Ojútùú Wo Ni Ọlọ́run Ní fún Ìwà Ìkà?
BÁWO ni a ṣe lè dènà ìwà ìkà? Kí ni ojútùú rẹ̀? Nígbà tí a bá yẹ ìtàn wò, ó ṣe kedere pé àwọn ojútùú tí ènìyàn ní ti kùnà. Ní gidi, ìtakora pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ọwọ́ tí àwọn aṣáájú ènìyàn ti fi mú ọ̀ràn náà, bí kò bá tilẹ̀ jẹ́ àgàbàgebè gan-an.
Mú 1995 bí àpẹẹrẹ. Ó sàmì àádọ́ta ọdún tí Ìpakúpa láti ọwọ́ àwọn Nazi àti Ogun Àgbáyé Kejì wá sópin, ó sì sàmì àádọ́ta ọdún ìbúgbàù bọ́ǹbù eléròjà atom. Lọ́dún yẹn, a ṣe àwọn ayẹyẹ ìrántí tí àwọn aṣáájú lágbàáyé pésẹ̀ sí ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé. Èé ṣe? Láti tàtaré ìmọ̀lára ìkórìíra àwọn ìwà ìkà wọ̀nyí, kí irú rẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, àwọn kan tó ṣàkíyèsí ohun tó ṣẹlẹ̀ rí ìtakora tí ń ba nǹkan jẹ́ nínú irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀.
Àgàbàgebè
Níbi àwọn ayẹyẹ tí a polongo gidigidi wọ̀nyí, gbogbo aṣojú ìsìn àti ti ìjọba ń fẹ́ kí a rí àwọn bí aṣenilóore, tàbí ó kéré tán, wọn kò fẹ́ kí a wo àwọn bí olubi. Síbẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́bi fún àwọn ìwà ìkà àtijọ́ ti to àwọn ohun ìjà jọ rẹpẹtẹ, wọ́n sì ń wéwèé owó ìná rẹpẹtẹ fún ète yẹn. Nígbà kan náà, wọn kò tíì rí ojútùú sí àwọn ìṣòro tó ṣe kókó bí òṣì, ìwà ìbàjẹ́, àti ìbàyíkájẹ́, tí wọ́n sì ń sọ lọ́pọ̀ ìgbà pé àwọn kò ní owó tó fún wọn.
Ìsìn ayé ń wọ́nà láti gbé oríṣi ìtàn kalẹ̀, tí yóò bo bí kò ṣe fọhùn fún ìgbà pípẹ́ nípa àwọn ìwà ìkà àwọn aláṣẹ oníkùmọ̀ mọ́lẹ̀, kí ó sì mú kí àwọn ará ìlú má mọ̀ nípa àjọṣe tí ó ní pẹ̀lú irú àwọn aláṣẹ bẹ́ẹ̀. Àwọn ìsìn wọ̀nyí kò ṣe ohunkóhun láti dá àwọn onísìn kan náà lọ́wọ́ kọ́ nínú pípa ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, Kátólíìkì pa Kátólíìkì, Pùròtẹ́sítáǹtì sì pa Pùròtẹ́sítáǹtì, nítorí pé wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ń bára wọn jà. Ìhà méjèèjì ń sọ pé Kristẹni làwọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣe ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Jésù fi kọ́ni. (Mátíù 26:52; Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 3:10-12; 4:20, 21) Àwọn ìsìn mìíràn ṣe bákan náà. Ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé lónìí, àwọn onísìn wọ̀nyí ṣì ń hùwà ìkà lóníranǹran.
Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn aṣáájú ìsìn ń ṣe àgàbàgebè. Jésù dẹ́bi fún wọn, ó wí pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ kọ́ sàréè àwọn wòlíì, ẹ sì ṣe ibojì ìrántí àwọn olódodo lọ́ṣọ̀ọ́, ẹ sì wí pé, ‘Ì bá ṣe pé àwa wà ní àwọn ọjọ́ àwọn baba ńlá wa, àwa kì bá jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì.’ Nítorí náà, ẹ ń jẹ́rìí lòdì sí ara yín pé ẹ̀yin jẹ́ ọmọ àwọn tí wọ́n ṣìkà pa àwọn wòlíì.” (Mátíù 23:29-31) Àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn sọ pé àwọn jẹ́ ẹni Ọlọ́run, ṣùgbọ́n alágàbàgebè tó ṣe inúnibíni sí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni wọ́n.
Ẹ̀kọ́ Tí Bíbélì Kọ́ni
A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ láti inú ìtàn ayé, ṣùgbọ́n inú Bíbélì ni a ti lè rí ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní jù. Kò gbé iṣẹ́ títúmọ̀ ìtàn karí èrò ènìyàn tàbí ẹ̀tanú wọn. Bíbélì gbé àlàyé rẹ̀ nípa ìtàn àti ọjọ́ ọ̀la karí ọ̀nà ìrònú ti Ọlọ́run.—Aísáyà 55:8, 9.
Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rere àti ìṣẹ̀lẹ̀ búburú, ó sì tún sọ nípa àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè kọ́ ẹ̀kọ́ títọ̀nà, tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, láti inú àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mélòó kan nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, ó parí ọ̀rọ̀ pé: “Wàyí o, nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa.” (1 Kọ́ríńtì 10:11) Jésù fúnra rẹ̀ fa ẹ̀kọ́ kan yọ láti inú ìtàn nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.”—Lúùkù 17:32.
Ohun Tí Ọlọ́run Ń Rántí àti Ohun Tí Ó Ń Gbàgbé
Bíbélì kọ́ni pé ìwà tí àwọn ènìyàn bá hù ní ń mú kí Ọlọ́run rántí wọn, tàbí kí ó gbàgbé wọn. “Lọ́nà títóbi,” Ọlọ́run ń dárí ji àwọn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ronú pìwà dà. (Aísáyà 55:7) Bí ẹni burúkú kan bá ronú pìwà dà, tí ó sì “yí padà . . . kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo, . . . kò sí ìkankan nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ . . . tí a óò rántí lòdì sí i.”—Ìsíkíẹ́lì 33:14-16.
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò san ẹ̀san fún àwọn tí ó bá rántí sí rere. Jóòbù olóòótọ́ gbàdúrà pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù [sàréè gbogbo ènìyàn lápapọ̀], . . . pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!”—Jóòbù 14:13.
Ní òdì kejì, Ọlọ́run yóò hùwà sí àwọn ẹni burúkú tí kò ronú pìwà dà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Ó sọ fún Mósè pé: “Èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.” (Ẹ́kísódù 32:33) Ní tòótọ́, Ọlọ́run yóò gbàgbé àwọn ẹni burúkú títí láé.
Onídàájọ́ Ìkẹyìn
Ọlọ́run ni Onídàájọ́ ìkẹyìn ní ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn. (Jẹ́nẹ́sísì 18:25; Aísáyà 14:24, 27; 46:9-11; 55:11) Ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ rẹ̀ tí kò láfijọ, kò ní gbàgbé àìlóǹkà ìwà ìkà tí a ti hù sí ìran ènìyàn. Ní ọjọ́ ìbínú òdodo rẹ̀, yóò dá gbogbo ènìyàn àti àwọn àwùjọ tó hùwà ìkà lẹ́jọ́.—Ìṣípayá, orí 18, 19.
Lára ìwọ̀nyí ni gbogbo ètò ìsìn èké, tí Ìwé Mímọ́ fún ní orúkọ ìṣàpẹẹrẹ náà, “Bábílónì Ńlá.” Àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ sọ pé: “Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti mú àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.”—Ìṣípayá 18:2, 5.
A retí pé kí àwọn ìsìn wọ̀nyí kọ́ àwọn olùsìn ní ohun títọ́, ṣùgbọ́n wọ́n kùnà. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa gbogbo ìsìn ayé tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run pé: “Nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 18:24) Nítorí tí wọ́n kùnà láti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn onísìn ẹlẹgbẹ́ wọn, a fi ẹ̀sùn ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kan àwọn ìsìn wọ̀nyí.
Ayé Tuntun Kan Dé Tán!
Ìgbà tí a óò mú ibi kúrò ti dé tán nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Sefanáyà 2:1-3; Mátíù 24:3, 7-14) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àkókò yóò dé, tí ‘kì yóò sí ọ̀fọ̀, igbe ẹkún, àti ìrora mọ́’ fún àwọn aláyọ̀, olùgbé orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 21:3-5) Àwọn ìwà ìkà àti ìpakúpa kì yóò wáyé mọ́, nítorí tí a óò gba ìṣàkóso ayé yìí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, a óò sì fi fún Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run lọ́wọ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” náà, Jésù Kristi.—Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.
Nígbà yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 46:9 yóò wá ṣẹ pátápátá pé: “[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” Àlàáfíà yẹn yóò máa wà títí ayé nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 2:4 ṣe sọ tẹ́lẹ̀, “orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, Sáàmù 37:11 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ní gidi, a óò sọ nígbà náà pé, “gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú.”—Aísáyà 14:7.
Gbogbo ìwọ̀nyí túmọ̀ sí pé ayé tuntun òdodo kan ti dé tán. Nínú ayé yẹn sì nìyí, lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run, ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu mìíràn yóò ṣẹlẹ̀—àjíǹde àwọn òkú! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnni ní ìdánilójú pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣàfihàn èyí nípa jíjí àwọn òkú dìde. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ó jí ọ̀dọ́mọbìnrin kan dìde, ìròyìn náà sọ pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, omidan náà sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn . . . Ní kíá, [àwọn tí ń kíyè sí i] kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” (Máàkù 5:42) Nígbà àjíǹde, a óò jí àwọn tí ó ti kú nípasẹ̀ àwọn ìwà ìkà àti àwọn mìíràn tí ó ti kú tipẹ́ dìde, a óò sì fún wọn ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43) Bí àkókò sì ti ń lọ, “àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—Aísáyà 65:17.
Yóò jẹ́ ìgbésẹ̀ ọlọgbọ́n fún ọ láti gba ìmọ̀ pípé ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, kí o sì ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run yóò wá rántí rẹ sí rere nígbà tí ó bá ń yanjú ìṣòro ìwà ìkà, tí ó sì ń mú àwọn tí a ti hùwà ìkà sí padà sí ìyè. Jésù wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ọlọ́run yóò yí ilẹ̀ ayé yìí padà di párádísè alálàáfíà kan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọlọ́run yóò mú gbogbo ohun tí ìwà ìkà àtijọ́ ti yọrí sí kúrò nípa jíjí àwọn òkú dìde