rìn ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.” (1 Kọ́ríńtì 13:11) Bẹ́ẹ̀ ni, bí o ti ń dàgbà ni bí o ṣe ń ronú ń yí padà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Adolescent Development ṣe wí, “agbára ìwòye tuntun . . . máa ń yọjú nígbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà.” O ń bẹ̀rẹ̀ sí ní agbára láti lóye àwọn èrò àti òye tí ó jẹ́ ti èrò orí nìkan, o sì ń lè tú wọn palẹ̀. O túbọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lóye nípa ìwà rere, ìlànà ìwà híhù, àti àwọn ọ̀ràn gbogbogbòò mìíràn. O bẹ̀rẹ̀ sí ronú, bí àgbàlagbà, nípa ìgbésí ayé rẹ ọjọ́ ọ̀la.

Kí ló lè jẹ́ ìṣòro náà? Níní gbogbo èrò, àbá, àti òye tuntun wọ̀nyí, tí ń yí lọ yí bọ̀ nínú ọpọlọ, lè máa pín ọkàn níyà. O kò ronú lóréfèé bí ọmọ kékeré tí ń ronú àwọn nǹkan kéékèèké lásán mọ́. Ní báyìí, ọpọlọ rẹ ti ń mú ọ ṣàtúpalẹ̀ àwọn ohun tí o ń rí, tí o ń gbọ́, kí o sì ronú jinlẹ̀ nípa wọn. Ọ̀rọ̀ kan tí olùkọ́ kan sọ lè mú ìrònú rẹ yà bàrá. Àmọ́, bí kò bá jẹ́ pé o kọ́ láti káwọ́ ìrònú rẹ tí ń yà bàrá, o lè pàdánù àwọn ìsọfúnni tó níye lórí. Lọ́nà dídùnmọ́ni, Bíbélì sọ pé ọkùnrin olóòótọ́ náà, Aísíìkì, ṣe àṣàrò láìsí ìdíwọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 24:63) Bóyá yíya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, láti jókòó pẹ̀sẹ̀, kí o ṣàṣàrò, kí o sì yanjú àwọn nǹkan lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ pọkàn pọ̀ ní àwọn ìgbà mìíràn.

Àwọn Ìmọ̀lára àti Àwọn Omi Ìsúnniṣe

Àwọn ìmọ̀lára rẹ pẹ̀lú lè máa pín ọkàn rẹ níyà. O ń gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tí o ń kà tàbí tí o ń gbọ́, àmọ́ o rí i pé o ń ronú lórí àwọn nǹkan mìíràn. Bí ọkàn rẹ ti ń lọ sórí àárẹ̀ àti ìsoríkọ́ ló ń lọ sórí ìyáragágá àti ìdùnnú. Fọkàn balẹ̀! Orí rẹ kò dà rú. Ó lè wulẹ̀ jẹ́ pé àwọn omi ìsúnniṣe ara rẹ ló ń dà ọ́ láàmú. O ń nírìírí àwọn ìyípadà ìgbà ìbàlágà.

Kathy McCoy àti Charles Wibbelsman kọ̀wé pé: “Ìmọ̀lára ń pọ̀ gidigidi ní àwọn ọdún àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà . . . Dé àyè kan, àwọn àfihàn ìmọ̀lára wọ̀nyí jẹ́ apá kan bíbàlágà. Èyí kan àìfararọ tí gbogbo ìyípadà tí o ń ní nísinsìnyí ń mú wá lọ́nà kan.” Síwájú sí i, o ń sún mọ́ “ìgbà ìtànná òdòdó èwe”—àkókò tí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ máa ń lágbára jù nínú ìgbésí ayé. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Òǹkọ̀wé Ruth Bell wí pé: “Àwọn ìyípadà inú ara nígbà ìbàlágà máa ń fa ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ tó túbọ̀ lágbára lọ́pọ̀ ìgbà. O lè rí i pé o ń ronú púpọ̀ sí i nípa ìbálòpọ̀, tí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ túbọ̀ tètè máa ń ru ọ́ sókè, tí o sì máa ń nímọ̀lára pé ọ̀ràn ìbálòpọ̀ gbà ọ́ lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”b

Ìrònú Jesse, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀, máa ń yà bàrá lọ́nà tí ó wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn ọ̀dọ́langba, ó wí pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ronú nípa àwọn ọmọbìnrin tàbí ìdààmú ọkàn kan tí mo ní tàbí ohun tí n óò wá ṣe lẹ́yìn náà.” Tó bá yá, ìmọ̀lára tí ń ru gùdù náà yóò rọlẹ̀. Ní báyìí ná, máa lo ìbára-ẹni-wí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” (1 Kọ́ríńtì 9:27) Bí o bá ṣe kọ́ láti máa káwọ́ ìmọ̀lára rẹ tó ni yóò ṣeé ṣe fún ọ láti pọkàn pọ̀ tó.

Bí O Ṣe Ń Sùn Tó

Ara rẹ tí ń dàgbà ń fẹ́ oorun tó pọ̀ tó kí o lè dàgbà ní ìrísí, kí ọpọlọ rẹ sì lè ráyè ṣiṣẹ́ lórí àwọn èrò àti ìmọ̀lára tuntun tí o ń bá pàdé lójoojúmọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́langba ń dí ara wọn lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kì í lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti fi sùn. Ẹnì kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ìgbékalẹ̀ àti àrùn iṣan ara sọ pé: “Ara kò ní gbójú fo iye wákàtí tí ó yẹ kí ẹnì kan fi sùn, tí kò sùn. Dípò bẹ́ẹ̀, yóò máa rántí nígbà gbogbo, lójijì ni yóò sì yọjú lọ́nà gbígbàgbé nǹkan, àìlèpọkànpọ̀, àti ìrònú tí ń falẹ̀.”

Àwọn olùwádìí kan gbà pé wíwulẹ̀ fi wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kún àkókò tí ẹnì kan fi ń sùn lóru lè mú kí agbára ìpọkànpọ̀ rẹ̀ sunwọ̀n sí i gan-an. Lóòótọ́, Bíbélì dẹ́bi fún ìwà ọ̀lẹ àti ìfẹ́ oorun sísùn ṣáá. (Òwe 20:13) Bí ó ti wù kí ó rí, ó lọ́gbọ́n nínú láti sinmi tó bó ṣe yẹ kí ara lè gbéṣẹ́ dáradára.—Oníwàásù 4:6.

Ipa Tí Oúnjẹ Ń Ní Lórí Ìpọkànpọ̀

Ó ṣeé ṣe kí oúnjẹ jẹ́ ìṣòro mìíràn. Àwọn ọ̀dọ́langba fẹ́ràn àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá àti oníṣúgà gan-an. Àwọn olùwádìí sọ pé, nígbà tí ó ṣeé ṣe kí àwọn pàrùpárù oúnjẹ dùn, ó jọ pé wọ́n ń dín ìjípépé ọpọlọ kù. Bákan náà, àwọn ìwádìí tọ́ka sí i pé ìṣiṣẹ́ ọpọlọ máa ń lọ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ènìyàn bá jẹ oúnjẹ eléròjà carbohydrate, bí búrẹ́dì, èso oníhóró, ìrẹsì, tàbí pasta. Èyí lè jẹ́ nítorí pé àwọn èròjà carbohydrate máa ń mú kí ìwọ̀n kẹ́míkà tí a ń pè ní serotonin pọ̀ sí i nínú ọpọlọ, ó sì ń mú kí oorun kun ènìyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ dámọ̀ràn pé kí a máa jẹ àwọn oúnjẹ eléròjà protein nígbà tí a bá fẹ́ ṣe ohun tó gba kí ọpọlọ wà lójúfò.

Ìran Ènìyàn Onítẹlifíṣọ̀n òun Kọ̀ǹpútà

Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́ ti rò pé tẹlifíṣọ̀n àti àwọn àwòrán rẹ̀ tí ń yára kọjá ń mú kí àwọn èwe má lè pọkàn pọ̀ lọ títí, àwọn kan sì ti ń nàka àbùkù kan náà sí kọ̀ǹpútà nísinsìnyí. Nígbà tí àwọn ògbógi ṣì ń jiyàn nípa bí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé wọ̀nyí ṣe ń nípa lórí àwọn èwe, kò dájú pé lílo àkókò púpọ̀ nídìí tẹlifíṣọ̀n tàbí nídìí àwọn eré orí kọ̀ǹpútà ṣàǹfààní. Èwe kan sọ pé: “Nítorí tí a ní àwọn nǹkan bí àwọn eré ìdárayá fídíò, kọ̀ǹpútà, àti ìsokọ́ra alátagbà Internet, àwa ọmọdé ti fi rírí ohun tí a ń fẹ́ gbà kíákíá kọ́ra.”

Ìṣòro náà ni pé, ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìgbésí ayé la ń rí nípasẹ̀ ìsapá, ìforítì, àti sùúrù tí ó ti wà nígbà kan rí nìkan. (Fi wé Hébérù 6:12; Jákọ́bù 5:7.) Nítorí náà, má wulẹ̀ gbà pé nǹkan gbọ́dọ̀ máa yára kánkán, kí ó sì máa dáni lára yá, kí ó tó níye lórí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wíwo tẹlifíṣọ̀n àti ṣíṣe àwọn eré orí kọ̀ǹpútà lè dáni lára yá, èé ṣe tí o kò máa kun àwòrán, kí ó máa ya àwòrán, tàbí kí o kọ́ bí a ṣe ń lo ohun ìkọrin kan? Irú òye iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè mú kí agbára ìpọkànpọ̀ rẹ sunwọ̀n sí i.

Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí o lè gbà mú kí agbára ìpọkànpọ̀ rẹ pọ̀ sí i? Dájúdájú, wọ́n wà, àpilẹ̀kọ kan lọ́jọ́ iwájú yóò sì gbé díẹ̀ nínú wọn jáde.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àwọn ìtẹ̀jáde Jí!, November 22, 1994, ojú ìwé 3 sí 12; June 22, 1996, ojú ìwé 11 sí 13; àti February 22, 1997, ojú ìwé 5 sí 10.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbé Ọkàn Mi Kúrò Lára Ẹ̀yà Òdìkejì?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti August 8, 1994.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

Àwọn olùwádìí sọ pé, ó jọ pé àwọn pàrùpárù oúnjẹ máa ń dín ìjípépé ọpọlọ kù

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

“Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ronú nípa àwọn ọmọbìnrin tàbí ìdààmú ọkàn kan tí mo ní”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ǹjẹ́ ó sábà máa ń ṣòro fún ọ láti pọkàn pọ̀ ní kíláàsì?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́