Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wá Owó?
“Mo ń fẹ́ iṣẹ́ tí yóò mówó wá.”—Tanya.
Ọ̀PỌ̀ èwe ni èrò wọn dà bí ti Tanya. Èwe kan tí ń jẹ́ Sergio sọ pé: “Mo nílò owó láti fi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan àti láti lè ra aṣọ. N kò fẹ́ kí ó jẹ́ àwọn òbí mi ni yóò máa ṣe gbogbo nǹkan fún mi.” Ọ̀dọ́mọdé Laurie-Ann ń ṣiṣẹ́ nítorí ìdí kan náà. Ó wí pé: “Obìnrin ni mí, mo sì fẹ́ láti máa ra nǹkan.”
Nígbà náà, kò yani lẹ́nu nígbà tí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé, “akẹ́kọ̀ọ́ 3 lára àwọn 4 tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní [United States] ló ń gba ibi iṣẹ́ lọ lẹ́yìn ilé ìwé àti ní òpin ọ̀sẹ̀.” Dé àyè kan, èyí ń fi “ìfẹ́ owó” lọ́nà tí kò wà déédéé, tí ó wọ́pọ̀ nínú ayé onífẹ̀ẹ́-ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì yìí, hàn. (1 Tímótì 6:10) Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo àwọn èwe tí ń wá owó ni wọ́n ń juwọ́ sílẹ̀ fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì.
Bíbélì sọ pé: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Ọ̀pọ̀ ìdí tí ó jẹ́ ojúlówó sì lè wà tí ìwọ gẹ́gẹ́ bí èwe Kristẹni kan fi fẹ́ láti ní owó díẹ̀.a Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́mọdé Avian ṣàlàyé ìdí tí ó fi ń ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ méjì láàárín ọ̀sẹ̀ pé: “Ó ń jẹ́ kí n lè pèsè fún ara mi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé [ajíhìnrere alákòókò kíkún].”
O lè fẹ́ láti ní iṣẹ́ àyàbá kan nítorí ìdí kan náà. Bóyá o ń sáré àtilọ sí àpéjọpọ̀ Kristẹni kan ni. Tàbí bóyá o nílò àwọn aṣọ díẹ̀ tí yóò bójú mu láti wọ̀ lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Ohun yòówù kí ó jẹ́, owó ni o máa fi ra àwọn nǹkan wọ̀nyí. Láìsí àní-àní, Jésù ṣèlérí pé, Ọlọ́run yóò pèsè fún àwọn tí ‘ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Àmọ́, èyí kò fagi lé kí o dánú ṣe àwọn nǹkan kan nínú ọ̀ràn yìí. (Fi wé Ìṣe 18:1-3.) Kí wá ni àwọn ohun tí ó bọ́gbọ́n mu tí o lè ṣe bí o bá ní láti wá owó?
Bíbẹ̀rẹ̀
Ká sọ pé àwọn òbí rẹ gbà pé kí o máa ṣe àwọn iṣẹ́ kan, ohun tí o máa kọ́kọ́ ṣe lè jẹ́ láti tọ àwọn aládùúgbò, àwọn olùkọ́, àti àwọn ẹbí rẹ lọ, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ń wá iṣẹ́. Bí ojú bá ń tì ọ́ láti bi wọ́n tààràtà, o wulẹ̀ lè bi wọ́n ní irú iṣẹ́ tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n wà ní ọ̀dọ́langba. Wọ́n lè fún ọ ní àwọn ìsọfúnni díẹ̀ tí ó wúlò. Bí àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ̀ pé o ń wá iṣẹ́ bá ṣe pọ̀ tó ni ó ṣeé ṣe kí o fi rí ìsọfúnni àti ìtọ́kasí gbà tó.
Lẹ́yìn náà, gbìyànjú àwọn ìpolówó wíwá òṣìṣẹ́ nínú àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn pátákó ìsọfúnni ní àwọn ilé ìtajà, ilé ẹ̀kọ́ rẹ, àti àwọn ibi tí èrò ń wà mìíràn. Èwe kan tí ń jẹ́ Dave sọ pé: “Ọ̀nà tí mo gba rí iṣẹ́ nìyẹn. Mo wo inú àwọn ìwé ìròyìn, mo fi ìwé àkọsílẹ̀ irú iṣẹ́ tí mo mọ̀ àti bí mo ṣe tóótun tó ránṣẹ́ sí wọn nípasẹ̀ ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni, mo sì tẹ̀ wọ́n láago.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni kì í ṣeé polówó? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Seventeen ti sọ, àwọn kan fojú díwọ̀n pé, “ó tó mẹ́ta lára iṣẹ́ mẹ́wàá tí kì í ṣí sílẹ̀ àyàfi ìgbà tí ẹni tí ó lè ṣeé bá wá iṣẹ́ náà wá.” Bóyá o lè jẹ́ kí ọ̀gá iṣẹ́ kan gbà gbọ́ pé ó ní láti wá iṣẹ́ kan fún ọ!
Àmọ́ lọ́nà wo? O lè ronú pé, ‘N kò ní ìrírí iṣẹ́.’ Ó dára, ronú lẹ́ẹ̀kan sí i. O ha tọ́jú àbúrò rẹ nígbà tí àwọn òbí rẹ kò sí nílé tàbí kí o bá àwọn kan tọ́jú ìkókó wọn rí bí? Èyí fi hàn pé o tó fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́. O ha ti ran bàbá rẹ lọ́wọ́ láti tún ọkọ̀ ṣe rí? Ìyẹn fi hàn pé o lè ní ẹ̀bùn títún ẹ̀rọ ṣe. O ha mọ ìwé tẹ̀ tàbí o lè fi kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ bí? Àbí o ha gba máàkì fún ṣíṣe àwọn ohun tuntun kan bí? Ohun tí àwọn ọ̀gá iṣẹ́ tí ń wá òṣìṣẹ́ máa ń wá lára ẹni tí wọ́n fẹ́ gbà síṣẹ́ nìyẹn.
Má ṣe gbójú fo iṣẹ́ afipawọ́ rẹ àti àwọn ohun tí o nífẹ̀ẹ́ sí dá. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ń fi ohun èlò ìkọrin kan kọrin, ṣèwádìí bí àyè kan bá ṣí sílẹ̀ ní ilé iṣẹ́ kan tí ń ṣe ohun èlò orin. O ṣe kedere pé o nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tí ilé iṣẹ́ náà ń ṣe jáde, ìwọ yóò sì tóótun láti dáhùn àwọn ìbéèrè oníbàárà kan.
Kíkọ̀wé Wá Iṣẹ́
Jẹ́ kí a gbà pé wọ́n ti ní kí o wá fún àyẹ̀wò fún iṣẹ́ kan. Múra dáadáa, kí o sì wọ aṣọ tí ó sunwọ̀n, nítorí ìrínisí ni ìsọnilọ́jọ̀. Ó lè fi hàn pé o “tó fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, o jẹ́ onímọ̀ọ́tótó, o wà létòlétò”—tàbí òdì kejì rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Bíbélì ṣeé mú lò, tí ó fún àwọn Kristẹni obìnrin níṣìírí pé, ‘kí wọ́n máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.’ (1 Tímótì 2:9) Ìyẹn pẹ̀lú kan àwọn ọkùnrin. Má ṣe wọ aṣọ ìgbàlódé tàbí èyí tí ń fi ara sílẹ̀ lọ síbi àyẹ̀wò fún iṣẹ́, láìka irú iṣẹ́ tí ó jẹ́ sí.
Ìṣarasíhùwà rẹ ń sọ púpọ̀ nípa rẹ pẹ̀lú. Fi Òfin Oníwúrà ṣèwàhù: Ohun tí o bá fẹ́ kí ẹlòmíràn máa ṣe sí ọ ni kí o máa ṣe sí wọn. (Mátíù 7:12) Má ṣe pẹ́ dé ibi tí wọ́n ti pè ọ́ náà. Ṣe ọ̀yàyà, kí o sì wà lójúfò. Hùwà ọmọlúwàbí. Láìfọ́nnu àti láìsàsọdùn, ṣàlàyé ìdí tí o fi lérò pé o tóótun fún iṣẹ́ náà. Sọ̀rọ̀ bí ó ti rí pàtó.
Àwọn ògbógi kan dámọ̀ràn pé kí o mú ìwé àkọsílẹ̀ irú iṣẹ́ tí o mọ̀ àti bí o ṣe tóótun tó, tí ó wà létòlétò, dání (tàbí kí o fi ránṣẹ́ ṣáájú). Orúkọ, àdírẹ́sì, nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ, ìdí tí o fi ń wá iṣẹ́, bí o ṣe kàwé sí (títí kan ẹ̀kọ́ àkànṣe èyíkéyìí tí o lè ti kọ́), ìrírí tí o ní lẹ́nu iṣẹ́ tí o ń ṣe tẹ́lẹ̀ rí (títí kan iṣẹ́ tí o gbowó fún àti iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni), àwọn òye iṣẹ́ àkànṣe, ohun tí o lọ́kàn ìfẹ́ nínú rẹ̀ àti eré àfipawọ́ (ìwọ̀nyí lè fi bí o ṣe tóótun tó hàn) àti ìwé kan tí ń fi hàn pé ẹni tí wọ́n lè wádìí ìtóótun rẹ lọ́wọ́ rẹ̀ wà bí wọ́n bá fẹ́, gbọ́dọ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ náà. Bákan náà, o lè kọ ìwé mìíràn tí ó ní àwọn orúkọ, àdírẹ́sì, àti nọ́ńbà tẹlifóònù àwọn ènìyàn tí wọ́n lè dámọ̀ràn rẹ fún iṣẹ́ náà nínú. Sáà rí i dájú pé o gba àṣẹ lọ́wọ́ wọn ṣáájú. Àwọn tí o ti bá ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí, olùkọ́ kan, olùgbani-nímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́, ọ̀rẹ́ kan tí ó dàgbà lè wà lára wọn—ẹnikẹ́ni tí ó lè jẹ́rìí sí òye rẹ, bí o ṣe lè ṣiṣẹ́ sí, tàbí ìwà àbímọ́ni rẹ.
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ara Rẹ
Tí ó bá ṣẹlẹ̀ pé lójú bí o ṣe sa gbogbo ipá rẹ, o kò rí iṣẹ́ ńkọ́? Ohun tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ púpọ̀ nìyẹn. Àmọ́, má sọ̀rètí nù. Dídá iṣẹ́ ara rẹ sílẹ̀ lè yanjú ìṣòro náà. Kí ni àǹfààní rẹ̀? O lè gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò ara rẹ kalẹ̀, kí o sì máa ṣiṣẹ́ tó bí o bá ṣe fẹ́. Lótìítọ́, níní iṣẹ́ ara ẹni ń béèrè pé kí o ní ìsúnniṣe, ìkóra-ẹni-níjàánu, kí o sì ní ìfẹ́ inú láti dánú ṣe nǹkan.
Ṣùgbọ́n irú iṣẹ́ wo ni o lè dá sílẹ̀? Ronú nípa àdúgbò rẹ. Àìní ha wà fún ohun kan tàbí iṣẹ́ kan tí kò sí ẹni tí ń ṣe é bí? Fún àpẹẹrẹ, ká ní o fẹ́ràn àwọn ẹranko. O lè gba iye kan fún wíwẹ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn aládùúgbò rẹ tàbí gígé irun wọn kù. Tàbí bóyá o mọ bí a ti ń fi ohun èlò orin kọrin. Ǹjẹ́ o lè kọ́ àwọn mìíràn bí wọn yóò ṣe lò ó? Tàbí bóyá ọ̀ràn ti ṣíṣe iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn kan sábà máa ń ṣáátá, bí nínu fèrèsé tàbí fífọ ilẹ̀. Ojú kì í ti àwọn Kristẹni láti fi ọwọ́ wọn ṣiṣẹ́. (Éfésù 4:28) O tilẹ̀ lè gbìyànjú kíkọ́ iṣẹ́ tuntun kan. Wo àwọn ibi ìkówèésí tí o ti lè rí àwọn ìwé báyìí-ni-o-ṣe é, tàbí kí o ní kí ọ̀rẹ́ kan kọ́ ọ. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́mọdé Joshua gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìkọ̀wé gígúnrégé. Lẹ́yìn náà, ó dá iṣẹ́ kékeré kan sílẹ̀, ó ń ṣe ọnà sára àwọn ìwé ìkésíni síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó àti àpèjẹ mìíràn.—Wo àpótí náà, “Àwọn Iṣẹ́ Tí O Lè Dá Sílẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ ìṣílétí: Má ṣe kùgbù bẹ̀rẹ̀ òwò èyíkéyìí kí o tó wádìí iye tí yóò ná ọ àti àwọn ohun tí ó ní nínú. (Lúùkù 14:28-30) Lákọ̀ọ́kọ́, bá àwọn òbí rẹ sọ ọ́. Bákan náà, bá àwọn mìíràn tí wọ́n ti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ yóò béèrè pé kí o san owó orí? Ìwọ yóò ha nílò ìwé àṣẹ bí? Béèrè fún kúlẹ̀kúlẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ àdúgbò.—Róòmù 13:1-7.
Ṣe Nǹkan Níwọ̀ntúnwọ̀nsì!
Ní ti gidi, ewu ti dídáwọ́lé àwọn iṣẹ́ tí ó ju agbára rẹ lọ wà. Laurie-Ann sọ nípa àwọn èwe díẹ̀ tí a gbà síṣẹ́ pé: “Wọn kì í ṣe púpọ̀ nínú iṣẹ́ àṣetiléwá wọn, ó sì máa ń rẹ̀ wọ́n jù tí wọn kì í fi lè pọkàn pọ̀ ní kíláàsì.” Lótìítọ́, ní àwọn apá ibì kan lágbàáyé, kò sí ọgbọ́n tí àwọn èwe máa dá sí i ju pé kí wọ́n fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ láti lè ran ìdílé wọn lọ́wọ́ kí nǹkan lè máa gún régé. Àmọ́ bí ọ̀ràn tìrẹ kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ọ̀ràn yìí le mọ́ ọ lára? Bí ohun tí ọ̀pọ̀ ògbógi sọ, ṣíṣiṣẹ́ fún ohun tí ó ju 20 wákàtí lọ lọ́sẹ̀, nígbà tí o ṣì ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ jẹ́ àṣejù àti dídí àṣeyọrí góńgó ẹni lọ́wọ́. Àwọn kan dámọ̀ràn yíya ohun tí kò ju wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ lọ́sẹ̀.
Bí o bá lo èyí tí ó pọ̀ jù lára àkókò, agbára, àti làákàyè rẹ sórí iṣẹ́ tí o ń lọ ṣe lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́, ìlera, máàkì rẹ, àti pàápàá jù lọ ipò tẹ̀mí rẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í di ahẹrẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe àwọn àgbàlagbà nìkan ni “agbára ìtannijẹ ọrọ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn fún àwọn nǹkan yòókù” ti há mọ́. (Máàkù 4:19) Nítorí náà, ṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Sólómọ́nì kìlọ̀ nípa iṣẹ́ àṣejù pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:6.
Lóòótọ́, wíwá owó lè pọndandan. Bí ète tí o fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ bá sì gbámúṣé, tí ó sì jẹ́ aláìlábòsí, bí ti ọ̀dọ́mọdé Avian tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, ó lè dá ọ lójú pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá rẹ. Àmọ́, rí i dájú pé iṣẹ́ kò kó àárẹ̀ bá ọ gan-an débi tí o fi lè gbàgbé “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” ìyẹn ni, ire tẹ̀mí. (Fílípì 1:10) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó lè jẹ́ “ààbò,” ipò ìbátan rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ni yóò mú kí o ṣàṣeyọrí ní gidi.—Oníwàásù 7:12; Sáàmù 91:14.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” tí ó wà nínú àwọn Jí!, ìtẹ̀jáde July 22, 1991; August 8, 1991; àti September 22, 1997, gbé àwọn àǹfààní àti ìṣòro ṣíṣiṣẹ́ lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ yẹ̀ wò.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn Iṣẹ́ Tí O Lè Dá Sílẹ̀
• Nínu fèrèsé
• Títa ìwé ìròyìn tàbí kíkó o lọ fún àwọn ènìyàn
• Kíkó òjò dídì kúrò nílẹ̀
• Dídáko tàbí gígé koríko
• Títọ́jú ìkókó
• Bíbọ́ ẹran ọ̀sìn, mímú un jáde, tàbí wíwẹ̀ ẹ́
• Dídán bàtà
• Gígán aṣọ pọ̀ tàbí lílọ̀ ọ́
• Gbígbin èso àti títà á
• Sísin adìyẹ tàbí títa ẹyin
• Títẹ ìwé tàbí fífi kọ̀ǹpútà tẹ̀wé
• Jíjíṣẹ́ fúnni
• Bíbáni gbé ẹrù wá sílé
• Kíkọ́ni ní orin tàbí àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ mìíràn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Iṣẹ́ àṣejù lè mú kí máàkì rẹ lọ sílẹ̀