Ǹjẹ́ A Lè—Dárí Jì, Ká Sì Gbàgbé?
Ó LÉ ní 50 ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí ní 1945. Ogun yẹn ló ní ìwà ìkà nínú jù, tó sì fa àdánù jù, nínú gbogbo ìtàn ènìyàn.
Ogun Àgbáyé Kejì jà fún ọdún mẹ́fà, ó sì gba ẹ̀mí nǹkan bí 50 mílíọ̀nù ènìyàn, nínú èyí tí àwọn ará ìlú lásán wà. Àìlóǹkà ni àwọn tó sọ di aláàbọ̀ ara ní ti ara ìyára, ní ti èrò orí, àti ní ti ìmọ̀lára. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fojú winá àwọn ọdún ogun oníjàǹbá wọ̀nyẹn ṣì ń rántí àwọn ìwà ìkà tí wọ́n rí àti àwọn olólùfẹ́ tí wọ́n kú.
A kò gbàgbé ìwà ìkà tí àwọn Nazi hù nígbà Ìpakúpa, tó mú ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ lọ. Ní Yúróòpù àti Éṣíà, àwọn ológun tó ń wọlé kógun tini, tó ń pani, tó ń fipá báni lò, tó ń jíni lẹ́rù kó, tó sì ń pá àwọn ará ìlú láyà, hùwà ìkà lọ́pọ̀lọpọ̀. Lẹ́yìn náà ni àwọn ìkóguntini láti ojú òfuurufú, tó fa ìsọdahoro, ìpalára, àti ikú fún àìlóǹkà àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tún wà. Ojú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ jagunjagun tún rí màbo ní onírúurú pápá ìtẹ́gun kárí ayé.
Ìpalára ti Èrò Orí àti Ìmọ̀lára
Ọ̀pọ̀ ìpalára ti èrò orí àti ìmọ̀lára tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì fà ṣì wà láìṣeéparẹ́ nínú ọkàn ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà láàyè nígbà náà, tí wọ́n sì tún wà láàyè nísinsìnyí. Ó wù wọ́n láti gbàgbé gbogbo ìrántí bíbanilẹ́rù, tí ń bani nínú jẹ́ wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n, wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ti àwọn kan, wọ́n ń rántí àwọn ìpọ́njú náà bí ohun tí ń dẹ́rù bani tí ń ṣẹlẹ̀ léraléra.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mìíràn kò fẹ́ gbàgbé, bóyá nítorí pé wọ́n ń fẹ́ gbẹ̀san tàbí nítorí pé wọ́n ń fẹ́ bọlá fún ìrántí àwọn tó kú. Láfikún sí i, èrò kan tó gbilẹ̀ ni pé, kí a jẹ́ kí ìran ènìyàn máa rántí ìwà ìkà tó ṣẹlẹ̀ kọjá náà, pẹ̀lú èrò pé, irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ní 1994 sí 1995, ìmọ̀lára tó wà ní àyájọ́ ìrántí àádọ́ta ọdún ọjọ́ mánigbàgbé (tí Ẹgbẹ́ Ogun Alájọṣe balẹ̀ sí Normandy ní June 1944) àti ìrántí ìhà ti Yúróòpù nínú Ogun Agbáyé Kejì (ní May 1945) fi hàn pé, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn láti dáríjì, kí wọ́n sì gbàgbé. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í fara mọ́ ìsapá èyíkéyìí láti mú àwọn ọ̀tá àtijọ́ rẹ́ padà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn àbọ̀dé ológun ará Britain kọ̀ láti pe àwọn aṣojú ilẹ̀ Germany síbi ìrántí bí Ẹgbẹ́ Ogun Alájọṣe ṣe balẹ̀ sí Normandy.
Nígbà tí òǹkọ̀wé Vladimir Jankélévitch ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìkà tí àwọn Nazi hù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àti bí ó ṣe ṣòro tó láti dárí jì, kí a sì gbàgbé, ó sọ ọ́ báyìí pé: “Nípa irú ìwà ọ̀daràn arínilára bẹ́ẹ̀, ìmọ̀lára àdánidá . . . ni kí a bínú, kí a sì rí i dájú pé a kò gbàgbé, kí a sì lépa àwọn ọ̀daràn náà títí dé òpin ilẹ̀ ayé—gẹ́gẹ́ bí àwọn adájọ́ alájọṣe Ìgbìmọ̀ Ìgbẹ́jọ́ Nuremberg ṣe lérí.” Òǹkọ̀wé kan náà ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Tayọ̀tayọ̀ ni a óò yí àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run nínú Ìhìnrere ti Lúùkù Mímọ́ padà pé: Olúwa, má ṣe dárí jì wọ́n, nítorí pé wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”—Fi wé Lúùkù 23:34.
Ó bani nínú jẹ́ pé, láti 1945 wá di òní olónìí, àìlóǹkà ìwà ìkà mìíràn—ní Cambodia, Rwanda, Bosnia, ká mẹ́nu ba díẹ̀ péré—ti ń fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ nìṣó. Àwọn ìwà ìkà wọ̀nyí ti pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn, ó ti sọ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn di opó àti aláìlóbìí, ó ti ba ìgbésí ayé àwọn kan jẹ́, ó sì ti ń fa ìrántí tí ń bani lẹ́rù, ní àtúbọ̀tán rẹ̀.
Kò sí iyèméjì pé ọ̀rúndún ogún yìí ti jẹ́ àkókò ìwà òǹrorò tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí. Ó rí bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti sọ ní rẹ́gí tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn nípa àkókò yìí—àwọn ènìyàn ti jẹ́ “òǹrorò” àti “aláìní ìfẹ́ ohun rere.”—2 Tímótì 3:1-5; Ìṣípayá 6:4-8.
Kí Ló Yẹ Ká Ṣe?
Ìhùwàpadà àwọn ènìyàn ń yàtọ̀ síra nígbà tí wọ́n bá kojú irú ìwà àìṣènìyàn bẹ́ẹ̀. Àwa ńkọ́? Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa rántí? Àbí ó yẹ ká gbàgbé? Ǹjẹ́ rírántí túmọ̀ sí níní èrò ibi, tó jinlẹ̀, lódò ikùn wa, sí àwọn ọ̀tá wa àtijọ́, kí a kọ̀ láti dárí jì wọ́n? Lọ́nà mìíràn, ǹjẹ́ dídáríjì túmọ̀ sí pé ènìyàn lè gbàgbé pátápátá ní ti ìtumọ̀ mímú ìrántí búburú kúrò pátápátá?
Kí ni èrò Ẹlẹ́dàá ènìyàn, Jèhófà Ọlọ́run, nípa àwọn ìwà ọ̀daràn lílékenkà tí àwọn ènìyàn ti hù ní àkókò tiwa àti àwọn àkókò tó ṣáájú? Ǹjẹ́ yóò dárí ji àwọn tó hùwà náà? Ṣé kò sì tíì pẹ́ jù fún Ọlọ́run láti san ẹ̀san fún àwọn tí wọ́n pa nípasẹ̀ ìwà ìkà? Ǹjẹ́ ìrètí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kankan wà pé ìwà ìkà yóò dópin, nígbà tó ti ń ṣẹlẹ̀ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá? Báwo gan-an ni Ọlọ́run Olódùmarè yóò ṣe yanjú àwọn ọ̀ràn lílọ́júpọ̀ wọ̀nyí níkẹyìn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn ọmọ tí a pa àwọn òbí wọn nípakúpa kóra jọ ní àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi
[Credit Line]
UN PHOTO 186797/J. Isaac
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò U.S. Navy