Àwọn Ètò Tí Àjọ UN Ṣe Nítorí Àwọn Ọ̀dọ́—Báwo Lo Ṣe Ṣàṣeyọrí Tó?
NÍ NǸKAN bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, àjọ UN kéde ọdún 1985 gẹ́gẹ́ bí Ọdún Àwọn Ọ̀dọ́ Jákèjádò Ayé. Ní àfikún, ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, àjọ UN gbé Ètò Ìgbéṣẹ́ṣe fún Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbáyé Dé Ọdún 2000 àti Ré Kọjá Rẹ̀ kalẹ̀. Wọ́n retí pé àwọn ètò wọ̀nyí yóò báni dín àwọn ìṣòro kù, yóò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọ́n lé ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ lágbàáyé túbọ̀ ní àǹfààní ìlọsíwájú. Ǹjẹ́ àwọn ètò wọ̀nyí mú kí nǹkan túbọ̀ ṣẹnuure fún àwọn ọ̀dọ́?
Dájúdájú, ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀nà kan. Ìwé ìròyìn Choices, tí Ìwéwèé Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fún Ìdàgbàsókè ṣe, fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ kan pé: Ní Thailand, ó lé ní ìdajì lára àwọn ọmọdé tí kò tíì dàgbà tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọn kò jẹunre kánú ní 1982. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ohun tí kò tó ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú àìjẹunre kánú tí ó ṣẹ́ pẹ́ẹ́rẹ́ àti èyí tí ó burújáì kúrò. Ní orílẹ̀-èdè Oman, ilé ẹ̀kọ́ mẹ́ta péré ló wà níbẹ̀ lọ́dún 1970, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] ọmọdékùnrin péré ló sì ń kàwé níbẹ̀. Ṣùgbọ́n ní 1994, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] ọmọ tó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn ló lọ sí ilé ẹ̀kọ́, ìpín mọ́kàndínláàádọ́ta lára wọn sì jẹ́ obìnrin. Láìsí àní-àní, àwọn wọ̀nyẹn jẹ́ ìròyìn àṣeyọrí.
Ṣùgbọ́n ìwé ìròyìn tí àjọ UN ṣe náà, United Nations Action for Youth, sọ pé, ńṣe ni àwọn ìṣòro tí ń ṣẹlẹ̀ léraléra ń pọ̀ ju ìlọsíwájú lọ ní àyíká ètò ẹ̀kọ́, ìníṣẹ́lọ́wọ́, àti ipò òṣì, ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ìwọ̀nyí sì wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn apá tí Ètò Àgbáyé náà fojú sùn láti mú sunwọ̀n sí i.
Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ni kò ní lè kúnjú ìwọ̀n góńgó pípèsè ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ fún gbogbo ọmọdé ní ọdún 2000. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé àwọn òbí tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kì í lè rán àwọn ọmọ wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ nítorí pé kò sí ilé ẹ̀kọ́ tàbí wọn kò lè rówó ilé ẹ̀kọ́ san. Ìwé ìròyìn United Nations Action for Youth, sọ pé, ní àbájáde rẹ̀, “iye àwọn púrúǹtù yóò máa pọ̀ sí i ni.” Ní ìtòtẹ̀léra, jíjẹ́ púrúǹtù yóò mú kí àìríṣẹ́ṣe pọ̀ sí i, àìríṣẹ́ṣe yóò sì yọrí sí ọ̀pọ̀ àwọn ìṣòro láwùjọ, bí “àìdára-ẹni-lójú, fífini sípò aláìjámọ́-ǹkan,” àìlo ẹ̀bùn ìgbà ọ̀dọ́ lọ́nà jíjáfáfá, àti ipò òṣì bíburújáì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tọmọdé tàgbà ni ipò òṣì ń pọ́n lójú, àwọn ọ̀dọ́ ló máa ń tètè ṣẹlẹ̀ sí jù. Ìwé ìròyìn àjọ UN kan náà sọ pé, lójú gbogbo ipá tí a ń sà, “ebi àti àìjẹunre kánú ṣì wà lára àwọn ewu tí ó burú jù lọ, tí kò sì ṣeé kápá tí ń bá aráyé fínra.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ètò tí a ṣe pẹ̀lú èrò rere àti àwọn amọṣẹ́dunjú tí ń ṣiṣẹ́ kára ń ṣe àwọn àṣeyọrí kan, wọn kò lè mú àwọn ohun tí ń fa ìṣòro láwùjọ ẹ̀dá kúrò. A nílò ohun púpọ̀ sí i láti ṣàṣepé rẹ̀. Ìwé Mensenrechten en de noodzaak van wereldbestuur (Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn àti Kòṣeémánìí fún Ṣíṣàkóso Ènìyàn) sọ pé, ‘àyàfi tí alákòóso ayé kan tí ó lè gbé àwọn ìwéwèé aṣeéfipá-múniṣe kalẹ̀ bá dé ni àwọn ìṣòro ayé yóò yanjú.’ Kò yani lẹ́nu nígbà náà, pé àwọn Kristẹni—tọmọdé tàgbà—ń wọ̀nà fún Ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀, ìṣàkóso ayé tí Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa gbàdúrà fún. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Ìṣàkóso yẹn yóò mú ìyàtọ̀ wá ní tòótọ́!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ẹ̀tọ́ àti ohun kòṣeémánìí pàtàkì ni ẹ̀kọ́ jẹ́ fún gbogbo ọmọ
[Credit Line]
Fọ́tò WHO tí J. Mohr yà
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Fọ́tò FAO/F. Mattioli
Àmì: Fọ́tò UN